Lesson 11 - Elementary
Memory Verse
“Wá kiri, ẹnyin o si ri” (Matteu 7:7).Notes
Awọn ọkunrin ti wọn ra Josẹfu lọwọ awọn arakunrin rè̩ mu un lọ si Egipti, wọn si ta a lẹru. Olori ogun kan ra Josẹfu, o si fẹran rè̩ pupọ nitori Josẹfu jé̩ oninu rere, o si gbọran.
Ni ọjọ kan, a purọ mọ Josẹfu. Olori ogun yii gba irọ naa gbọ, o si fi Josẹfu sinu tubu. Ohun ti ko rọrun ni o jé̩ fun Josẹfu lati wà ninu tubu pẹlu awọn eniyan buburu nigba ti ó mọ pé oun kò dẹṣẹ rara.
S̩ugbọn Josẹfu fẹran Ọlọrun; o si gbagbọ pe ohun gbogbo yoo yọri si rere. O ṣe oninure ninu tubu, o si layọ, o si n ṣe iranwọ fun awọn ẹlomiran bi oun i ti i maa ṣe tẹlẹtẹlẹ. Onitubu ri i pe Josẹfu kò dabi awọn ẹlomiran, o si ṣe iyọnu si Josẹfu. Nigba ti o wà ninu tubu, awọn onde meji kan lá àlá, Josẹfu si sọ itumọ àlá wọn fun wọn.
Ni ọdun meji lẹyin eyi, ọba lá àlá, à ni o lá àlá kan ṣoṣo lẹẹmeji. O pe awọn eniyan diẹ lati sọ itumọ ala naa, ṣugbọn wọn kò mọ ọn. Nigba naa ni a ranti Josẹfu ninu tubu. Ọba ti gbọ pe o le tumọ ala, nitori naa o ranṣẹ lọ pe Josẹfu.
O sọ fun Josẹfu pe oun la ala ti oun duro lẹba odo ti maluu meje ti o sanra jade ninu odo, wọn si n jẹ koriko. Lẹyin naa maluu meje miiran ti kò sanra tun jade wọn si gbé awọn ti o sanra mi. Lẹyin naa o tun la ala pe oun ri ṣiiri ọka meje ti o sanra lori igi ọka kan. Awọn ṣiiri ọka meje miiran ti o tinrin si tun jade wá, wọn si gbé meje ti o sanra ni mì.
Josẹfu ti gbadura si Ọlọrun lati le mọ itumọ ala naa, o si mọ ọn. O sọ fun ọba pe Ọlọrun fi ohun ti o yẹ ki ọba yii ṣe ni ilẹ rè̩ hàn án. Maluu meje ti o sanra ati ṣiiri ọka meje ti o sanra fi hàn pe ounjẹ yoo pọ fun ọdun meje. Lẹyin naa ounjẹ yoo wọn laaarin ọdun meje ti yoo tẹle, kò ni si ounjẹ rara, a fi bi a bá fi ounjẹ pamọ ni ọdun meje ti ounjẹ pọ.
Inu ọba dun to bẹẹ ti o fi Josẹfu ṣe alakoso ilẹ naa. Ọlọrun san è̩san rere fun Josẹfu. Ọdọmọkunrin ẹrú, ti a gbé sinu tubu lai ṣè̩, jade kuro ninu tubu, o si di alakoso lori gbogbo ilẹ Egipti.
Questions
AWỌN IBEERE1 Ki ni awọn ọkunrin ti wọn ra Josẹfu lọwọ awọn arakunrin rè̩ ṣe si i? Gẹnẹsisi 37:36
2 Ta ni ra Josẹfu lọwọ wọn? Gẹnẹsisi 39:1
3 Ala wo ni ọba lá? Gẹnẹsisi 41:2-7
4 Njẹ Josẹfu dẹṣẹ ti a fi gbé e sinu tubu?
5 Bawo ni Josẹfu ṣe mọ itumọ ala naa?
6 Ere wo ni a fun Josẹfu nitori o ran ọba lọwọ? Gẹnẹsisi 41:41