Gẹnẹsisi 34:1-34

Lesson 12 - Elementary

Memory Verse
“ Ẹ máṣe jẹ ẹnikẹni ni gbese ohun kan, bikoṣepe ki a fẹran ọmọnikeji ẹni” (Romu 13:8)
Notes

Nigba ti Josẹfu sọ itumọ ala ọba fun un, inu ọba dun to bẹẹ ti o fi Josẹfu ṣe alakoso ilẹ naa. Ọba paṣẹ ki Josẹfu ra ounjẹ, ki o si fi wọn pamọ titi di ọdun meje ti ounjẹ kò ni pọ. Josẹfu fi agbado ti awọn eniyan naa jẹ kù pamọ sinu àká nla nla.

Ọdun meje ti ounjẹ pọ kọja, ọdun meje iyàn dé. Kò si agbado loko rara. Ọpọlọpọ jẹ agbado ti wọn ti fi pamọ tán, wọn si tọ ọba wá ki o ràn wọn lọwọ. Ọba dari wọn sọdọ Josẹfu, oun si ṣi àká nla nla wọnni, o si ta ounjẹ fun awọn eniyan.

Ni ibi ti baba Josẹfu ati awọn arakunrin rè̩ n gbé kò si agbado, nitori naa awọn eniyan tọ Josẹfu wa ki ebi ma ba pa wọn kú. Baba Josẹfu ati awọn arakunrin rè̩ lówó pupọ, ṣugbọn lai si ounjẹ, owó wọn kò jamọ nnkankan.

Nitori naa Jakọbu rán awọn ọmọ rè̩ mẹwaa ti wọn dagba jù lọ si Egipti lati ra agbado wá nibi ti a ti fi pamọ sinu aka nla nla. Oun kò jẹ ki aburo Josẹfu lọ nitori o n bẹru ki ohunkohun ma baa ṣe e.

Lẹyin naa awọn arakunrin Josẹfu tọ ọ lọ lati ra ounjẹ. O fẹrẹ to ọdun mẹtala nigba ti wọn tà á. Nisisiyii ó ti dagba, o wọ aṣọ bi ọmọ-ọba, o si gunwa lori itẹ, wọn kò si mọ ọn. Josẹfu mọ awọn arakunrin rè̩ lẹsẹkẹsẹ ti o ri wọn.

Josẹfu fé̩ mọ nipa wọn boya wọn kò buru mọ bi ti igba ti wọn ta a, nitori naa kò fi ara rè̩ hàn fun wọn. Awọn arakunrin Josẹfu sọ fun un pe aburo wọn abikẹyin wà nile. Nigba naa Josẹfu sọ pe oun yoo mú ẹni kan silẹ ninu wọn titi wọn yoo fi mú aburo wọn abikẹyin wá.

Nigba ti wọn n pada lọ ni ọjọ kẹta lẹyin naa, o ṣe rere fun wọn. O ti dari gbogbo iwa buburu ti wọn hù si i ji wọn. O fi agbado kún apo wọn, o si dá owó ti wọn san pada sinu apo wọn.

Nigba ti wọn sọ fun baba wọn nipa ọkunrin ajeji ti o n ṣe alakoso ilẹ naa ti o fẹ ki wọn mú aburo wọn abikẹyin wá, ẹru ba a. Oun kò ri Josẹfu mọ, ẹru si n ba a ki Bẹnjamini ma ba kú pẹlu.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni Josẹfu fi agbado ti o kó pamọ ṣe?

  2. 2 Ki ni awọn eniyan ṣe nigba ti ounjẹ wọn tán?

  3. 3 Ta ni tọ Josẹfu wá fun ounjẹ?

  4. 4 Bawo ni Josẹfu ṣe fi inu rere hàn fun awọn arakunrin rè̩?

  5. 5 Ta ni Josẹfu fé̩ ri?