Johannu 19:38-42; Matteu 27:62-66; Johannu 20:1-31

Lesson 14 - Elementary

Memory Verse
“Gbogbo agbara li ọrun ati li aiye li a fifun mi” (Matteu 28:18).
Notes

Jesu, Ẹni ti I ṣe Ọrẹ ati Olugbala gbogbo araye, ni a ti kàn mọ igi agbelebu. Ọkan ninu awọn ọrẹ Jesu, ti a n pe ni Josẹfu tọrọ okú Jesu lọwọ Pilatu. Ọrẹ Rè̩ miiran ti a n pe ni Nikodemu mú ororo oloorun didun wá, awọn ọrẹ mejeeji wọnyii ni wọn jumọ fi aṣọ ọgbọ daradara wé oku Jesu lẹyin ti wọṅ fi ororo kun Un.

Ọgba kan wà ni tosi, nibẹ ni Josẹfu té̩ Jesu si ninu iboji titun ti o gbé̩ fun ara rè̩. O si yi okuta nla di ẹnu iboji naa. Awọn eniyan buburu ti wọn kan Jesu mọ agbelebu fẹ ri i daju pe ẹnikẹni kò ji oku Jesu gbé lọ, nitori naa wọn fi ontẹ tẹ okuta naa, wọn si yan awọn ọmọ-ogun lati maa ṣọ iboji naa.

Ni owurọ Ọjọ Isinmi, nigba ti ilẹ ko i ti i mọ daradara Maria Magdalene, ẹni ti o fẹran Jesu lọpọlọpọ, lọ si iboji naa. S̩ugbọn iboji naa ṣofo. Maria sare lọ sọ fun awọn ọmọ-ẹyin pe a ti gbé oku Jesu lọ.

Nigba ti Peteru ati Johannu gbọ pe iboji naa ti ṣofo, wọn sare lọ sibẹ lati wo o. Lotitọ ati lododo, wọn ri aṣọ ti a fi wé oku Jesu, ṣugbọn ara Rè̩ ko si nibẹ mọ. Ki ni ṣẹlẹ?

Nigba ti Peteru ati Johannu kuro nibẹ, Maria Magdalene nikan duro lẹyin iboji, o si n sọkun. Nibo ni a gbé oku Jesu Oluwa rè̩ ọwọn lọ? Maria wò yika,o si ri ẹni kan duro lẹyin rè̩. O ro pe oluṣọgba ni, o si wi fun un pe, “Alàgba, bi iwọ ba ti gbé e kuro nihin, sọ ibiti o gbé tẹ ẹ si fun mi.”

Nigba naa ni O pè é pé “Maria.” Ah! ohùn didùn Jesu ni! Lotitọ O wà laaye! Olugbala ati ọrẹ rè̩ ọwọn.

Awa gbagbọ pe Jesu wà laaye sibẹ lonii. O wà loke Ọrun, O n gbadura si Ọlọrun lati ràn wá lọwọ ki O si daabo bò wá lojoojumọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Awọn ọrẹ Jesu wo ni wọn fi aṣọ wé oku Rè̩? Johannu 19:38-40

  2. 2 Nibo ni Josẹfu gbé té̩ oku Jesu si, ki ni oun si fi si ẹnu iboji naa? Johannu 19:41

  3. 3 Ta ni wá si ibi iboji nigba ti ilẹ ko i ti i mọ, ti o si ri ti iboji naa ṣofo? Johannu 20:1

  4. 4 Ta ni bá Maria sọrọ nibi ti o duro si ti o n sọkun? Johannu 20:11-12

  5. 5 Njẹ Jesu wà laaye lonii?

  6. 6 Nibo ni O wà, ki ni O si n ṣe?