Lesson 15 - Elementary
Memory Verse
“Emi kò le ṣàima wà nibi iṣẹ Baba mi” (Luku 2:49).Notes
Nigba ti ọba buburu nì fé̩ pa Jesu, Ọlọrun sọ fun awọn obi Rè̩ lati gbé E lọ si Egipti. Ọba naa pa gbogbo awọn ọmọkunrin wẹwẹ; bayii ni Ọlọrun daabo bo Jesu. Nigba ti ọba naa kú, Ọlọrun sọ fun awọn obi Rè̩ lati gbé E pada. Wọn pada si Nasarẹti. Nibẹ ni Jesu gbé dagba. Wọn ko ni omi ẹrọ bi ti wa, ṣugbọn odo kan wà ni Nasarẹti ti ki i gbẹ; dajudaju Jesu a maa ṣe iranwọ fun awọn obi Rè̩ lati lọ pọn omi, bakan naa ni O si n ṣe iranwọ fun Josẹfu ni ile iṣẹ gbẹnagbẹna rè̩.
Jesu ko i ti i lọ si Jerusalemu ri ṣugbọn nigba ti O di ọmọ ọdun mejila, O bá awọn obi Rè̩ lọ si Tẹmpili ni Jerusalemu. Lẹyin ọjọ diẹ, awọn obi Rè̩ pada lati lọ sile, ṣugbọn wọn ko mọ pe Jesu ko bá wọn pada. Nigba ti wọn mọ pe ko si ni aarin ero, wọn tun pada si Jerusalemu.
Lẹyin ọjọ mẹta, wọn ri I ni Tẹmpili ti o tẹti silẹ si awọn olukọ ti O si n beere ibeere lọwọ wọn.
Ẹnu ya awọn eniyan si ibeere Rè̩. Nigba ti awọn obi Rè̩ ri I ti wọn sọ fun Un wahala ti wọn ti ṣe nigba ti wọn ko ri I, O wi fun wọn pe, Oun ko le ṣai ṣe iṣẹ Baba Oun nigba ti I ṣe ọsan.
A ko mọ pupọ nipa igbà èwe Jesu ṣugbọn a mọ daju pe O gbọran si awọn obi Rè̩. O si fẹran lati maa gbadura si Baba Rè̩ ni Ọrun ti O fẹran Rè̩ jù lọ.
Questions
AWỌN IBEERE1 Ki ni Jesu n ṣe ni Tẹmpili? Luku 2:46
2 Ki ni Jesu wi fun awọn obi Rè̩ nigba ti wọn ri I? Luku 2:49
3 Njẹ Jesu gbọran si awọn obi Rè̩ lẹnu? Luku 2:51
4 Ọmọ ọdun meloo ni Jesu ni akoko yii? Luku 2:42