Matteu 3:1-12; Marku 1:1-11; Johannu 1:19-28

Lesson 16 - Elementary

Memory Verse
“Eyi ni ayanfẹ ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi” (Matteu 3:17).
Notes

Eniyan Ọlọrun kan wà ti a n pè ni Johannu Baptisi. Oun ki i gbé aarin ilu nibi ti awọn eniyan wà. O n gbé inu aginju. S̩ugbọn è̩ru kò ba Johannu. O mọ pe Ọlọrun wà pẹlu oun. Inu iho ni Johannu Baptisi n sùn. Aṣọ ti a fi irun rakunmi ṣe ni i maa wọ, eeṣu, bi kokoro nla ti o fara jọ ẹlẹnga ni ounjẹ rè̩, ati oyin igan ti awọn oyin fi pamọ sinu apata tabi ara igi.

Johannu fé̩ lati wà jinna si awọn eniyan ki o le ri aaye lati maa rò nipa ti Ọlọrun. Nitori lai pẹ yoo bẹrẹ si waasu fun awọn eniyan yoo si maa kọ wọn bi o ṣe yẹ lati fi eti silẹ si Jesu nigba ti O ba n waasu ni ọjọ kan. Ọlọrun sọ fun Johannu lati sọ fun awọn eniyan pé Jesu n pada bọ ati pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu I ṣe. O sọ fun wọn pe ohun buburu ni lati maa dẹṣẹ. O rọ wọn lati kaanu fun è̩ṣẹ wọn, ki wọn si beere pe ki Ọlọrun dariji wọn, ki wọn si pinnu lati má dẹṣẹ mọ. Ọpọlọpọ ni o kaanu ti wọn si beere pe ki Ọlọrun dari ẹṣẹ wọn ji wọn. Lẹyin naa Johannu Bakptisi a si ṣe iribọmi fun wọn ninu odo Jordani.

Lai pẹ lọjọ, gbogbo awọn ti o wà ni Jerusalẹmu ati gbogbo ẹkun Judea gbọ nipa abami oniwaasu ti o wà ni aginju yii. Ta ni oluwarẹ? Nibo ni o ti wá? Ko si ẹni ti o mọ. Awọn ẹlomiran bi i pe, “Ta

ni iwọ iṣe? Iwọ ha ni Kristi ti awa ti n reti?” Johannu dahun pe: “Emi li ohùn ẹniti n kigbe ni ijù. Ẹ tún ọna Oluwa ṣe.”

Jesu wá si odo nibi ti Johannu ti n ri awọn eniyan bọmi. Jesu fẹ ki a ri Oun naa bọmi pẹlu. Ọlọrun fẹ fi Jesu ṣe apẹẹrẹ fun wa nitori Jesu ni aṣaaju wa, a si ni lati maa tẹle E.

A ri Jesu sinu omi, bi O ti n goke lati inu odo Ọrun ṣi silẹ, Ẹmi Mimọ Ọlọrun si sọkalẹ bi adaba, O si ba le E. Ohun kan ti Ọrun wá pe: “Eyi ni ayanfẹ ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi.

Inu Ọlọrun dùn si Jesu nitori O gbọran nigba gbogbo. Nigba ti a ba duro niwaju Ọlọrun nigbooṣe, bawo ni yoo ti dùn to bi Ọlọrun ba le sọ fun wa pe; “Iwọ ni ayanfẹ ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Nibo ni Johannu Baptisi n gbé? Matteu 3:3

  2. 2 Iru aṣọ wo ni o n wọ? Ki ni ounjẹ rè̩ Matteu 3:4

  3. 3 Ki ni ṣe ti o fi n gbé aginju?

  4. 4 Ta ni wá ṣe iribọmi lọdọ Johannu? Marku 1:9

  5. 5 Ki ni ṣe ti Jesu fi ṣe iribọmi? Matteu 3:15

  6. 6 Ki ni Ọlọrun sọ nipa Jesu? Marku 1:11