Lesson 17 - Elementary
Memory Verse
“Oluwa Ọlọrun rẹ ni ki iwọ ki o foribalẹ fun” (Matteu 4:10).Notes
Jesu ti dá nikan wà ni aginju fun ogoji ọjọ. Ni gbogbo akoko yii, kò jẹ ohunkohun, ṣugbọn O n fi gbogbo akoko yii gbadura. Eṣu mọ pé Jesu wà ninu aginju. O n ṣọ Jesu tọwọ-tẹsẹ, bakan naa ni o n ṣọ gbogbo awọn ti o fé̩ Jesu lode oni, O mọ pe Jesu wá si ayé lati pa agbara Eṣu run ati lati sọ awọn eniyan di rere ati mimọ. Eṣu fẹ ṣe idena Jesu. O fẹ mu ki Jesu dẹṣẹ lọnakọna.
Eṣu mọ pe aarẹ mú Jesu, ebi si n pa A. O sọ fun Jesu pe ki O sọ okuta di akara ki O jẹ é̩. Ohun ti o rọrun fun Jesu lati ṣe ni, ṣugbọn Oun kò ni ṣe iṣé̩ iyanu lati té̩ Eṣu lọrun. Jesu dá Eṣu lohun lati inu Bibeli wá, “Enia kì yio wà lāyè nipa akara nikan, bikoṣe nipa gbogbo ọrọ ti o ti ẹnu Ọlọrun jade wá.” O dara lati ka ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun fun awọn ti o ba fẹ tàn wá lati ṣe ibi.
Lẹyin naa, Eṣu gbé Jesu lọ si ṣonṣo Tẹmpili daradara ti ilu Jerusalemu. Satani sọ fun Jesu lati bẹ silẹ lati ori Tempili yii. O ni Ọlọrun yoo rán awọn angẹli lati gbé Jesu ni ọwọ wọn ki O ma ba fi ara pa.
Jesu mọ pe ko tọ lati mọọmọ ṣe ohunkohun ti o lewu tabi ti o le pa wá lara. Ọlọrun yoo daabo bo wá ninu ewu, ṣugbọn Oun fẹ ki a maa ṣọra.
Ki i rẹ Eṣu bẹẹ. Bi ko ba le mú eniyan lọna kan, a tun wá lọna miiran. Nisisiyii, Eṣu gbé Jesu lọ si ori-oke kan. Jesu le ri gbogbo ijọba ayé. Satani wi pe, “Emi yoo fun Ọ ni gbogbo ilè̩ yii ati ọpọlọpọ ọrọ ti wura ati fadaka bi iwọ ba le tẹriba fun mi, ki O si sin mi.”
Ki i ṣe Eṣu ni o ni awọn ilè̩ ati ọrọ ayé yii, Ọlọrun ni o ni wọn. Lẹẹkan sii, Jesu tun dahun lati inu Bibeli wá, “Oluwa Ọlọrun rẹ ni ki iwọ ki o foribalẹ fun, on nikanṣoṣo ni ki iwọ mā sìn.” “Pada lẹhin mi, Satani.” Ohunkohun ti o wu ki Eṣu sọ, Jesu kò jẹ gbọ ti rè̩.
Nigba miiran Eṣu a maa tọ wa wá, a si gbiyanju lati rọ wá lati ṣe ibi pẹlu ileri pe, a o ri ere nla gbà. A kò le fi oju ara ri i, ṣugbọn a le mọ bi o ba wà nitosi. Nitori naa a ni lati maa gbadura lojoojumọ ki a sọ fun Jesu lati ràn wá lọwọ lati dahun pe, “BẸẸ KỌ” nigbakuugba ti Eṣu ba n dán wa wò lati ṣe ibi. Jesu n tẹti silẹ, O si ṣetan lati ràn wá lọwọ.
Questions
AWỌN IBEERE1 Bawo ni Jesu ti pé̩ to ni aginju? Matteu 4:2
2 Ki ni O ṣe nigba ti O fi wà nibẹ? Matteu 4:2
3 Ta ni wá dán Jesu wò lati ṣe íbi? Matteu 4:1
4 Ki ni Jesu fi ṣẹgun rè̩?
5 Ki ni a ni lati ṣe nigba ti Eṣu bá n tàn wá lati ṣe ibi?