Matteu 5:1-48; 6:9-13

Lesson 18 - Elementary

Memory Verse
Ẹnyin ni imọlẹ aiye” (Matteu 5:14)
Notes

Ọpọlọpọ eniyan ti gbọ okiki Jesu bi O ṣe n wo alaisàn sàn. Ọpọ ti gbọ pé O n ṣiṣẹ iyanu, nitori naa ni ọpọ eniyan ṣe n tẹle E nigba gbogbo ti wọn si fẹ gbọ ọrọ Rè̩. Boya idi rè̩ ti Jesu fi gun ori oke lọ ni pe ki ọpọlọpọ eniyan le ni anfaani lati gbọrọ Rè̩. O fẹ kọ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ni ohun ti o yẹ ki wọn le mọ, ki awọn naa le fi kọ awọn ẹlomiran. O joko, O si bẹrẹ si kọ wọn.

Lara ohun ti Jesu kọ wọn ni pe, Ọlọrun yoo bukun awọn ẹni ti o gbẹkẹle Ọlọrun fun iranwọ, bi wọn ba gbagbọ pe Ọlọrun ni O le ṣe ohun gbogbo daradara ju ẹnikẹni lọ. Ọlọrun yoo tọ wọn si ọna ijọba Ọlọrun.

O si tun sọ fun wọn pe, Ọlọrun yoo bukun awọn ti o sa ipá wọn lati ṣe ifẹ Ọlọrun, ti wọn si ṣe onirẹlẹ ati ẹni rere, ti wọn si n ṣe iranlọwọ fun awọn alaini. Bakan naa ni O kọ wọn pe, Ọlọrun yoo bukun ẹni ti ọkàn rè̩ bá mọ ti o si funfun laulau.

O kọ wọn pe, Ọlọrun yoo bukun awọn ti ki i fi ahọn wọn sọrọ buburu, ti ki i purọ tabi ki o mọ ti ara rè̩ nikan.

Awọn ọmọ-ẹyin rè̩ bẹ Ẹ pe ki O kọ wọn bi a ti n gbadura, O si kọ wọn ni adura daradara kan ti o kó gbogbo aini wọn já - eyi ni Adura Oluwa. (Matteu 6:9-13).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Bawo ni a ṣe le jẹ “imọlẹ” fun Jesu? Matteu 5:16

  2. 2 Njẹ ẹni ti o n binu si arakunrin rè̩ le rí ibukun Ọlọrun gbà? Matteu 5:22

  3. 3 Njẹ o yẹ ki a fi buburu gbẹsan buburu? Matteu 5:44

  4. 4 Bawo ni a ṣe le fi han awọn ti o n huwa buburu pe kò tọ lati maa ṣe bẹẹ?

  5. 5 Njẹ o yẹ ki ran alaini lọwọ? Matteu 5:42