Lesson 19 - Elementary
Memory Verse
“Ẹnyin ọmọ, ẹ mā gbọ ti awọn obi nyin ninu Oluwa” (Efesu 6:1)Notes
Ni ọdun pupọ sẹyin, obinrin kan wà ni Israeli ti a n pè ni Hanna. Ọkọ rè̩ fẹran rè̩, ṣugbọn sibẹ inu rè̩ kò dùn. Inu rè̩ bajẹ nitori kò bimọ ti o le fẹran ti o si le tọjú.
Ni gbogbo igba yii, ọkàn rè̩ fẹ lati ni ọmọ ti rè̩, ṣugbọn sibẹ kò bimọ.
Tẹlẹ ri, ile-isin ko si ni ilu kọọkan bi o ti wà nisisiyii, nitori naa, ọdọọdun ni Hanna ati ọkọ rè̩ n lọ si S̩ilo lati lọ jọsin ni Tẹmpili.
Ni ọdun kan, Hanna pinnu lati gbadura si Ọlọrun ki O le fun oun ni ọmọ kan. O mọ pe Ọlọrun fẹ ki oun beere. Ni ọjọ kan, nigba ti o wà ni Tẹmpili, o bẹrẹ si gbadura. O gbadura gidigidi. Ko gbadura soke ti ẹnikẹni fi le gbọ ohun ti o n wi. S̩ugbọn o gbadura lati inu ọkàn rè̩ wá, ete rè̩ n mi wuyẹwuyẹ. Ọlọrun n gbọ adura bi o tilẹ ṣe pe a gba a wuyẹwuyẹ.
O gbadura pe ki Ọlọrun fun oun ni ọmọ. O ṣeleri pe, oun yoo fẹran ọmọ naa, oun yoo si ṣikẹ rè̩ bi Ọlọrun bá fun oun ni ọmọ. O ṣeleri pe bi ọmọ naa ba dagba, oun yoo fi i fun Ọlọrun lati maa ṣiṣẹ fun Un.
Nisisiyii, inu Hanna kò bajẹ mọ, o ti gbadura o si gbagbọ pe Ọlọrun yoo gbọ adura oun. Ọlọrun gbọ, Ọlọrun fun un ni ọmọkunrin jojolo kan.
Inu Hanna dùn! O sọ ọmọ naa ni Samuẹli, itumọ eyi ti i ṣe mo tọrọ rè̩ lọwọ Ọlọrun.
Hanna fẹran Samueli, o si n tọju rè̩ lojoojumọ, gẹgẹ bi iya rẹ ti n tọju rẹ. O ranti ileri ti o ṣe fun Ọlọrun. Nigba ti o ri i pe Samuẹli ti dagba, o mu un lọ si ile Ọlọrun ni S̩ilo. Nibẹ ni alufaa rere ni yoo gbé kọ ọ ni Ọrọ Ọlọrun.
Hanna fẹran Samuẹli. O ṣoro lati dagbere fun ọmọ rè̩ nigba ti o fẹ pada lọ si ile, ṣugbọn inu rè̩ dùn nitori o mu ileri ti o ṣe fun Ọlọrun ṣẹ. Hanna layọ lori Samuẹli. Iya rẹ ha layọ lori rẹ bi?
Questions
AWỌN IBEERE1 Ki ni ṣe ti inu Hanna kò fi dùn? 1 Samuel 1:6, 7
2 Igba meloo ni Hanna ati ọkọ rè̩ i maa lọ jọsin ni Tẹmpili laaarin ọdun kan? 1 Samuel 1:3
3 Ki ni Hanna beere lọwọ Ọlọrun? 1 Samuel 1:11
4 Njẹ adura rè̩ gbà? Lọna wo? 1 Samuel 1:20
5 Ki ni ileri ti o ṣe fun Ọlọrun? 1 Samuel 1:11
6 Ki ni wọn fi kọ Samuẹli ni Tẹmpili?