Lesson 20 - Elementary
Memory Verse
“Emi mbọ wá mu u larada” (Matteu 8:7).Notes
Ọkunrin kan wà ti o ṣaisàn pupọ ni agbegbe ibi ti Jesu n gbé. Ọkunrin naa kò lè rìn. O dabi ẹni pe ki yoo le rin mọ ni gbogbo ọjọ ayé rè̩.
Jesu n lọ lati ilu de ilu lati waasu ati lati ṣe iwosan fun awọn ti ara wọn kò dá. Ni ọjọ kan Jesu lọ si ilu ti ọkunrin yii wà.
Diẹ ninu awọn ọrẹ ọkunrin alaisan yii gbọ nipa Jesu. Wọn ba ara wọn sọ pe, ẹ jẹ ki a gbé ọrẹ wa lọ sọdọ Jesu. Jesu le wò ó sàn. Ọna kan ti wọn le fi gbé alaisan naa ni lati fi akete ti o fi n sùn gbé e.
Nigba ti awọn ọrẹ oninuure wọnyii dé ile ibi ti Jesu wà, ile naa kún fun ọpọ eniyan to bẹẹ ti kò si àye lati wọle. Wọn ro o lọkan wọn pe, “Ki ni awa yoo ṣe?” Wọn kò sọ ireti nù. Wọn ni lati wá ọna miiran lati le dé ọdọ Jesu nitori ọkunrin alaisan yii n fẹ iranwọ. Ko si ẹni ti o le ràn án lọwọ afi Jesu.
Ero kan sọ si wọn lọkàn. Wọn gbé ọkunrin naa lọ si ori orule. Wọn ṣi orule naa. Wọn so okùn mọ akete ọkunrin alaisan naa, wọn si sọ ọ kalẹ si ibi ti Jesu wà. Oun mọ pe awọn ọkunrin mẹrin wọnyii ni igbagbọ pe ọrẹ wọn yoo sàn. Ayọ ni o jé̩ fun Jesu lati ran ọkunrin alaisan naa lọwọ.
Ohun ti o ṣe pataki jù lọ ni ayé yii ni ki a ri idariji è̩ṣẹ gbà. Nitori naa Jesu wi fun un pe, Mo dari gbogbo è̩ṣẹ rẹ ji ọ. Jesu yipada si ọkunrin alaisan naa, o si tun wi fun un pe, “Dide, si gbé akete rẹ, ki o si ma rìn.”
Lẹsẹ kan naa, ọkunrin naa dide lori ẹsẹ rè̩. O ká ẹní rè̩ o si bẹrẹ sii rìn. Ara rè̩ le, inu rè̩ si dùn.
Awọn ọrẹ rè̩ ṣe oriire ti wọn kò sọ ireti nù, nigba ti wọn kò le de ọdọ Jesu ni akọkọ. Igba gbogbo ni ọna si ọdọ Jesu ṣi silẹ. O wà nibẹ nigba gbogbo, O si ṣe tan lati ràn wá lọwọ.
Questions
AWỌN IBEERE1 Ki ni àrùn ti o n bá ọkunrin alaisan naa jà? Marku 2:3
2 Ta ni wa bẹ ilu ti ọkunrin alaisan naa n gbé wò? Marku 2:5
3 Njẹ o ṣe e ṣe lati gbé ọkunrin alaisan naa dé ọdọ Jesu lẹsẹkẹsẹ? Ki ni ṣe? Marku 2:4
4 Ki ni wọn ṣe? Marku 2:4
5 Ki ni ohun kin-in-ni ti Jesu ṣe fun ọkunrin alaisan naa? Marku 2:5
6 Ki ni ohun keji ti Jesu ṣe fun un? Marku 2:11
7 Ki ni ọkunrin naa ṣe lẹyin ti Jesu ti sọrọ? Marku 2:12