Johannu 6:1-13

Lesson 21 - Elementary

Memory Verse
“O ti fi ohun ti o dara kún awọn ti ebi npa” (Luku 1:53).
Notes

Ọpọlọpọ eniyan maa n tẹle Jesu nibikibi ti O bá lọ. Ni ọjọ kan, Jesu fé̩ lati dá wà pẹlu awọn ọmọ-ẹyin Rè̩, ki O ba lè bá wọn sọrọ.

Jesu ati awọn Orẹ Rè̩ wọ inu ọkọ, wọn si lọ si apakeji òkun. Nibẹ wọn rò pe awọn yoo dá wà.

Awọn eniyan diẹ ti mọ ibi ti Jesu lọ, iroyin ibi ti wọn yoo ti ri I tàn kalẹ. Nigba ti Jesu dé ibẹ, Ọpọ eniyan ti n duro dè É, awọn miiran wà lọna. Jesu kò rán awọn eniyan wọnyii lọ. Aanu wọn ṣe É nitori O mọ pé wọn n fé̩ kẹkọọ nipa Ọrọ Ọlọrun kò si sí ẹni ti yoo kọ wọn afi Jesu.

Gbogbo ọsán ni Jesu fi kọ wọn. Oòrùn n wọ, ilẹ si n ṣú. Awọn ọmọ-ẹyin daamu. Wọn rò pé o yẹ ki Jesu rán awọn eniyan naa lọ lati ra ounjẹ ninu ilu ati awọn ileto ti ó yí wọn ká.

Ọmọdekunrin kan wà laaarin èrò ti ó ni iṣù akara marun-un ati ẹja kékèké meji. Anderu sọ fun Jesu nipa ọmọdekunrin yii, ṣugbọn Anderu rò pé ounjẹ kekere yii kò já mọ nnkan kan.

Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pé ki wọn mú awọn eniyan naa jokoo ni ẹgbẹgbé̩. Jesu duro nibẹ pẹlu ọmọdekunrin naa ti ó ti fi tayọtayọ gbé ounjẹ rè̩ silẹ; ó ṣeeṣe ki ebi maa pa ọmọ naa.

Jesu gbadura, O si bẹrẹ si i bu akara. Lẹsẹ kan naa, iṣu akara pọ si i, bẹẹ ni ẹja mejeeji pọ si i. Agbọn ni awọn ọmọ-ẹyin lò lati fi pín ounjẹ naa laaarin awọn eniyan.

Nigba ti wọn yó tán, agbọn mejila ṣé̩kù. Jesu kò fé̩ ki a fi ohunkohun ṣòfò. O sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pé ki wọn kó àjẹkù ti ó kù jọ.

A kò mọ orukọ ọmọdekunrin naa tabi ibi ti ti ó n gbé, ṣugbọn nitori ó fi ohun gbogbo ti ó ni silẹ fún Jesu bi o tilẹ ṣe pé kò tó nnkan, Jesu lo è̩bùn rè̩ yii lati ṣe iṣé̩ iyanu ní bíbọ ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan.

Orukọ wa kò já mọ nnkan; iwà wa ló jù.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nibo ni Jesu ati awọn ọrẹ Rè̩ lọ lati dá wà? Johannu 6:1
  2. O ti pé̩ tó ti Jesu ti kọ wọn?
  3. Ki ni ọmọdekunrin naa ní lati jẹ? Johannu 6:9
  4. Eniyan meloo ni Jesu lò ó lati bọ? Johannu 6:10
  5. Ki Jesu ṣe ki O tó bọ awọn eniyan? Johannu 6:11
  6. Agbọn meloo ni ó ṣé̩kù? Johannu 6:13.