Lesson 22 - Elementary
Memory Verse
“Emi li o yàn nyin” (Johannu 15:16).Notes
Baba Josẹfu wà pẹlu rè̩ fun ọdun mẹtadinlogun ki o to jé̩ ipè Ọlọrun. Lẹyin ikú Jakọbu, Josẹfu kò yi iwa rè̩ pada si awọn arakunrin rè̩. O fẹran wọn sibẹ. Bi wọn tilẹ ti ṣe ibi si i tẹlẹ rí, ṣugbọn o ti dariji wọn patapata.
Ni ọdun pupọ lẹyin eyi, ọba rere ti o mọ Josẹfu kú, ẹlomiran si jọba ni ipo rè̩. Josẹfu paapaa ti jé̩ ipè Ọlọrun. Ọba ti o wà lori oyè kò ni ifẹ Ọlọrun ninu ọkàn rè̩, bẹẹ ni ko si moore pẹlu.
O paṣẹ ki a fi iṣé̩ lile fun awọn Ọmọ Israẹli boya nipa ṣiṣe bẹẹ, ọpọlọpọ ninu wọn yoo kú. Lẹyin eyi o tun paṣẹ ki a pa gbogbo awọn ọmọkunrin. Ni akoko yii ni a bí Mose. Iya rè̩ si pa a mọ fun oṣu mẹta.
Ọba yii pọn awọn Ọmọ Israẹli loju pupọ. S̩ugbọn Ọlọrun fé̩ wọn, O si ri gbogbo iṣoro wọn. Bi a ba fé̩ Ọlọrun, Oun yoo ràn wá lọwọ lati bori iṣoro gbogbo. Iya Mose gbé e sinu agbọn, o gbé e si eti odò; ẹgbọn rè̩ si duro lokeere, Ọlọrun si pa ọmọ naa mọ.
Nigba ti ọmọbinrin Farao wá si eti odò, o rí ọmọ naa, o si gbé e.
Ẹgbọn Mose lọ pe iya rè̩ wá ki o ba le bá ọmọbinrin Farao ṣe itọju ọmọ naa. Bayii ni Ọlọrun ṣe pa Mose mọ. Lẹyin ọdun diẹ, a mu Mose wá si aafin ọba, ṣugbọn a mọ pe iya rè̩ ti kọ ọ ni Ọrọ Ọlọrun nigba ti Mose wà lọdọ rè̩. Mose kò fé̩ sin oriṣa gẹgẹ bi awọn ara Egipti ti maa n ṣe. Ifẹ Ọlọrun wà lọkàn rè̩.
Ọlọrun ni iṣé̩ nla fun Mose lati ṣe nigba ti o bá dagba. Ọlọrun fẹ ki olukuluku ọmọ ṣiṣẹ fun Oun. O dara ki a bẹrẹ lati igba èwe wa lọ, ki a ba le ṣiṣẹ fun Ọlọrun fun ọpọlọpọ ọdun.
Questions
AWỌN IBEERE1 Fun oṣu meloo ni iya Mose pa á mọ ki o to gbé e lọ si eti odò? Ẹksodu 2:2
2 Ta ni duro lokeere ti o n ṣọ ọ? Ẹksodu 2:4
3 Ta ni a lọ pè lati tọju Mose? Ẹksodu 2:8
4 Njẹ Ọlọrun ri ọmọ naa ninu agbọn?
5 Njẹ Ọlọrun n fé̩ ki awọn ọmọde ṣiṣẹ fun oun lati igba èwe wọn?