Eksodu 11:1-10; 12:1-51

Lesson 23 - Elementary

Memory Verse
“Oju Oluwa mbẹ lara awọn olododo” (1 Peteru 3:12).
Notes

Awọn eniyan Josẹfu ti jiya lọpọlọpọ, ṣugbọn Ọlọrun ri gbogbo irora wọn, O si ti gbọ igbe wọn.

Ọba Egipti kò fẹ ki wọn lọ, nitori wọn n ṣe biriki fun un. Tẹlẹ ri a ti n fun wọn ni koriko lati fi ṣe biriki, ṣugbọn nisisiyii a kò fun wọn ni koriko mọ, a n lù wọn pe ki wọn ṣiṣẹ wọn pe.

Ọmọde ti a gbé sinu agbọn leti odo ni ọjọ wọnni ti di agbalagba, o si ti kuro ni ile ọba. O wà lọna jijin, ṣugbọn Ọlọrun mọ ibi ti ó wà, Ó si pè é lati wá si Egipti lati ran awọn eniyan rè̩ lọwọ. Ọlọrun fun oun ati Aarọni arakunrin rè̩ ni lagbara lati ṣiṣẹ iyanu, ki awọn eniyan le mọ Ọlọrun otitọ.

Omi awọn ara Egipti di ẹjẹ, a rán ọpọlọ, iná ori ati arun miiran si wọn, ṣugbọn sibẹ, wọn kò jẹ ki awọn Ọmọ Israeli lọ.

Ọlọrun paṣẹ fun Mose lati sọ fun awọn Ọmọ Israeli lati ya ọdọ agutan tabi ewurẹ sọtọ fun ọjọ mẹrin ki wọn pa á, ki wọn sun ún, ki wọn si jẹ é̩. Wọn ni lati fi ninu ẹjẹ rè̩ sara òpó ati atẹrigba ile wọn. Nigba ti angẹli ba la ilu naa kọja lati pa awọn akọbi Egipti, yoo dá awọn Ọmọ Israeli ti o ba fi ẹjẹ si ile wọn sí. Ẹjẹ yii n tọka si Ẹjẹ ti Jesu ta silẹ fun wa.

Awọn ara Egipti kò fi ẹjẹ sara opo ile wọn, nitori wọn kò ni ifẹ Ọlọrun lọkan wọn. Gbogbo awọn akọbi wọn kú.

Nisisiyii ọba gbà pe ki wọn maa lọ. O mọ pe inu Ọlọrun kò dùn si iwa buburu ti oun n hù.

Mose mu awọn eniyan wọnyii lọ si ilẹ ti Ọlọrun ṣeleri. Inu wọn dùn pe wọn gbọran si Ọlọrun lẹnu.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni Ọlọrun sọ pe yoo ṣẹlẹ ni ọganjọ òru? Ẹksodu 11:4, 5
  2. Irú agutan wo ni wọn ni lati pa? Ẹksodu 12:5
  3. Ki ni wọn ni lati fi ẹjẹ rè̩ ṣe? Ẹksodu 12:7
  4. Njẹ awọn Ọmọ Israeli gbọran si aṣẹ Mose? Ẹksodu 12:28
  5. Njẹ ọba gbà nisisiyii pe ki wọn maa lọ? Ẹksodu 12:31