Eksodu 14:1-31

Lesson 24 - Elementary

Memory Verse
“Ẹ maṣe jẹ ki ọkàn nyin dàru” (Johannu 14:1).
Notes

Nigba ti Ọlọrun paṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli lati fi Egipti silẹ, O wà pẹlu wọn lati ṣe itọju wọn. Ikuuku funfun kan n ṣe amọna wọn lọsan, ọwọn iná si n ṣe amọna wọn loru.

Ọlọrun ni O fi i fun wọn lati maa tọ wọn. Bi a ba tẹle itọni Ọlọrun a kò ni ṣina, bẹẹ ni a kò ni bọ sinu ewu. O dara lati bá Ọlọrun rìn.

Farao kò fẹran Ọlọrun. Kò fẹ ki awọn Ọmọ Israẹli ki o lọ mọ. O kó ọpọlọpọ ọmọ-ogun rè̩ lati lọ mú awọn Ọmọ Israẹli pada.

Ẹru bà wọn nigba ti wọn ri awọn ọmọ-ogun Egipti. Òkun wà niwaju wọn, awọn ọmọ-ogun wà lẹyin wọn, nitori naa wọn ké pe Ọlọrun. Mose sọ fun wọn ki wọn má ṣe bẹru.

Ọlọrun fun Mose ni agbára lati ṣiṣẹ iyanu. O gbé ọpa rè̩ soke, omi òkun si pinya si meji. Awọn Ọmọ Israẹli si kọja ni iyangbẹ ilẹ. Ikuuku funfun ni jé̩ imọlẹ fun awọn Ọmọ Israẹli, ṣugbọn okunkun ni o jé̩ fun awọn ọta wọn.

Awọn ọmọ-ogun Egipti rì sinu Okun Pupa, nitori wọn kò fẹran Ọlọrun. Ọkàn awọn Ọmọ Israẹli kún fun ọpé̩ si Ọlọrun.

Wọn mọ pe Ọlọrun wà pẹlu Mose, wọn si gbọran si i lẹnu. Wọn mọ pe, o tọ lati ṣe ohunkohun ti Mose ba sọ fun wọn, nitori Ọlọrun ni O n tọ ọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni Ọlọrun fi ṣe amọna awọn eniyan Rè̩ lati fi ọna hàn wọn? Ẹksodu 13:21, 22

  2. 2 Ki ni Mose ṣe lati pín okun niya? Ẹksodu 14:21

  3. 3 Ki ni ṣẹlẹ si awọn ọmọ-ogun Egipti ni aarin òkun? Ẹksodu 14:25

  4. 4 Ki ni Mose ṣe lẹyin naa. Ẹksodu 14:27

  5. 5 Ta ni lana si aarin òkun? Ẹksodu 14:21