Eksodu 16:1-36

Lesson 25 - Elementary

Memory Verse
“Bi ẹnyin ba bère ohunkohun li orukọ mi, emi ó ṣe e” (Johannu 14:14).
Notes

Mose ati awọn eniyan rè̩ ti la Okun Pupa já lai lewu. Ọkàn wọn kún fun ọpé̩ si Ọlọrun nitori O daabo bò wọn, O si gbà wọn lọwọ awọn ara Egipti. Ki ni ẹ rò pe wọn ṣe? Wọn kọ orin ọpé̩ ati iyin si Ọlọrun.

Lẹyin ti wọn ti rìn fun ọjọ mẹta ti wọn kò si ri omi mu, oungbẹ n gbẹ wọn. Wọn kùn. Wọn de ibi kan ti omi rè̩ korò. Wọn tun kùn, wọn si banujẹ. Bawo ni o ti dara to lati gbadura si Ọlọrun nigba ti a ba ni iṣoro, kaka ki a maa kùn? Ọlọrun ṣaanu fun wọn, O si sọ omi naa di didùn.

Ohun ti o dara ni lati maa ranti oore Ọlọrun nigba gbogbo. Wọn gbagbe oore Ọlọrun ti wọn ti ri gbà. Wọn tun bẹrẹ si kùn pe, wọn ko ri ounjẹ. Ọlọrun gbọ kikùn wọn, O ṣeleri lati rọjo ouunjẹ fun wọn.

Ọlọrun mu ileri Rè̩ ṣẹ. O rọjo ounjẹ ti a n pe ni Manna silẹ fun wọn lojoojumọ lati Ọrun wá. Ọlọrun fẹ ki wọn gbẹkẹle Oun ni gbogbo ọjọ.

Bayi ni Ọlọrun rán ounjẹ si wọn lati Ọrun wá fun ogoji ọdun. Ebi kò pa wọn rara. Ọlọrun fun wọn ni okun ati agbára lati rin lọna ajo wọn si ibi ti Ọlọrun n mu wọn lọ.

Ọlọrun paṣẹ fun wọn lati fi ninu ounjẹ naa pamọ, ki awọn ọmọ wọn le mọ iru ounjẹ ti Ọlọrun fi bọ wọn, lati rán wọn leti oore ati aanu ati agbára Ọlọrun lati tọju wọn nibi gbogbo.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Tani awọn Ọmọ Israeli kun si? Edsodu 6:*

  2. 2 Njẹ Ọlọrun fẹ ki a kùn? Filippi 2:14

  3. 3 Iru ounjẹ wo ni Ọlọrun ran si wọn? Eksodu 6:3, 31

  4. 4 Ọeun melo ni wọn fi jẹ Manna? Eksodu 16:25