Eksodu 17:1-16

Lesson 26 - Elementary

Memory Verse
“Bi òrùngbẹ ba ngbẹ ẹnikẹni, ki o tọ mi wá, ki o si mu” (Johannu 7:37).
Notes

Bi Ọlọrun ṣe itọju awọn Ọmọ Israẹli to ninu irin-ajo wọn lọ si Ilẹ Ileri, wọn ki i pé̩ gbagbe oore Ọlọrun nigba ti iṣoro ba de ba wọn.

Ọlọrun fi ikuuku funfun ṣe amọna wọn ni ọsan ati ọwọn iná ni òru. Nigba ti omi koro, Ọlọrun mu un dùn, nigba ti ebi n pa wọn, Ọlọrun fun wọn ni ounjẹ didùn jẹ.

Bawo ni i ba ti dara fun wọn to, bi wọn ba ṣiro gbogbo ibukun wọnyii, ki wọn si ni ọkàn ọpẹ si Ọlọrun nigba gbogbo.

Nisisiyii oungbẹ n gbẹ wọn ati awọn ẹran wọn. Ko si omi lati mu. Wọn ti gbagbe pe Ọlọrun ti fun wọn ni omi tẹlẹ ri. Wọn bẹrẹsi kùn. Ọlọrun ti O n mu wọn lọ si Ilẹ Ileri ni wọn n kùn si, ki i ṣe Mose. Ọlọrun mọ gbogbo iṣoro ti o wà lọna, O si le mu wọn bori gbogbo rè̩ bi wọn ba gbẹkẹle E.

O yẹ ki Ọlọrun jẹ wọn niya, ṣugbọn Ó ṣaanu fun wọn. O paṣẹ fun Mose lati fi ọpa rè̩ lu apata, omi si tú jade lọpọlọpọ fun awọn eniyan naa lati mu. Ọlọrun nikan ni o le té̩ wa lọrun.

Ọlọrun nikan ni o le mu omi jade lati inu apata; ko si ohun ti o ṣoro fun Ọlọrun. O yẹ ki wọn gbẹkẹle Ọlọrun ki wọn má si ṣe kùn. Nigba ti wọn kùn, Ọlọrun ti o ṣe wọn ni oore ni wọn n kùn si. O yẹ ki wọn ni ọkàn ọpé̩ si Ọlọrun ti o n tọju wọn nigba gbogbo, nigba aini ati nigba iṣoro wọn.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni ṣe ti awọn Ọmọ Israeli fi kùn? Ẹksodu 17:3

  2. 2 Inu Ọlọrun ha dùn si kikùn wọn? Orin Dafidi 78:18-21

  3. 3 Ki ni Ọlọrun paṣẹ fun Mose lati ṣe? Ẹksodu 17:5, 6

  4. 4 Ta ni mu omi jade lati inu apata? Ẹksodu 17:5, 6

  5. 5 Ta ni gbé ọwọ Mose soke? Ẹksodu 17:12