Lesson 27 - Elementary
Memory Verse
“Ẹ mā tọ mi lẹhin, emi ó si sọ nyin di apẹja enia” (Matteu 4:19)Notes
A kò le gbagbe òkun Galili nitori igba gbogbo ni Jesu maa n lọ sibẹ. Oun a maa wo awọn apẹja bi wọn ti n fi awọn wọn kó ẹja lati inu òkun. Nigba kan Jesu paṣẹ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lati ju iwọ sinu omi, O si sọ fun wọn pe wọn yoo ri owó lẹnu ẹja ti wọn ba kọ mu jade. Ki i ṣe gbogbo ẹja ni a le ri owó lẹnu rè̩. Jesu nikan ni O le fi owó sibẹ bi O ba fẹ.
Ki i ṣe gbogbo ẹja ni o dara fun jijẹ. Eyi ti kò dara ni a maa n sọnu. Eniyan rere ati buburu ni wọn wà ni ayé. Awọn eniyan rere ti wọn fẹ Jesu yoo lọ si Ọrun rere ṣugbọn awọn eniyan buburu yoo lọ si ibi ti wọn yoo gbé maa jiya titi lae fun iwa buburu wọn.
Ni odo Galili ni Jesu gbé pe Peteru ati Anderu lati tẹle E ki Oun le sọ wọn di apẹja eniyan, ki wọn le lọ lati waasu fun awọn eniyan lati kọ è̩ṣẹ wọn silẹ ki wọn ba le lọ si Ọrun rere.
O si tun pe Jakọbu ati Johannu pẹlu. Gbogbo wọn tẹle Jesu tọkàntọkàn. Inu Jesu a maa dùn bi a ba tẹle E nigba ti O ba pe wa.
Nihin ni Jesu gbé paṣẹ fun Peteru lati ti ọkọ sinu ibu lati kó ẹja. O gbọran, o si kó ẹja pupọ. Idi rè̩ ti o fi kó ẹja pupọ ni pe o gbọran si aṣẹ Jesu.
Òkun Galili fè̩ o si gùn pupọ, nigbakuugba ni igbi maa n jà nibẹ. Lọjọ kan bi Jesu ati awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ti n kọja lori òkun yii, igbi dide o si bo ọkọ mọlẹ. Jesu a maa ṣiṣẹ pupọ. O n waasu, O n kọ ni, O si n mu ni larada. A maa rẹ Jesu bi awa. Arẹ mu Un, O si sùn. Awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ tọ Ọ wa pe, Oluwa, gbà wa, awa gbé.” Bi Jesu ba wa lọdọ wa a kò gbọdọ bẹru. Lẹsẹkẹsẹ ti awọn ọmọ-ẹyin tọ Ọ wá, O bá afẹfẹ wí, idakẹrọrọ si dé. Ẹnu ya awọn ọmọ-ẹyin Rè̩.
Lẹyin ti wọn ti wà pẹlu Rè̩ wọn mọ pe O le jí oku dide, O le wo ni sàn, O si ni agbára lati dá igbi duro. O ni agbára lori ohun gbogbo. Wọn mọ pẹlu pe Ọmọ Ọlọrun ni Oun I ṣe.
Questions
AWỌN IBEERE1 Ki ni Jesu n ṣe nigba ti igbi dide? Matteu 8:24
2 Ta ni dá igbi naa duro? Matteu 8:26
3 Ki ni awọn eniyan yii sọ fun Jesu? Matteu 8:27
4 Njẹ ohun kan wà ti Jesu kò le ṣe? Matteu 28:18
5 Njẹ Peteru gbọran nigba ti Jesu sọ fun un lati ju àwọn rè̩ sinu odò? Luku 5:5