Lesson 28 - Elementary
Memory Verse
“Ohunkohun bi o ba wi fun nyin, ẹ ṣe e” (Johannu 2:5)Notes
Jesu lọ sọdọ Johannu ki ó le ṣe iribọmi fun Un. Johannu si ṣe iribọmi fun Un. Jesu fẹ lati mu gbogbo Ọrọ Ọlọrun ṣẹ. Inu Ọlọrun dùn si I gidigidi; bakan naa ni inu Ọlọrun maa n dùn si ẹnikẹni ti o ba fẹ Ẹ ti o si gbọran si I lẹnu. Ohun ti Ọlọrun ba wi ni Jesu maa n ṣe nigba gbogbo.
Jesu fé̩ lati ràn wá lọwọ ati lati wà pẹlu wa nigba gbogbo, yala nigba aisàn, nigba ayọ tabi nigba iṣoro. O wá si ayé lati fun wa ni ayọ titi lae. Awọn ti o bá fẹran Jesu ti wọn ba si gbọran si I lẹnu a maa ni ayọ nigba gbogbo. Ọlọrun fun wa ni awọsanma daradara, igi eleso, ewebẹ ti o tutu yọyọ, itanna oloorun didùn ati awọn ẹyẹ ti n kọrin didùn. O fi nnkan wọnyii fun wa lati mú inu wa dùn.
Lẹyin awọn obi wa ti o fé̩ wa ati awọn arakunrin wa, Ọlọrun fun wa ni awọn ọrẹ rere. Olukuluku wa ni a fẹ ni ọrẹ ti yoo wà pẹlu wa nigba ayọ ati igba iṣoro. Bibeli sọ fun wa pe Jesu paapaa ni awọn ọrẹ ti o ṣọwọn pupọ fun Un. Oun ko ni ile ti Rè̩, ṣugbọn Iwe-Mimọ sọ fun ni pe Oun a maa lọ si ile awọn ọrẹ Rè̩ Maria, Marta ati Lasaru lati sinmi. Awọn ẹlomiran a maa pe E lọ si ile wọn lati jẹun. Oun a si lọ ki o ba le ni anfaani lati sọ Ọrọ Ọlọrun fun wọn.
Nigba kan a pe E lọ si ibi igbeyawo kan ni Kana ti Galili. Kana kò jinna si ilu Rè̩. Iya Jesu ati awọn ọmọ-ẹyin wa nibẹ pẹlu. Ki ariya yii to pari, waini tán. Iya Jesu tọ Ọ wa lati sọ fun Un ki O fun awọn eniyan ni waini mu. Gbogbo wa ni o fẹran Coca-Cola ti a le fi wé eso ajara. Ọlọrun ti fun wa ni ohun mimu ti o dara, ṣugbọn awọn eniyan a maa ba a jé̩ nigba ti wọn ba sọ ọ di ọti lile.
Maria sọ fun awọn iranṣẹ pe ki wọn ṣe ohunkohun ti Jesu ba palaṣẹ fun wọn. Maria mọ pe Jesu ni agbára lati ṣe ohun gbogbo. O yẹ ki a ṣe ohunkohun ti Jesu ba palaṣẹ fun wa lẹsẹkẹsẹ ti O ba sọ fun wa. Wọn pọn omi sinu ikoko. Jesu sọ ọ di waini didùn. Gbogbo ohun ti Jesu ba ṣe ni o dara. Eyi ni iṣẹ iyanu kin-in-ni ti Jesu ṣe ti O fi hàn fun awọn ọmọ-ẹyin ati ọrẹ Rè̩ pe alagbara ni Oun I ṣe.
Questions
AWỌN IBEERE1 Ki ni Maria sọ fun awọn iranṣẹ? Johannu 2:5
2 Njẹ awọn iranṣẹ mọ ẹni ti O sọ omi di waini?
3 Njẹ waini daradara ni Jesu ṣe? Johannu 2:9
4 Ki ni Jesu ṣe fun awọn ti wọn n taja ni Tẹmpili? Johannu 2:15
5 Ki ni Jesu ṣe fun awọn ti o n ta adaba ninu Tẹmpili? Johannu 2:16