Johannu 3:1-21

Lesson 29 - Elementary

Memory Verse
“A kò le ṣe alaitún nyin bi” (Johannu 3:7).
Notes

Ọrun jé̩ ibi ti o dara pupọ. Kò si ibi ti o dara to o laye yii. Jesu sọ pe Oun n lọ lati pese àye silẹ fun awọn ti o ba fẹ Ẹ, a si mọ pe ibi ti Jesu bá pese ni o dara jù lọ. Ohun adùn ni lati wà pẹlu awọn eniyan rere, ṣugbọn a mọ pe ohun ti o dara jù lọ ni lati wà lọdọ Ọlọrun ati Jesu, Ọrẹ ti o dara jù lọ ni ayé ati ni Ọrun. Nigba ti a ba dé Ọrun a o wà nibẹ titi ninu ayọ ti kò ni opin.

Jesu wá si ayé lati kú ati lati gba iya wa jẹ ki a le yẹ fun Ọrun rere. Ibi mimọ ni Ọrun i ṣe. Iwa buburu ati eeri kò le wọ ibè̩. Ẹjẹ Jesu ni lati wẹ è̩ṣẹ ati iwa buburu kuro ni ọkàn wa ki a to le de Ọrun. Ibi rere ni Ọrun i ṣe. Ọrun kò ni jé̩ ibi ti o dara bi awọn eniyan buburu bá wà nibè̩. A ni lati wẹ è̩ṣẹ kuro ni ọkàn awọn eniyan ki wọn to le wà pẹlu Ọlọrun ni Ọrun.

Olukọni kan ti o yẹ ki o mọ ohun ti oun ni lati ṣe lati wà ni imurasilẹ fun Ọrun tọ Jesu wá. O sọ pe oun mọ pe Olukọni ni Jesu i ṣe lati ọdọ Ọlọrun wá ati pe kò si ẹni ti o le ṣe iṣẹ iyanu ti Jesu n ṣe.

Jesu wi fun Nikodemu pe a ni lati tún eniyan bí ki o to le wọ ijọba Ọrun. Ohun ti Jesu sọ kò yé e, ṣugbọn a gbagbọ pe Jesu la a ye e pe eniyan ni lati kaanu fun iwa buburu ti o n hù – olè, irọ, ibura, ibinu, ikorira ati iwa buburu gbogbo – ki o si ronupiwada. O ni lati gbadura ki Ọlọrun dariji oun, nigba naa Oun yoo wẹ ọkàn rè̩ mọ laulau.

Jesu a maa fun ni ni ọkàn ti o fẹran Rè̩, ti o si korira ibi. Nigba ti Ọlọrun ba ti wẹ ọkàn wa nù, nigba naa a di “atunbi.” Ọlọrun fẹ ki gbogbo eniyan di atunbi, eyi yii ni pe ki wọn ni igbala.

Jesu wá si ayé lati kọ ni bi a ṣe le ni igbala, O si sa gbogbo ipá Rè̩ lati kọ ni bi a ṣe le ri idariji è̩ṣẹ wa gbà ki a si kà wá yẹ fun Ọrun lati wà pẹlu Jesu ninu Ile ti O ti pese silẹ fun wa.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni a ni lati ṣe ki a le wà ni imurasilẹ fun Ọrun? Johannu 3:3

  2. 2 Njẹ Nikodemu mọ bi oun ṣe le ri igbala ki Jesu to sọ fun un? Johannu 3:4

  3. 3 Njẹ Jesu a maa ta ẹni ti ọkàn rè̩ n poungbẹ fun otitọ nù?

  4. 4 Ki ni ohun ti Jesu ṣe lati gbà wá là? Matteu 26:28

  5. 5 Njẹ Ọlọrun fẹran gbogbo eniyan? Johannu 3:16