Johannu 4:1-42

Lesson 30 - Elementary

Memory Verse
“Ati ẹniti ongbẹ ngbẹ ki o wá” (Ifihan 22:17).
Notes

Ki i ṣe gbogbo wa ni o ti ri kanga ti a n lò ki ẹrọ afami to de. Awa ti o ni omi ọpọlọpọ kò mọ riri rè̩ bi awọn wọnni ti wọn wà nibi ti omi gbé ṣọwọn. A kà ninu Iwe Mimọ pe Abrahamu a maa tẹ pẹpẹ a si maa wa kanga nibikibi ti o ba de. Mejeeji ni o ṣe pataki. Ni ilu miiran, awọn eniyan a maa wa kanga ti o jìn ni ogun ẹsè̩ tabi ọgbọn ẹsè̩. Wọn a so okùn mọ koroba lati fi fa omi jade lati inu kanga.

Ni ọjọ kan aarẹ mu Jesu pupọ lẹyin ti O ti waasu ti O si ti rìn pupọ. O duro nibi kanga ti Jakọbu ti wà ni ọdun pupọ sẹyin. Kanga yii jìn to ọgọrun ẹsè̩, o si wà nibẹ di oni-oloni. Nigba ti Jesu joko nibẹ ti O n sinmi, obinrin kan dé pẹlu ikoko omi ati koroba ti o ti so okùn mọ lati fi pọn omi. Jesu beere pe ki o fun Oun ni omi mu. Jesu si sọ fun obinrin naa pe Oun yoo fun un ni omi kan mu to bẹẹ ti oungbẹ ki yoo tun gbẹ é̩ mọ lae bi Oun bá fun un ni omi mu. Obinrin yii kò mọ iru omi ti eyi le jẹ. O wi fun Jesu pe kanga naa jìn, bẹẹ ni Jesu kò si ni okun ati koroba ti yoo fi fa omi lati inu kanga naa. Obinrin yii n fẹ mọ bawo ni Jesu yoo ṣe le fun oun ni omi mu. Jesu fi ye e pe idariji è̩ṣẹ ati agbára lati gbé igbesi ayé rere ni Oun fi wé “omi iye.”

Bi o ba mu un, oungbẹ ki yoo gbẹ é̩ mọ lae. Lẹsẹkẹsẹ o mọ pe Jesu ni O n bá oun sọrọ. Obinrin yii sare lọ si ilu lati sọ ohun ti o ri fun wọn. Lẹsẹkẹsẹ, awọn eniyan sare wá si ọdọ Jesu. Jesu kọ wọn ni ohun ti o yẹ fun wọn lati mọ.

Dajudaju Jesu ti mọ tẹlẹ pe obinrin yii yoo wá fa omi ni akoko naa, nitori naa ni O ṣe wá pade rè̩ lati kọ ọ nipa bi o ṣe le ri igbala. Jesu ṣe tán nigba gbogbo lati ràn wá lọwọ. O yẹ ki a maa dupẹ fun Un ki a si fi gbogbo ọkàn wa fẹ Ẹ. A mọ pe obinrin yii fẹran Jesu nitori ohun ti O ti ṣe fun un.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni ṣe ti Jesu fi joko leti kanga? Johannu 4:6

  2. 2 Ki ni ohun ti Jesu sọ fun obinrin naa? Johannu 4:7

  3. 3 Njẹ obinrin naa tete mọ pe Jesu ni? Johannu 4:9

  4. 4 Iru “omi” wo ni Jesu n sọrọ rè̩? Johannu 4:10

  5. 5 Ki ni obinrin naa ṣe lẹyin ti o mọ Jesu? Johannu 4:28, 29