Matteu 8:1-16

Lesson 32 - Elementary

Memory Verse
“Nitori ohun gbogbo ni ṣiṣe fun Ọlọrun” (Marku 10:27).
Notes

Ko pẹ fun awọn eniyan lati mọ pe Jesu lagbara lati wo àrun wọn sàn. O laju afọju, O mu ki arọ rin, O n ji oku dide. Awọn eniyan a maa gbé awọn alaisan wọn tọ Ọ wá. Awọn eniyan a maa tọ Ọ lọ si ibikibi ti o ba n lọ. Gbogbo awọn ti o ba tọ Ọ wá ni O n ràn lọwọ. A dupẹ lọwọ Ọlọrun pe agbára Rè̩ wà sibẹ lati wo alaisan sàn lonii.

Awọn ẹlomiran rò pe ko le wo aisan nla sàn ṣugbọn Bibeli sọ fun ni pe gbogbo arun ni O n wò sàn. Oun ni o dá ara, kò si ṣoro fun Un lati wo o sàn. Ni ọjọ kan adẹtẹ kan tọ Ọ wá fun iwosan. Boya o ni egbo pupọ lara, ti awọn eniyan ko si fẹ sún mọ ọn. Nigba ti o foribalẹ fun Jesu ti o si wi pe oun gbagbọ pe Jesu le wo oun sàn, Jesu fi ọwọ kan an O si wi pe, “Iwọ di mimọ”, o si ri iwosan gbà lẹsẹkẹsẹ. O dá ni loju pe oun yoo fẹran Jesu nitori O wo o sàn.

Bakan naa ni ọmọ-ogun kan ti ara iranṣẹ rè̩ kò dá tọ Jesu wá. O gbagbọ pe bi Jesu ba ti sọrọ kan, ara iranṣẹ oun yoo dá.

Jesu fẹ ki awọn eniyan ni igbagbọ ninu Oun. Bi O ba ti sọrọ O fẹ ki a gbagbọ. Inu Jesu dùn nigba ti ọmọ-ogun yii gbagbọ pe Jesu le mu iranṣẹ oun lara dá. Ara ọmọ naa si dá ni wakati kan naa ti Jesu ti sọrọ.

Nigba ti Jesu dé ile Peteru. O ri i ti aisan ibà n bá iya iyawo Peteru jà. Jesu fọwọ kan an, o si dide lẹsẹkẹsẹ lati maa ṣe iṣẹ rè̩. Ko ṣoro fun Jesu lati mu ni lara dá. A ni ọrẹ ti o ṣọwọn fun wa ninu ayé ṣugbọn Jesu ni Ọrẹ ti o dara jù lọ. Ki i ṣe pe O n gbà wá là nikan, ṣugbọn O n fun wa ni ojo ati oorun ti o n mu irugbin dagba. O n fun ni ni ounjẹ ati aṣọ. O n wò wá sàn bi a ba fẹ Ẹ ti a gbadura si I, ti a gbagbọ, ti a si gbọran.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Njẹ adẹtẹ naa gbagbọ pe Jesu le wo oun sàn? Matteu 8:2

  2. 2 Njẹ olori ogun naa rò pe oun yẹ ni ẹni ti Jesu i bá wá si ile rẹ? Matteu 8:8

  3. 3 Ki ni ṣe ti ọrọ rè̩ ya Jesu lẹnu? Matteu 8:10

  4. 4 Bawo ni a ṣe wo iya iyawo Peteru sàn? Matteu 8:15