Ẹksodu 19:1-25

Lesson 33 - Elementary

Memory Verse
“Oluwa li oluranlọwọ mi” (Heberu 13:6).
Notes

Mose pẹlu awọn eniyan rè̩ ti rin ninu aginju fun iwọn oṣu mẹta. Ọlọrun tọju wọn lọna gbogbo. O n ṣe amọna wọn lọsan ati loru. O sọ omi ti o koro di dídùn. O mu omi jade lati inu apata, O rọjo manna lati ọrun wa, ebi ko si pa wọn, aṣọ wọn kò gbó. O si fun wọn ni ilera. Ọlọrun nikan ni O le pese fun gbogbo aini wa.

Ọlọrun fẹ ki awọn eniyan Oun mọ bi a ti ṣe le sin Oun ni ọna otitọ. Ọlọrun sọ fun Mose, Mose si sọ fun awọn eniyan. Wọn de ibi ti Ọlọrun yàn lati sọkalẹ sí lati bá awọn eniyan sọrọ. Ọlọrun pe Mose lọ si ori oke yii. O sọ fun un pe bi awọn eniyan naa ba gbọran, Oun yoo fun wọn ni ohun rere pupọpupọ, Oun yoo si jẹ ki inu wọn dùn. Mose sọ fun awọn eniyan, wọn dahun pe gbogbo ohun ti Oluwa wí ni “awa yio ṣe.” Awọn ẹlomiran ki i pé̩ gbagbe ileri ti wọn ṣe fun Ọlọrun ṣugbọn Ọlọrun ki i gbagbe.

Ọlọrun fẹ ki gbogbo eniyan ni ọkàn mimọ. O paṣẹ fun awọn eniyan naa lati ya ara wọn si mimọ fun ọjọ mẹta nitori Oun yoo ba wọn sọrọ lati ẹnu Mose. Ọlọrun sọ pe Oun yoo sọkalẹ sori oke naa ṣugbọn ẹnikẹni ko gbọdọ de ibi oke naa lati lọ wo o. Oke naa ti di oke iyanu nitori Ọlọkrun wà nibẹ. Ẹnikẹni ti o ba fi ọwọ kan an yoo kú.

Ni ọjọ ti Ọlọrun dá lati sọkalẹ, ara san, manamana kọ, ilẹ si mì tìtì. Ọlọrun sọkalẹ si ori oke. O pe Mose sọdọ ara Rè̩. Mose ko jẹ daba lati lọ bi Ọlọrun ko ba pe e. Ọlọrun sọ ohun ti Oun fé̩ ki a fi kọ awọn eniyan naa fun Mose ati Aarọni. Awọn ohun ti wọn tun jẹ iranlọwọ fun wa lonii. O kọ wọn lati fẹran Rẹ ati lati gbẹkẹle E. Wọn o layọ bi wọn ba ṣe ohun ti Ọlọrun palaṣẹ. Bi awa naa ba ṣe ohun ti Ọlọrun palaṣẹ, a o ni ayọ, a o si ni idaniloju pe a o lọ si Ọrun rere lati bá Ọlọrun gbé titi lae.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni Mose ṣe ki awọn eniyan maa ba de oke naa? Ẹksodu 19:12

  2. 2 Ki ni ohun ti yoo ṣẹlẹ bi ẹnikẹni ba fi ọwọ kan oke naa? Ẹksodu 19:13

  3. 3 Lọna wo ni awọn eniyan gba mura silẹ de igba ti Ọlọrun yoo ba wọn sọrọ? Ẹksodu 19:14, 15

  4. 4 Ki ni ṣẹlẹ si oke naa nigba ti Ọlọrun sọkalẹ? Ẹksodu 19:18