Eksodu 20:1-26

Lesson 34 - Elementary

Memory Verse
“Emi ni; ẹ má bè̩ru” (Johannu 6:20).
Notes

Nigba ti awọn eniyan ri manamana ati eefin, ti wọn gbọ sisán aara, wọn mọ pe Ọlọrun wà lori oke. Mose sọ fun wọn ki wọn má ṣe bẹru bi wọn ba ti ṣe ohun ti Ọlọrun sọ fun wọn. Ẹru bà wọn lati gbọ ohùn Ọlọrun nitori naa wọn sọ fun Mose lati maa bá wọn sọrọ. Ọlọrun sọrọ lati ori oke lọna ti awọn eniyan le gbọ. O sọ fun wọn pe Oun ni Oluwa Ọlọrun ti O mú wọn jade lati Egipti wá ti O ṣe itọju wọn ni gbogbo irin ajo wọn. O fẹ ki wọn mọ pe wọn ni lati gbẹkẹle Oun ki wọn si gbọran.

Ọlọrun sọ ohun ti a ni lati ṣe fun Oun ati ohun ti a ni lati ṣe si ẹlomiran. O sọ pe ki a fẹran Ọlọrun ju ohun gbogbo lọ.

O tun sọ pe a kò gbọdọ bọ oriṣa. A ko gbọdọ bura.

A ni lati bu ọla fun Ọlọrun ki a si bọwọ fun obi wa.

A kò gbọdọ paniyan

A kò gbọdọ jale

A kò gbọdọ purọ

A kò gbọdọ ṣojukokoro si ohun ẹlomiran.

Ọlọrun pe Mose sọdọ ara Rè̩ lori oke O si fun un ni awọn walaa okuta lori eyi ti O ti kọ Ofin si. Mose wà ni ori oke fun ogoji ọjọ, Ọlọrun si sọ ohun ti o yẹ ki awọn eniyan mọ fun un.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ta ni fun Mose ni Ofin Mẹwaa?

  2. 2 Njẹ aya awọn eniyan yii já nigba ti isẹlẹ sè̩ lori oke Sinai? Ẹksodu 20:18

  3. 3 Ki ni awọn eniyan sọ fun Mose lẹyin ti o pari ọrọ isọ?

  4. 4 Kọ Ẹksodu ori 20 ẹsẹ 3 ati 12 sori.