Eksodu 32:1-35; 34:1-7, 33-35

Lesson 35 - Elementary

Memory Verse
“Ko si ẹniti o le sin Oluwa meji” (Matteu 6:24).
Notes

Nitori Mose pé̩ lori oke nibi ti o gbé n bá Ọlọrun sọrọ, awọn eniyan rò pe kò ni pada wa mọ. Wọn n fẹ oriṣa. O yẹ ki wọn mọ pe oriṣa ko le ṣe alakoso wọn gẹgẹ bi Mose ati pe ohun ti ko dara ni lati sin oriṣa dipo Ọlọrun.

Wọn ti gbagbe oore Ọlọrun si wọn. Aaroni sọ fun wọn lati mu oruka-eti ti tọkunrin-tobinrin n lò nigba ni wá.

Ọlọrun ti mọ ohun ti wọn n ṣe, O sọ fun Mose lati sọkalẹ lọ nitori awọn eniyan naa n ṣe ohun ti kò dara. Ọlọrun sọ pe Oun yoo jẹ wọn niya pupọpupọ. Nigba ti Mose ri ti wọn n jó yí oriṣa ká, o sọ walaa okuta ọwọ rè̩ silẹ, wọn si fọ, O mu oriṣa naa, o gbe e sinu iná, o yọ ọ, o lọ ọ luuluu o si fi sinu omi fun awọn eniyan naa mu.

Wọn ṣe ohun buburu oun si ni lati jẹ wọn niya nitori wọn sin oriṣa, wọn ko bu ọla fun Ọlọrun.

Ọlọrun kò fẹ ba wọn lọ mọ nitori aigbọran wọn, ṣugbọn Mose bẹ Ọlọrun lati ṣaanu fun wọn ki O si maa ba wọn lọ.

Ọlọrun dariji wọn. Alaanu ni Ọlọrun, Oun a maa dariji ẹnikẹni ti o ba kaanu fun ẹṣẹ wọn ti wọn si gbadura si I pe ki O dariji wọn. Ọlọrun sọ fun Mose lati gbé̩ walaa okuta meji miiran, Oun yoo si tun kọ ohun ti o wà ninu ti iṣaaju si. Ọlọrun sọ fun Mose pe ki yoo ri Oun lojukoju. O sọ fun Mose pe Oun yoo kọja lọdọ rè̩ ṣugbọn Oun yoo fọwọ bo o loju, ẹyin Rè̩ nikan ni Mose yoo ri.

Mose ṣe ohun ti Ọlọrun palaṣẹ. Ọlọrun kọja lọdọ Mose, O si wi pe, Ọlọrun Alaanu, Oloore-ọfẹ ati Ẹni rere. Awa naa mọ pe Oun ko i ti i yipada. A ni lati dupẹ pe a ni Ọlọrun ati Baba Onibu-ọrẹ ati Jesu, Ọrẹ ti o dara ju lọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni Aaroni gbé kalẹ fun awọn eniyan lati sìn?

  2. 2 Njẹ Ọlọrun ri i?

  3. 3 Ki ni O wí fun Mose?

  4. 4 Ki ni Mose ṣe nigba ti o ri ẹgbọrọ maluu naa?

  5. 5 Ki ni ṣe ti Mose fi iboju bo oju rè̩?