Numeri 12:1-16

Lesson 37 - Elementary

Memory Verse
“Ẹ mā ṣe ohun gbogbo li aisi ikùnsinu (Filippi 2:14).
Notes

A kò le gbagbe itan Mose, ọmọdekunrin ti a gbé sinu agbọn ninu odò. Arabinrin rè̩ ti o duro lokeere ti o ṣọ ọ ni Miriamu. Mose ni arakunrin kan ti a n pè ni Aarọni. Ọlọrun ti yan Mose lati ṣe alakoso awọn Ọmọ Israeli. Aarọni ati Miriamu si ti ràn án lọwọ, nigba pupọ. Ọlọrun fẹran Aarọni. Ọlọrun pe e si ori oke nigba ti o pe Mose pẹlu. S̩ugbọn nigba miiran Aarọni ati Miriamu a maa ṣe ohun ti kò dùn mọ Ọlọrun, eyi a si mú inu Mose bajẹ.

Inu Mose bajẹ pupọ nigba ti Aarọni gbe ere maluu kalẹ fun awọn eniyan, nigba ti Mose wà pẹlu Ọlọrun ni ori oke. Bi Mose tilẹ pé̩, o yẹ ki wọn mọ pe Ọlọrun ni wọn ni lati sìn, wọn si mọ pe Ọlọrun a maa ràn wọn lọwọ ni idahun si adura Mose. Arakunrin ati arabinrin le ran ara wọn lọwọ lọpọlọpọ bi wọn ba fẹran ara wọn ti wọn fé̩ Jesu pẹlu. Bi wọn kò ba ni Jesu lọkan wọn ti wọn si n jà, eyi yoo mú wahala ati ibanujẹ bá wọn. Ọlọrun ti sọ fun awọn eniyan tẹlẹ tẹlẹ pe bi wọn ba kùn, ki i ṣe Mose ni wọn kùn si bi kò ṣe Ọlọrun. Aarọni ati Miriamu rò pe Mose arakunrin wọn ni wọn kùn si. Ọlọrun si gbọ kikùn wọn. Bi ọmọde ba kùn si ojiṣẹ Ọlọrun tabi olukọ ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi, Ọlọrun gan an ni o kùn si. A ni lati gbọran si awọn ti o n kọ wa ni ilana Ọlọrun. Ọmọde ti o ba kùn si obi rè̩, o kùn si Ọlọrun pẹlu. Nitori Ọlọrun wi pe, “Ẹ mā ṣe ohun gbogbo li aisi ikùnsinu ati ijiyan”, nitori naa ọmọde ni lati gbọran si obi rè̩ lẹnu.

Ọlọrun sọkalẹ si ẹnu ọna agọ, O si bá Aarọni ati Miriamu wí fun è̩ṣẹ wọn, Miriamu si di adẹtẹ. Ẹtẹ jé̩ àrun ti o buru lọpọlọpọ, ṣugbọn è̩ṣẹ ninu ọkàn wa buru ju arun è̩tè̩. Ẹjẹ Jesu le wo adẹtẹ sàn. Ẹjẹ Jesu nikan ni o le mú è̩ṣẹ kuro. Mose gbadura fun Miriamu Ọlọrun si wò ó sàn, ṣugbọn o wà lẹyin ibudo fun ọjọ meje. Eyi jé̩ ẹkọ fun Miriamu ati awọn ti igba ni ati awa ti isisiyii pẹlu. A kò gbọdọ gbagbe pe Ọlọrun kò fẹ ki a maa kùn.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Njẹ o tọ fun Aarọni ati Miriamu lati kùn si Mose?

  2. 2 Ki ni iyà ti o bá Miriamu nitori o kùn? Numeri 12:10

  3. 3 Ta ni gbadura fun iwosan rè̩? Numeri 12:15

  4. 4 Ọjọ meloo ni o fi wà lẹyin ibudo? Numeri 12:15

  5. 5 Njẹ Jesu fẹ ki a kùn? Filippi 2:14

  6. 6 Ta ni a n kùn si nigbakigba ti a ba kùn?