Numeri 13:1-33; 14:1-45

Lesson 38 - Elementary

Memory Verse
“Emi nlọ ipèse àye silẹ fun nyin” (Johannu 14:2).
Notes

Nigba ti awọn eniyan dé itosi ilè̩ ti wọn n lọ, Ọlọrun sọ fun Mose lati rán eniyan mejila lati lọ wo bi ilẹ naa ati awọn eniyan ti n gbé inu rè̩ ti ri. Nipa bẹẹ, wọn o mọ bi wọn yoo ṣe gba ilẹ naa nitori Ọlọrun ti ṣeleri lati fi i fun wọn. Lẹyin ogoji ọjọ, wọn pada, wọn si mu eso ajara lọwọ lati ibè̩ wá, wọn wi pe awọn eniyan naa lagbara pupọ, wọn bá Mose wí nitori o mu wọn jade wá sibẹ lati wá jà ki wọn to gba ilẹ naa. S̩ugbọn meji ninu awọn ọkunrin mejila ti o lọ wo ilẹ naa ni igbagbọ ninu agbára Ọlọrun. Kalebu ati Joṣua mọ pe Ọlọrun ti ṣeleri lati fun wọn ni ilẹ naa, yoo si ràn wọn lọwọ lati gba a, nitori kò si ohun ti o ṣoro fun Ọlọrun.

Inu Ọlọrun kò dùn si ijọ awọn eniyan yii nitori wọn kò gba ileri Rè̩ gbọ, O si jẹ wọn niya nitori aigbọran wọn. Dipo ti wọn i ba fi lọ si ilẹ daradara naa, wọn n rin kiri ni aginju fun ogoji ọdun nibi ti wọn gbé ni wahala ati iṣoro pupọ. Gbogbo awọn ti o bá wọn jade ni Egipti kò le de ilẹ rere naa. Awọn ọdọmọde ti ko to ọmọ ogun ọdun nigba ti wọn jade nikan ni o dé ilẹ naa.

Ọlọrun jẹ awọn ọkunrin mẹwaa ti o mú iroyin buburu wá niyà. Aisàn kọlu wọn, wọn si kú. S̩ugbọn a kò jẹ Kalebu ati Joṣua niya. Ohun ti o buru ni lati ṣaigbọran si Ọlọrun ki a má si gbẹkẹle E. Nigbakigba ti Ọlọrun ba paṣẹ fun wa lati ṣe ohun kan, Oun yoo ràn wa lọwọ bi a ba gbọran bi o ti wù ki ohun ti a fun wa ṣe ti ṣoro to.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Iru eso wo ni awọn ti o lọ wo ilẹ naa mú wá? Numeri 13:23

  2. 2 Ki ni Joṣua ati Kalebu sọ nipa ilẹ naa? Numeri 13:40; 14:7-9

  3. 3 Ki ni awọn mẹwaa iyoku wí? Numeri 13:31-33

  4. 4 Ki ni ṣẹlẹ si awọn ti o mu iroyin buburu wá? Numeri 14:36, 37

  5. 5 Njẹ a jẹ Joṣua ati Kalebu niyà? Numeri 14:38