NUMERI 22:1-41; 23:1-30

Lesson 39 - Elementary

Memory Verse
“Oluwa rán angẹli rè̩” (Iṣe Awọn Aposteli 12:11)
Notes

Awọn orilẹ-ède ti ko sin Ọlọrun otitọ gbọ bi Ọlọrun ti ran awọn Ọmọ Israẹli lọwọ lati ṣẹgun orilẹ-ède pupọ. Awọn ọba miiran ṣe oninuure, wọn jẹ ki awọn Ọmọ Israẹli kọja laaarin ilu wọn, ṣugbọn awọn miiran buru, wọn si gbógun ti wọn lati le dá wọn duro. Ọlọrun bukun awọn ti o fi ojurere hàn fun awọn eniyan Rè̩, O si jẹ awọn ti o hu iwa buburu si wọn niya.

Ọba kan ti a n pè ni Balaki n bẹru pe awọn Ọmọ Israeli yoo gba ilẹ oun. O bẹ Balaamu ẹni ti o dabi ẹni pe o n sin Ọlọrun lati gbadura si Ọlọrun ki O má ṣe ran awọn Ọmọ Israeli lọwọ mọ, O ṣeleri lati fun Balaamu ni owó pupọ. Balaamu fẹ gbọ ti ọba yii nitori owó. Ọlọrun kilọ fun un pe ki o má ṣe fi awọn eniyan Oun bú. Balaki bẹrẹ si i yọ Balaamu lẹnu. Balaamu fẹ gbọ ti ọba yii nitori owó. Ọlọrun si mọ ero ọkàn rè̩; nitori naa Ọlọrun gba a laye lati lọ.

Ọlọrun a maa dá wa lẹkun lati ṣe ohun ti kò tọ, ṣugbọn ki i ṣe igba gbogbo ni a n gbọran. O rán angẹli kan lati fa idà yọ ki o si duro si ọna ti Balaamu yoo gbà kọja. Kẹtẹkẹtẹ ri angẹli naa ṣugbọn Balaamu kò ri i. Kẹtẹkẹtẹ naa yà si è̩gbé̩ ogiri, o si rin ẹsè̩ Balaamu mọ ogiri, Balaamu si lu u. Kẹtẹkẹtẹ naa ṣubu lulẹ, o si tubọ lù ú.

Nigba naa ni Ọlọrun fún kẹtẹkẹtẹ naa ni agbára lati sọrọ, o si beere idi rè̩ ti Balaamu fi n lu on. Balaamu dahun pe oun i ba tilẹ pa a bi idà ba wà ni ọwọ oun. Inu ti bi i, ṣugbọn Ọlọrun ṣí Balaamu loju o si ri angẹli ti o fa idà yọ. Ọlọrun sọ fun un pe kẹtẹkẹtẹ naa ni ko jẹ ki angẹli ti pa a. Balaamu si mọ pe Ọlọrun ni O lo kẹtẹkẹtẹ naa lati kilọ fun oun ki oun má ṣe huwa buburu. Ọlọrun mu ki Balaamu súre fun awọn eniyan naa kàkà ki o fi wọn bú. Balaamu mọ pe Ọlọrun n ran awọn Ọmọ Israeli lọwọ, ṣugbọn ọkàn rè̩ ko ṣe deedee pẹlu Ọlọrun, nitori o fẹran owó ju Ọlọrun lọ. Nikẹyin Balaamu kú si oju ogun.

Nigba miiran awọn ọmọde a maa bẹbẹ lati ṣe ohun ti obi wọn ti kọ fun wọn. Ọlọrun mọ ohun ti o tọ, bi O ba si kọ fun wa lati ṣe ohunkohun O mọ pe ko tọ fun wa lati ṣe e ni. Ko yẹ ki Balaamu fẹ lati ṣe ohun ti Ọlọrun kọ fun un lati ṣe.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Njẹ inu Ọlọrun dùn si pe ki Balamu lọ sọdọ awọn alade Moabu? Numeri 22:22

  2. 2 Ki ni ṣe ti Balaamu fẹ lati lọ? Numeri 22:17

  3. 3 Ki ni Balaamu ṣe si kẹtẹkẹtẹ rè̩ nigba ti o yà kuro loju ọna? Numeri 22:23

  4. 4 Ki ni Balaamu ṣe nigba ti o ri angẹli nì? Numeri 22:31