Lesson 40 - Elementary
Memory Verse
“Oluwa yio si gbé e dide” (Jakọbu 5:15).Notes
Inu wa dùn pe ifẹ Jesu ni lati wo gbogbo arun wa sàn. Ọlọrun ni o dá ara wa, bi ohunkohun ba bajẹ nibẹ O lagbara lati tun un ṣe ki O si mu un bọ sipo. Ọrọ Ọlọrun kọ ni pe bi a ba gbadura ti a si ni igbagbọ ninu Ọlọrun, Oun yoo wò wá sàn. A maa n pe awọn ojiṣẹ Ọlọrun pẹlu lati gbadura fun wa bi a ba ṣaisan nitori Iwe Mimọ kọ wa lati ṣe bẹẹ. Ohun ti o dara ju lọ ni lati ni Jesu lọrẹ.
Adagun kan wà ti ọpọlọpọ alaisan wà ni bèbè rè̩. Angẹli a maa rú omi naa nigba kọọkan, awọn alaisan a si maa fẹ bọ sinu rè̩ lẹyin ti angẹli naa ba ti rú u.
Jesu gba ibè̩ kọja ni ọjọ kan, O ri ọkunrin alaisan kan ti o ti wà nibẹ lati ọdun meji-din-logoji (38) sẹyin. Aanu rè̩ ṣe Jesu. Oun a maa kaanu fun gbogbo ẹni ti o ba wà ninu iṣoro. Jesu beere bi o fé̩ ki a mú oun laradá. Alaisan naa ko mọ ẹni ti Jesu i ṣe ati pe O le ṣe iwosan aisàn oniruuru gbogbo. O wi fun Jesu pe oun ko ni ẹni ti o le gbé oun sinu odo nigba ti angẹli ni ba rú u. Eredi rè̩ ni yii ti awọn ẹlomiran maa n ṣaaju rè̩ bọ sinu odò ki oun to de ibè̩.
Jesu wi fun un pe, Dide, gbé akete rẹ, ki o si mā rin.” Jesu fun un lagbara lẹsẹkẹsẹ, ara rè̩ le o si gbé akete rè̩. Bi Jesu ba paṣẹ fun wa lati ṣe ohun kan, Oun yoo fun wa lagbara lati ṣe e bi a ba gbọran. Bayii ni Jesu ṣe mu ọkunrin ti o ti n ṣaisan lati ọdun meji-din-logoji yii larada. Bawo ni inu ọkunrin yii yoo ti dùn to pe Jesu mu oun larada.
Awọn eniyan buburu kan wà nibẹ ti wọn kò fẹran Jesu. Jesu fẹ lati kọ wọn lati ṣe rere ṣugbọn wọn ko fẹ gbà. Wọn n wá ọna lati purọ mọ Jesu, ṣugbọn Jesu ki i ṣe buburu afi rere.
Awọn eniyan buburu wọnyii sọ pe ko tọ fun Jesu lati ṣe iwosan lọjọ Isinmi. Wọn sọ pe ko tọ fun ọkunrin ti a mu larada naa lati gbé akete rè̩ lọjọ Isinmi. O sọ fun wọn pe Jesu ni O sọ pe ki oun gbé akete oun. O tọ lati gbọran si Ọlọrun ju eniyan lọ. Nigba ti Jesu tun pade rè̩ O kilọ fun un ki o má ṣe dẹṣẹ mọ ki ohun ti o buru ju bẹẹ lọ ki o má ba ba a. Gẹrẹ ti ọkunrin naa mọ pe Jesu ni O mu oun larada, o bẹrẹsi sọ fun awọn ẹlomiran. Inu rè̩ dun pupọ nipa ohun ti Jesu ṣe fun un, to bẹẹ ti o fẹ sọ fun gbogbo eniyan nipa Ẹni ti o wo oun sàn.
Inu wa dun pe ẹni kan sọ fun ni nipa agbara Jesu lati gbà wá là ati lati wo wa sàn nigba ti a ba ṣaisan. A fẹ jẹ oloootọ, a si fẹ lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa Jesu. Ohun ti o ba ni ninujẹ ni pe ki i ṣe ọpọlọpọ eniyan ni o mọ nipa Jesu ati ifẹ Rè̩.
Questions
AWỌN IBEERE1 Ki ni Jesu sọ fun ọkunrin alaisan naa ti ó wà ni eti adagun Bẹtẹsda? Johannu 5:8
2 Njẹ ọkunrin alaisan naa ṣe ohun ti a palaṣẹ fun un? Johannu 5:9
3 Njẹ o mọ ẹni ti Jesu i ṣe? Johannu 5:13
4 Ki ni Jesu sọ fun ọkunrin naa ki o ma ṣe mọ? Johannu 5:14