Johannu 14:1-14

Lesson 41 - Elementary

Memory Verse
“Emi li ọna, ati otitọ, ati iye” (Johannu 14:6).
Notes

Jesu fi ile Rè̩ daradara ni Ọrun silẹ lati wá si ayé. Kò ni ile nihin. Awọn eniyan buburu korira Rè̩ nitori O sọ fun wọn pe ko dara lati ṣe ibi ati pe wọn ko ni lọ si Ọrun rere bi wọn ko ba kọ iwa buburu silè̩.

Ọrọ yii ko dun mọ wọn, nitori naa wọn n wa ọna lati pa A. O wa si aye lati gba iya wa jẹ. A kan a mọ agbelebu ki gbogbo eniyan ba le ri idariji è̩ṣẹ wọn gbà, ki wọn si le lọ si Ọrun rere lati wà pẹlu Ọlọrun ati Jesu. O maa n ba Jesu ninujẹ lati ri iwa buburu ti awọn eniyan n hù.

Inu awọn ọmọ-ẹyin Jesu bajẹ nigba ti Jesu sọ fun wọn pe Oun fẹ pada lọ si Ọrun lọdọ Baba. O sọ fun wọn nipa ibi ti O fẹ lọ pese silẹ fun wọn, ati pẹlu pe awọn ti o ba gbọran ti wọn si ṣe ohun ti Oun ba palaṣẹ Oun yoo pada wa mu wọn lọ si ile daradara yii.

O da wa loju pe ibi daradara ni Ọrun i ṣe, nitori Jesu ni O ṣe e. O lagbara lati ṣe ohun gbogbo. Oun ni O dá ohun gbogbo. Ọlọrun dá ohun daradara gbogbo fun wa. Ọrun dara ju ohunkohun ninu ayé yii.

Orin ti o dun wà lọhun ti awọn angẹli ati awọn ẹni irapada n kọ yi ité̩ ka. Ko si orin ti o dun to bẹẹ laye. Bibeli sọ fun ni nipa awọn ti yoo maa fi harpu kọrin. A gbagbọ pe ọpọlọpọ ohun elo orin ni o wà ni Ọrun ti awọn ti o ba de Ọrun yoo fi maa kọrin aladun. Ọlọrun sọ fun ni pe eti ko i ti i gbọ iru orin ti o dùn bi orin Ọrun. Bi a ba fẹ kọrin yin Ọlọrun ni Ọrun lọhun, a ni lati bẹrẹ lati ayé yii lọ.

A kà ninu Iwe Mimọ pe ko si ibanujẹ tabi ẹkún ni Ọrun; ko si aisan, bẹẹ ni ko si iku lọhun. Bawo ni yoo ti dun to lati wa nibẹ ki i ṣe fun igba diẹ, ṣugbọn titi lae. Ibi mimọ ni Ọrun i ṣe.

A ni lati gbé igbesi aye mimọ bi a ba fẹ wà nibẹ. A ni lati wẹ è̩ṣẹ wa nù ki a si sọ ọkàn wa di mimọ laulau. Jesu fi ẹmi Rè̩ lelẹ lati ṣe wa yẹ fun Ọrun. Ọkàn wa ni lati kún fun ọpé̩ si Jesu fun ohun ti O ṣe fun wa ati fun ile daradara ti O lọ pese silẹ fun wa.

Bi ẹni kan ko ba fẹ mu awọn miiran lọ si Ọrun ti o dara bayii, oluwarè̩ jé̩ anikanjọpọn. Jesu ni o le kọ wa bi a ṣe le ran awọn miiran lọwọ lati wà ni imurasilẹ nigba ti Oun yoo tun pada wa mu awọn ti o fé̩ Ẹ lọ.

Inu wa ni lati dùn pe ẹni kan sọ fun wa nipa Jesu, awa naa si ni lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa ifẹ Rè̩.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Orukọ miiran wo ni a pe Ọrun?

  2. 2 Awọn eniyan wo ni yoo lọ si ile daradara yii?

  3. 3 Ki ni eredi rè̩ ti Jesu fi wá si ayé?

  4. 4 Njẹ a mọ igba ti Jesu yoo wá lati mu wa lọ si Ọrun?

  5. 5 Awọn eniyan buburu ko ni le lọ si Ọrun. Nibo ni wọn yoo lọ?