Luku 7:36-50

Lesson 43 - Elementary

Memory Verse
“ A dari è̩ṣẹ rẹ ji ọ” (Luku 7:48).
Notes

Awọn ẹlomiran wa ti wọn fẹran Jesu. Ohun ti O n ba wọn sọ dùn mọ wọn. Wọn fẹ lati ṣe rere. Wọn ko fẹ huwa buburu. Wọn ri ohun rere gbogbo ti Jesu ṣe, wọn si fẹran Rè̩ lọpọlọpọ.

Ọpọlọpọ eniyan ni o n tẹle E, ki o ba le ràn wọn lọwọ. Aarẹ mu Un to bẹẹ ti O lọ si ori – oke lati sinmi ati lati gbadura si Ọlọrun.

Jesu fẹran lati maa lọ si ile Maria ati Marta ati Lasaru arakunrin wọn ti Jesu ji dide kuro ninu oku. Awọn pẹlu fẹran Jesu lọpọlọpọ.

Ohun ti o dara ni lati ni awọn obi ti o n gbadura ti wọn si n kọ ni ni Ọrọ Ọlọrun. Awọn ọmọde miiran wà ti ko ni awọn obi ti o le kọ wọn lati fẹran Jesu. O yẹ ki a maa gbadura fun awọn ọmọ bẹẹ, o si yẹ ki awa ti awọn obi wa jé̩ Onigbagbọ kún fun ọpé̩ si Ọlọrun.

Ọkunrin kan pe Jesu lọ si ile rè̩ lati ba a jẹun. O dùn mọ Jesu lati lo anfaani ti o ba ṣi silẹ lati sọ ti Baba Rè̩ ti ó wà ni Ọrun fun awọn eniyan. O fẹ lati sọ fun wọn nipa Ile daradara ti wọn yoo lọ bi wọn ba fẹran Jesu.

Nigba ti Jesu wà ni ile yii, obinrin kan gbé kolobo ororo olowo iyebiye ti o ni oorun didun wá. O mọ pe Jesu yoo ran oun lọwọ. O fi omije wẹ ẹsè̩ Jesu, o si fi irun ori rẹ nu un. Lẹyin naa o fi ororo daradara naa kun ẹsè̩ Rè̩.

Ọkunrin ti o pe Jesu wa jẹun ro pe obinrin yii jẹ eniyan buburu o si n fẹ ki Jesu le e lọ. S̩ugbọn Jesu fẹ lati ran obinrin yii lọwọ lati maa ṣe rere. Nigba ti o tọrọ idariji lọwọ Jesu, Jesu fi tayọtayọ dariji i.

Ifẹ Jesu ni lati dari è̩ṣẹ ọkunrin, obinrin tabi è̩ṣẹ ọdọmọde jì wọn bi wọn ba beere idariji lọdọ Rè̩.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni awọn ohun mẹrin ti obinrin naa ṣe fun Jesu? Luku 7:38

  2. 2 Ki ni ọkunrin ti o pe Jesu wa jẹun ri si eyi nì?Luku 7:39

  3. 3 Njẹ Jesu dari è̩ṣẹ obinrin yii jì í? Luku 7:48

  4. 4 Njẹ ohun ti obinrin yii ṣe fun Jesu ni o gbà á là tabi igbagbọ rè̩ ninu Jesu?

  5. 5 Njẹ a ni lati ni igbagbọ ki a to le ni igbala?