Luku 12:1-34

Lesson 44 - Elementary

Memory Verse
“Ki ohun ti ẹ ni ki o to nyin” (Heberu 13:5)
Notes

Ni ọjọ kan bi Jesu ti n waasu, ero pọ to bẹẹ ti wọn fi n tẹ ara wọn mọlẹ. O n kọ wọn ni ohun ti o yẹ ki wọn mọ ki wọn ba le lọ si Ọrun nikẹyin. O kọ wọn pe ohun ti o ṣe pataki ju lọ ni lati mọ daju pe a ni Ile kan ni Ọrun. Eyi ṣe pataki ju owó tabi ohun meremere miiran lọ.

O sọ fun wọn nipa awọn ẹyẹ. Wọn ki i ṣiṣẹ, ṣugbọn Ọlọrun n bọ wọn. Awọn itanna igbẹ ki i ṣiṣẹ ṣugbọn Ọlọrun ṣe wọn lọṣọ. Nitori naa Jesu sọ fun awọn eniyan ki wọn má ṣe ṣe iyọnu nipa ounjẹ ati aṣọ. Ọlọrun yoo fi fun wọn bi wọn ba gbọran ti wọn si ṣe ohun ti Ọlọrun wi.

Jesu sọ itan ọkunrin ọlọrọ kan fun wọn. Awọn ohun ọgbin rè̩ mu èso pupọ wa to bẹẹ ti aka rè̩ ko gba a. O fi owo ati ohun ini pupọ pamọ nitori ọjọ ogbó rè̩. Ni ọjọ kan o pinnu lati wó abà ti o ti ni ki o le kọ eyi ti o tobi ki o ba le maa jẹ, ki o maa mu, ki o si maa gbadun. Ko fẹ mọ ohun ti Ọlọrun le wi si eyi ni.

Lojiji ohùn kan kọ si i. Ohùn Ọlọrun ni. O wi fun un pe, yoo kú, yoo si fi gbogbo ohun ti o ni silẹ. Ọlọrun pe e ni aṣiwere, nitori o to iṣura rè̩ jọ si ayé yii, ko si rò nipa Ile daradara ti o wà ni Ọrun. Dajudaju o n ro ti ara rè̩ nikan, boya ko tilẹ naani awọn talaka ati awọn alaini. Ni alẹ ọjọ kan naa ni ọkunrin ọlọrọ naa kú. Ko mu ohun kan wá si ayé, bẹẹ ni ko mu ohun kan lọ.

Awọn ohun iṣura ti a ni lati to jọ si Ọrun ni ifẹ wa si Ọlọrun, Ọrọ Mimọ Rè̩, iṣẹ Rè̩ ati ifẹ wa lati wà lọdọ Rè̩ nigba gbogbo. A n to iṣura jọ si Ọrun nigba ti a ba mu ẹlomiran wá sọdọ Jesu –tabi ti a mu wọn wá si Ile -Ẹkọ Ọjọ Isinmi lati kọ bi a ṣe le ri idariji è̩ṣẹ gbà.

A si tun le to iṣura jọ si Ọrun nipa bibẹ awọn alaisan wò tabi ki a fun wọn ni ounjẹ tabi owó bi wọn ba ṣe alaini. Bi a ba ṣe eyi, a n ṣe e fun Jesu. Bi a ba mu awọn eniyan wá mọ Jesu a oo maa tàn bi irawọ lae ati laelae.

Bi a ba gbẹkẹle Jesu ti a si tọrọ idariji lọdọ Rè̩, Oun yoo tọju wa laye, ati ju gbogbo rè̩ lọ, Oun yoo fun wa ni ohun daradara ti O ti pese silẹ fun wa ni Ọrun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni ọkunrin ọlọrọ ni pinnu lati ṣe? Luku 12:18

  2. 2 Ki ni Ọlọrun sọ fun un? Luku 12:20

  3. 3 Njẹ Jesu fẹ ki a maa ṣe iyọnu nipa ounjẹ ati aṣọ? Luku 12:22

  4. 4 Ki ni Jesu fẹ ki a ni ṣiwaju ohun gbogbo? Luku 12:31

  5. 5 Ta ni ẹni ti o le fun wa ni gbogbo ohun ti a n fé̩?