Deuteronomi 27:11-14; 28:1-68

Lesson 45 - Elementary

Memory Verse
“Ẹ mā gbọ ti awọn ti nṣe olori nyin” (Heberu 13:17).
Notes

Mose sọ fun awọn Ọmọ Israeli pe bi wọn ba de odi keji Jordani, ki wọn pejọ lati sọ nipa awọn ohun ti Ọlọrun fẹ. Awọn kan yoo duro ni ori oke kan, ki awọn miiran si duro ni ori oke miiran, ki wọn si sọ fun awọn eniyan pe Ọlọrun yoo bukun fun wọn bi wọn ba ṣe ohun ti Ọlọrun palaṣẹ. Gbogbo eniyan yoo dahun pe “AMIN”. Itumọ eyi ni pé, bẹẹ ni ki ó rí.

Awọn ti ó wà lori oke keji yoo si sọ fun awọn eniyan pé Ọlọrun yoo jẹ wọn niyà bi wọn kò ba ṣe ohun ti O palaṣẹ. Gbogbo eniyan yoo si wi pe, “AMIN.” Lẹyin ikú Mose, Joṣua ṣe ohun ti Mose wí, Ọlọrun si bukun un.

Ọlọrun fẹ ki awọn eniyan wọnyii mọ ohun ti Oun fẹ ki awọn obi fi kọ awọn ọmọ wọn. Ọlọrun paṣẹ ki awọn obi kọ awọn ọmọ wọn ni ofin ati ilana Ọlọrun. Lọjọ oni, Ọlọrun A maa bukun awọn eniyan ati awọn ọmọde ti o ba gbọran si aṣẹ Rè̩, Oun a si maa jẹ awọn alaigbọran ni ìyà.

A ka itan Ọba Saulu ti Ọlọrun paṣẹ fun lati pa ilu kan run. O ṣe bẹẹ, ṣugbọn ko pa ọba buburu ti o wa nibẹ ati awọn agutan ti o dara. Nigba ti Samuẹli beere bi o ti ṣe ohun ti Ọlọrun palaṣẹ, o dahun pe, “Bẹẹ ni”.

Samuẹli sọ fun un pe oun gbọ igbe agutan. Ọba Saulu ṣe awawi pe oun fẹ fi wọn rubọ si Ọlọrun ni. S̩ugbọn o mọ pe otitọ kọ ni eyi. Ohun ti o dara ju lọ ni lati gbọran si Ọlọrun. Ọlọrun kọ ọ ni ọba, ko si gbọ adura rè̩ mọ.

Iyá kan wà ti o n kọ awọn ọmọ rè̩ ni Ọrọ Ọlọrun nibi gbogbo ti wọn ba lọ. Ọmọ rè̩ ọkunrin a maa wa beere lọwọ rẹ lati jẹ ki oun lọ si ibi kan tabi ṣe ohun kan, ṣugbọn oun a wi pe, “jé̩ ki a lọ wo ohun ti Ọrọ Ọlọrun wí”. Wọn a si lọ wo inu Bibeli fun idahun. Ohunkohun ti Bibeli ba wi ni wọn n tẹle.

Ọlọrun gba ọkàn ọmọdekunrin yii là, O si bukun fun un lọpọlọpọ nitori o gbọran si ohun ti iya rè̩ kọ ọ lati inu Bibeli wá. Nigba ti o dagba, Ọlọrun lo o lọpọlọpọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Darukọ diẹ ninu awọn ibukun ti Ọlọrun yoo fi fun awọn eniyan bi wọn ba gbọran si I? Deuteronomi 28:3-5

  2. 2 Darukọ diẹ ninu awọn ijiya ti Ọlọrun yoo mu wa si ori awọn ti o ba ṣe aigbọran si I? Deuteronomi 28:16, 17

  3. 3 Ki ni Bibeli sọ nipa awọn eniyan ti o ba gbọran si Ọlọrun lẹnu? Deuteronomi 28:1, 2

  4. 4 Njẹ Jesu gbọran si awọn obi Rè̩?

  5. 5 Ọna wo ni Ọlọrun fi n bukun awọn eniyan ni ọjọ oni?