Lesson 46 - Elementary
Memory Verse
“Emi wà pẹlu nyin nigbagbogbo” (Matteu 28:20).Notes
Lẹyin irin ajo ati wahala ọdun pupọ ni aginju, awọn Ọmọ Israeli dé bebe odo Jordani lati rekọja lọ si ilẹ ti Ọlọrun ṣeleri fun wọn. Awọn eniyan wọnyii ti mu inu Mose bajẹ nigba pupọ nipa aigbọran ati kikùn wọn, nipa ounjẹ, omi, ati iṣoro ti wọn ba pade ni irin ajo wọn. S̩ugbọn awọn eniyan naa fẹran Mose, oun naa si fẹran wọn.
Mose, ọmọdekunrin ti a gbé jade ninu agbọn lori omi ti dagba nisisiyii; o si di ẹni ọgọfa (120) ọdun. Bi o tilẹ jẹ pe eniyan rere ni, ti o si n gbadura, ṣugbọn nigba ti o ṣe aṣiṣe kan Ọlọrun ni lati ba a wí.
Ọlọrun sọ fun Mose pe Oun yoo mu un lọ si ori oke giga kan lati fi ilẹ daradara ni ti wọn n lọ hàn án, ṣugbọn ki i ṣe Mose ni yoo mú awọn Ọmọ Israeli de ilẹ naa. Lẹyin naa ni Mose kú. Iwe Mimọ sọ fun wa pe Ọlọrun ni O sin oku rè̩. Ko si ẹni ti o mọ iboji rè̩.
Mose jé̩ ẹni ọgọfa (120) ọdun nigba ti o kú. Ọlọrun sọ fun ni pe ko si wolii miiran ti o dabi Mose ti o ri Ọlọrun ni ojukoju. Ọlọrun fẹran Mose nitori Mose a maa gbọran si Ọlọrun, afi igba kan ṣoṣo ti o ṣe aṣiṣe yii.
Ọlọrun sọ fun Joṣua lati ṣe giri ki o si mu àyà le, ati pe Oun yoo wà pẹlu rè̩ nibi gbogbo ti o ba n lọ. Nigba naa ni Ọlọrun sọ fun Joṣua lati kó awọn eniyan naa rekọja odo Jordani si ilẹ rere ti Ọlọrun ti pese fun wọn.
Nigba ti Joṣua sọ Ọrọ Ọlọrun fun awọn eniyan, wọn ṣeleri lati ṣe ohun gbogbo ti Joṣua ba sọ fun wọn, wọn si gbadura ki Ọlọrun bukun Joṣua bi O ti bukun Mose. S̩ugbọn nigba miiran, wọn a maa gbagbe ileri wọn.
Questions
AWỌN IBEERE1 Njẹ Mose de ilẹ ileri? Deuteronomi 34:4
2 Ta ni sin oku Mose? Deuteronomi 34:6
3 Ta ni dipo Mose gẹgẹ bi alakoso awọn Ọmọ Israeli? Joṣua 1:1, 2
4 Ki ni ileri ti Ọlọrun ṣe fun Joṣua? Joṣua 1:5
5 Njẹ awọn eniyan gbọran si Josua? Joṣua 1:16, 17