Orin Dafidi 107:1-43

Lesson 47 - Elementary

Memory Verse
“Gbogbo è̩bun rere ati gbogbo è̩bun pipé lati oke li o ti wá” (Jakọbu 1:17).
Notes

Ọlọrun n fẹ ki a maa dupẹ lọwọ Oun fun gbogbo oore Rè̩. Bi a ba ni ọkàn ọpé̩, a o ni ifẹ lọkan wa. Ọlọrun fẹ ki a fẹran Oun. O fẹ wa to bẹẹ ti O fi Jesu fun wa lati kú ati lati ko è̩ṣẹ wa lọ. O yẹ ki ọkàn wa kun fun ọpé̩ fun iya nlà ti O jẹ fun wa. O jiya ki a má ba ṣegbe.

A ko gbọdọ kuna lati dupẹ pẹlu gbogbo ọkàn wa fun oore ati ifẹ Ọlọrun si wa. Nigba pupọ ni a n dupẹ lọwọ awọn obi ati awọn ọrẹ wa nigba ti wọn ba ṣe wa loore, ṣugbọn boya a ko mọ pe lati ọdọ Ọlọrun ni gbogbo è̩bun rere ti wá. A ko le ni wọn lai si Rè̩. O fun wa ni ojo ati oorun ti o n mu irugbin ti o n fun wa ni ounjẹ dagba. O fun wa ni afẹfẹ rere. O fun wa ni ilera, O si n wò wa san bi a ba ṣaisan. O fun wa ni awọn obi rere ati ọrẹ rere lati mu inu wa dùn.

Ju gbogbo rè̩ lọ, O fun wa ni Jesu Ẹni ti O kó è̩ṣẹ wa lọ ti O si fi ọna si Ọrun rere hàn wa. Ibi ti o dara ni Ọrun i ṣe. Kò si aisan, ibanujẹ tabi ikú nibẹ. Jesu ti lọ pese ibẹ silẹ fun wa, yoo si pada wa mu awọn ti o fẹ Ẹ lọ sibẹ. Jesu a maa tọju wa nihin bi a ba fẹran Rè̩ ti a si gbọran si I. A ni lati kun fun ọpẹ si I.

A dupẹ pe Ọlọrun fẹran wa. Ko fi iyatọ si dudu tabi funfun. Ohun ti O n fẹ ni pe ki gbogbo wọn tọrọ idariji fun è̩ṣẹ wọn ki wọn le di ọmọ Rè̩.

Nigba gbogbo ni a n ri aworan Jesu pẹlu awọn ọmọde. O fẹran gbogbo wọn bakan naa. Jesu fẹ fi è̩ṣẹ wọn jì wọn, ki wọn ba le ba A gbé ni Ile daradara ni Ọrun. Ọlọrun ṣe ohun gbogbo daradara. A ko gbọdọ kuna lati maa dupẹ ki a si fẹ Ẹ, ki a si ṣe ohun gbogbo ti O ba palaṣẹ fun wa.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Njẹ Jesu maa n ran awọn ti o wà ninu iṣoro lọwọ? Orin Dafidi 107:13

  2. 2 Njẹ Jesu n fẹ ki a maa yin Oun ninu Ile-isin? Orin Dafidi 107:32

  3. 3 Njẹ Ọlọrun ranti awọn otoṣi? Orin Dafidi 107:41

  4. 4 Ibukun ojoojumọ meloo ni o le sọ ti a n ri gbà lọdọ Ọlọrun?

  5. 5 Njẹ Jesu n fẹ ki a maa dupẹ ninu ohun gbogbo?