Joṣua 2:1-24

Lesson 48 - Elementary

Memory Verse
“Ifẹ ti o pé nlé ibẹru jade” (1 Johannu 4:18).
Notes

Ọlọrun ti ṣeleri fun Joṣua pe Oun yoo wà pẹlu rè̩ bi Oun ti wà pẹlu Mose. Joṣua mọ pe ko rọrun lati kó awọn eniyan lọ si ilẹ rere naa, ṣugbọn Ọlọrun sọ fun un lati ṣe giri ki o si mu aya le, ki wọn gbẹkẹle Oun, Oun yoo si ràn wọn lọwọ.

Joṣua paṣẹ fun wọn lati tọju ounjẹ wọn ki wọn si mura lati rekọja odo Jordani. Wọn ko ni ọkọ lati fi sọda odo ti o jìn ti iṣan rè̩ si le. S̩ugbọn Ọlọrun mọ ohun ti Oun yoo ṣe lati ràn wọn lọwọ.

Lati odi keji odo, awọn eniyan ri odi giga ti o yi ilu ti wọn n lọ ká. Joṣua sọ fun awọn obinrin ati awọn ọmọde lati duro titi yoo fi rọrun fun wọn lati rekọja. Ọlọrun a maa tọju awọn ti o gbẹkẹle E.

Nigba naa ni Joṣua rán ami meji lati lọ wo bi ilu naa ti ri ati bi wọn ṣe le gba a. S̩ugbọn Ọba ilu naa ti gbọ iroyin awọn eniyan wọnyii nigba ti wọn wà ni aginju, ẹru si ba a. Nigba ti o gbọ pe awọn ajeji kan wọ ilu oun, o fẹ mu wọn boya lati pa wọn.

Awọn ami naa de ile obinrin kan ti o ràn wọn lọwọ. O fi wọn pamọ soke àjà ile rè̩. Nigba ti awọn iranṣẹ ọba de lati wa mu wọn, wọn kò ri wọn. O sọ fun awọn ami naa pe oun gbagbọ pe Ọlọrun ti fi ilẹ naa fun wọn. O ti gbọ nipa gbogbo iranlọwọ ti Ọlọrun ti ṣe fun wọn ti O mu Okun pupa gbẹ ki wọn kọja ni iyangbẹ ilẹ. Lai si aniani o gbagbọ ninu Ọlọrun otitọ.

Lẹyin naa o bẹbẹ pe ki wọn ṣe iranwọ fun baba, iya, awọn arabinrin ati awọn arakunrin oun, awọn naa si ṣeleri lati ran awọn ẹbi rè̩ lọwọ. S̩ugbọn wọn sọ ohun ti o ni lati ṣe fun un.

Lẹyin naa o sọ wọn kalẹ lẹyin ogiri, o si ta owu pupa soju ferese rè̩ gẹgẹ bi a ti wi fun un. Nigba ti awọn ọmọ-ogun dé, wọn ko pa awọn ara ile rè̩. Ohun ti o dara ni lati maa ṣoore ati lati gbọran.

Laisi aniani, Ọlọrun ni O sọ fun awọn ami naa lati sọ bẹẹ fun un. Nigba ti o ṣe ohun ti wọn sọ fun un, o ṣe ohun ti Ọlọrun fẹ. Awọn eniyan yoo wà lai lewu bi wọn ba gbẹkẹle Ọlọrun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Njẹ awọn ara Jẹriko gbọ nigba awọn Ọmọ Israeli? Joṣua 2:11

  2. 2 Njẹ ẹru ba awọn ara Jeriko? Joṣua 2:11

  3. 3 Bawo ni Rahabu ṣe gba awọn ami meji naa là? Joṣua 2:15

  4. 4 Nibo ni gbogbo awọn ara ile Rahabu ni lati wà ki a má ba pa wọn run? Joṣua 2:18

  5. 5 Amì wo ni wọn fi soju ferese? Joṣua 2:21.