Lesson 49 - Elementary
Memory Verse
“Fun Ọlọrun ohun gbogbo ni ṣiṣe” (Matteu 19:26).Notes
Awọn amí meji wọnyii ko pada pẹlu ibẹru ati iroyin buburu gẹgẹ bi awọn kan ti ṣe tẹlẹ ri. S̩ugbọn awọn amí rere wọnyii sọ pe bi o tilẹ jẹ pe awọn eniyan naa tobi ti ogiri giga si yí ilu wọn ká, sibẹ wọn gbagbọ pe, nipa iranlọwọ Ọlọrun, awọn yoo gba ilu naa.
Lẹyin ti wọn ti fi ọjọ mẹta palẹmọ lati rekọja odo yii, Joṣua sọ fun awọn eniyan lati gbadura ki wọn si wà ni mimọ ki Ọlọrun ba le ràn wọn lọwọ. Lẹyin naa o sọ fun wọn pe bi awọn alufaa ba ti n lọ ki awọn eniyan naa tẹle wọn. Nigba ti wọn ba de bebe odo, awọn alufaa ni ki o tete kọ tẹ ẹsè̩ bọ inu omi.
Wọn ni lati ni igbagbọ ninu Ọlọrun ki wọn to le ṣe eyi. Wọn ṣe bi Joṣua ti wi. Ọlọrun mu ki omi duro gbọningbọnin bi ogiri nla ki awọn eniyan le kọja lori ilẹ gbigbẹ.
Joṣua paṣẹ ki wọn ṣa okuta mejila lati inu odò nibi ti awọn alufaa duro si titi awọn eniyan fi kọja. Wọn gbé okuta mejila wọnyii lọ si ibudo wọn, wọn si tò wọn jọ sibẹ gẹgẹ bi ohun iranti fun ohun ti Ọlọrun ṣe fun wọn. Bi awọn ọmọ wọn ba beere eredi rè̩ ti wọn fi to okuta wọnyii jọ, wọn yoo sọ ohun ti Ọlọrun ṣe fun wọn ni mimu wọn la odò Jordani kọja ni iyangbẹ ilẹ. Ọlọrun fẹ ki awọn obi kọ awọn ọmọ wọn nipa Oun. Ọlọrun fẹ ki gbogbo eniyan ranti oore Oun si wọn, ki wọn si maa dupẹ. Ọlọrun fẹ ki a mọ pe Oun ṣetan lati ràn wá lọwọ bi o tilẹ dabi ẹni pe ohun ti Ọlọrun fẹ ki a ṣe ṣoro loju wa. Ko si ohun ti o ṣoro fun Ọlọrun lati ṣe.
Bi a ba ranti ohun ti Ọlọrun ti ṣe ti a si dupẹ lọwọ Rẹ a oo ni igbagbọ ninu Rè̩ a oo si gbẹkẹ le E, Oun yoo si ràn wá lọwọ nigba gbogbo.
Ifẹ ni Ọlọrun; ifẹ Rè̩ ni lati ran awọn ti o ba gbọran ti wọn si gbẹkẹ le E lọwọ. O ti ṣeleri yii ninu Ọrọ Mimọ Rè̩.
Questions
AWỌN IBEERE1 Ta ni ṣiwaju nigba ti awọn eniyan la Jordani kọja? Joṣua 3:14
2 Ki ni ṣẹlẹ niba ti ẹsè̩ awọn alufaa kan omi? Joṣua 3:16
3 Njẹ bebe odo naa nibi ti wọn gbà kọja gbẹ? Joṣua 3:17
4 Ki ni awọn ọkunrin mejila naa mu jade laaarin odo naa? Joṣua 4:8
5 Ki ni ṣẹlẹ si odò Jordani nigba ti awọn eniyan kọja? Joṣua 4:18