Joṣua 6:1-27

Lesson 50 - Elementary

Memory Verse
“Nipa igbagbọ li awọn odi Jẹriko wó lulẹ” (Heberu 11:30).
Notes

Awọn ara Jẹriko ti Joṣua fẹ lọ bá jà ni lati ti gbọ pe Ọlọrun fun awọn eniyan wọnyii ni ounjẹ ni aginju, O fun wọn ni omi mu nibi ti ko si omi. Ko jẹ ki ẹranko buburu pa wọn jẹ. O si sọ omi di iyangbẹ ilẹ fun wọn lati kọja.

Gbogbo iroyin wọnyii mu ki ẹru Joṣua ati awọn eniyan rè̩ bà wọn. Boya ẹru Ọlọrun ti O n ran Joṣua lọwọ ba wọn pẹlu. Oriṣa ti wọn n sin ni ilu wọn ko le ṣe iru iranlọwọ bẹẹ fun wọn.

Ogiri giga ni o yí ilu naa ká, a si ti awọn ilẹkun ẹnu ọna rè̩. Wọn ko jẹ ki ẹnikẹni wọle, bẹẹ ni ẹnikẹni ko gbọdọ jade.

Wọn fẹ ri daju pe awọn ọta ko wọ ilu. Wọn gbẹkẹle ogiri wọn, ṣugbọn Joṣua ati awọn eniyan rè̩ gbẹkẹle Ọlọrun ti O ṣeleri lati fi ilu naa le Joṣua lọwọ. Ogiri giga ko le sé Ọlọrun tabi awọn eniyan Rè̩ mọ nigba ti O fẹ ki wọn wọ ilu naa.

Awọn ọmọ ogun yí ogiri naa ká lẹẹkan lojumọ fun ọjọ mẹfa. Awọn alufaa meje n fun ipe lọ niwaju Apoti-ẹri. S̩ugbọn ni ọjọ keje, wọn yí ilu naa ká ni igba meje; nigba ti Joṣua paṣẹ fun wọn lati hó yè è, wọn ṣe bẹẹ. Awọn ogiri naa wó lulè̩ bẹẹrẹbẹ, awọn ọmọ-ogun si wọ ilu naa, wọn si gbà á.

Wọn ranti ileri ti wọn ṣe fun obinrin oninu rere nì ti o pa awọn amí mọ, wọn ko pa ile rè̩ run. O ta owu pupa soju ferese rè̩ gẹgẹ bi awọn amí ti sọ fun un pe ki o ṣe, oun ati awọn ara ile rè̩ si wà ni ailewu.

Awa naa yoo wa ni ailewu bi a ba ṣe ohun ti Ọlọrun palaṣẹ. Owu pupa ni mu wa ranti Ẹjẹ Jesu. Nigba ti a ba fi Ẹjẹ Jesu wẹ ọkàn wa mọ ti a si wà ni mimọ, awa pẹlu wà ni ailewu labẹ itọju Ọlọrun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni awọn eniyan naa ṣe nigba ti awọn alufaa fun ipè? Joṣua 6:20

  2. 2 Ki ni ṣẹlẹ si awọn ogiri? Joṣua 6:20

  3. 3 Ta ni a dá sí nigba ti a pa gbogbo ara ilu run? Joṣua 6:25

  4. 4 Ki ni ṣe ti a dá wọn sí? Joṣua 6: 25

  5. 5 Igba meloo ni awọn eniyan yí ilu naa ká ni ọjọ keje? Joṣua 6:15