Lesson 51 - Elementary
Memory Verse
“Jesu ni iwọ o pè orukọ rè̩” (Matteu 1:21).Notes
Awọn oluṣọ-agutan kan wà ni papa nibi ti wọn n ṣọ agbo ẹran wọn. Lojiji imọlẹ kan tàn si wọn ti o mu ki ẹru ba wọn. S̩ugbọn angẹli kan sọ fun wọn pe ki wọn má ṣe bẹru nitori oun mu iroyin ayọ nla wa fun wọn ti yoo mu inu gbogbo eniyan dùn – a ti bí Olugbala kan.
Lẹyin naa ni awọn angẹli pupọ wá kọrin si Ọlọrun, wọn si sọ nipa ifẹ Rè̩. Orin wọn dùn pupọ. Ẹni ti o ba fẹran Ọlọrun yoo gbọ orin wọn ni Ọrun nikẹyin, boya yoo bá wọn kọrin pẹlu.
Nigba ti awọn angẹli lọ tán, awọn oluṣọ-agutan wi pe “Ẹ jẹ ki a lọ tàra si Bẹtlẹhẹmu, ki a le ri ohun ti o ṣẹ, ti Oluwa fihàn fun wa”. Awọn oluṣọ-agutan naa yara lọ si ilu lati lọ wo Ọmọ ti angẹli sọ fun nipa Rè̩.
Wọn ranti pe a ti sọ fun wọn pe Ọmọ naa wà ni ibujẹ ẹran nibi ti awọn ẹranko n jẹun - nibẹ ni wọn gbé ri I. Inu wọn dùn nigba ti wọn ri I, wọn si royin ohun ti wọn rí ati ohun ti angẹli ti sọ fun wọn fun ọpọlọpọ eniyan. Wọn pada pẹlu ayọ ati iyin si Ọlọrun.
Ọlọrun ṣeun pupọ lati rán angẹli lati sọ fun awọn oluṣọ-agutan nipa Jesu. Awa pẹlu ni lati kún fun ọpé̩ si Ọlọrun pe a gbọ nipa Jesu ati ifẹ Rè̩ si wa. O yẹ ki awa naa sọ fun awọn ẹlomiran gẹgẹ bi awọn oluṣọ-agutan naa ti ṣe.
Nigba ti angẹli ni sọ pe a o bi Jesu, o sọ pe, “Jesu” ni a o pe orukọ Rè̩, nitori Oun ni yoo gba awọn eniyan Rè̩ là kuro ninu è̩ṣẹ wọn. Jesu ni orukọ ti o dùn ju lọ ni ayé. Iwe Mimọ sọ fun wa pe bi a ba beere ohunkohun ni orukọ Jesu, Oun yoo ṣe e. A le beere fun ohun rere gbogbo ni orukọ Rè̩ nitori O kú fun wa.
Ọkàn wa ni lati kún fun ọpé̩ si Ọlọrun nitori Ọmọ iyanu ni ti a bí ni Bẹtlẹhẹmu, o si yẹ ki a gbiyanju lati jọ Jesu.
Questions
AWỌN IBEERE1 Ta ni sọ fun Josẹfu pe ki o sọ ọmọ rè̩ ni JESU? Matteu 1:20, 21
2 Ki ni ṣe ti a fi pe E ni “JESU”? Matteu 1:21
3 Bawo ni awọn oluṣọ-agutan ṣe mọ pe a bi JESU? Luku 2:8-11
4 Ki ni wọn ṣe lẹyin ti wọn rí JESU? Luku 2:17
5 Ki ni yẹ ki awọn ti o mọ JESU ṣe fun awọn ẹlomiran?