I Samuẹli 16:1-23

Lesson 210 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “OLUWA ki iwò bi enia ti nwò; enia a ma wò oju, OLUWA a ma wò ọkàn” (I Samuẹli 16:7).
Cross References

I. Iṣẹ ti a Ran Samuẹli lati Fi Ororo Yàn Ọba Miiran

1. “Emi ti ri ọba kan fun ara mi”, I Samuẹli 16:1;13:14; Orin Dafidi 78:70-72

2. Lati idile Jesse ti è̩ya Juda ni a ti sọ asọtẹlẹ pe ọba kan yoo ti wá, Gẹnẹsisi 49:10; Isaiah 11:1; Iṣe Awọn Apọsteli 13:21, 22

3. Samuẹli bè̩ru Saulu, I Samuẹli 16:2, 3

II. Ẹbọ ti A Rú ni Betlẹhẹmu

1. Awọn agbà ilu wariri, nitori Samuẹli tọ wọn wá, I Samuẹli 16:4, 5; Matteu 2:3

2. Gbogbo ọmọ Jesse ti o wà nibẹ ni a kọ, I Samuẹli 16:6 - 10

3. Eniyan n wò oju -- Ọlọrun n wò ọkàn, I Samuẹli 16:7

4. A pe Dafidi wa lati ibi ti o gbe n ṣọ agbo-agutan, I Samuẹli 16:11, 12; Johannu 7:3-5

5. Ẹmi Ọlọrun bà le Dafidi, I Samuẹli 16:13; Isaiah 61:1

III. Ẹmi Ọlọrun fi Saulu Silẹ

1. Ẹmi buburu rọpo Ẹmi Oluwa ninu rè̩, I Samuẹli 16:14

2. Saulu ṣe awari Dafidi, ẹni ti o mọ bi a ti i lu harpu, ISamuẹli 16:15-19

3. Dafidi ri oju rere lọdọ Saulu, I Samuẹli 16:20-23

Notes
ÀLÀYÉ

Aṣẹ ti a Pa fun Samuẹli

“OLUWA si wi fun Samuẹli pe, Yio ti pẹ to ti iwọ o fi ma kānu Saulu, nigbati o jẹ pe, mo ti kọ ọ lati ma jọba lori Israẹli?”

Samuẹli kaanu fun Saulu – iwa ti Saulu hù ba a ninu jẹ gidigidi. O si to akoko ti Ọlọrun sọ pe, Samuẹli ti kaanu pé̩ to. Nigba ti ẹni kan ba kú tabi o pada kuro ninu igbagbọ -- eyi ti o buru jù ikú ti ara lọ -- iwa eniyan ni pe, ki o dùn awọn ti o sun mọ ọn, ki wọn si kaanu fun adanu yii. S̩ugbọn nigba ti o ba pẹ diẹ, a ni lati pa ikaanu tì, ki a si maa ba iṣẹ Ọlọrun lọ. “Fi ororo kún iwo rẹ, ki o lọ”, ni aṣẹ ti Ọlọrun fi fun Samuẹli.

Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli beere fun ọba, Ọlọrun ti sọ fun Samuẹli pe, “Gbọ ohun wọn ki o si fi ọba jẹ fun wọn” (I Samuẹli 8:22), ṣugbọn nigba ti o ran Samuẹli si Jesse, O wi pe, “Emi ti ri ọba kan fun ara mi ninu awọn ọmọ rè̩.” Oju Ọlọrun ti ri ọkàn ẹgbẹẹgbẹrun ni Israẹli, O si ti ri ẹni kan bi ti inu Rè̩.

Samuẹli mọ pe Saulu ti kọ Oluwa silẹ, nitori ti o wi pe, “Bi Saulu ba gbọ yio si pa mi” Lẹyin ọdun diẹ, ẹ wo iru iyipada ti o ti de ba ọmọ Kiṣi, ẹni ti o ti bá awọn woli rin nigba kan ri! Olugbala wa kilọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe, “Ẹ mā ṣọna, ki ẹ si mā gbadura, ki ẹnyin ki o má ba bọ sinu idẹwò” (Matteu 26:41). Ibẹrẹ rere ki i ṣe è̩ri opin rere. Jesu sọ fun awọn Ju ti o gba A gbọ pe, “Bi ẹnyin ba duro ninu ọrọ mi, nigbana li ẹnyin jẹ ọmọ-ẹhin mi nitõtọ” (Johannu 8:31).

Ẹrù ati Iwariri

Nigba ti Samuẹli de Bẹtlẹhẹmu, ẹrù ba awọn agbagbà ilu naa, eyi ti o fi ipa ati agbara eniyan Ọlọrun yii hàn. Nigba pupọ, iduro eniyan Ọlọrun yoo mu ki ara awọn ẹlẹṣè̩ maa gbọn pẹlu idalẹbi ọkàn. Ahabu ni lati wariri ni ọjọ ti Elijah pade rè̩ ninu ọgba Naboti. Feliksi wariri nigba ti Paulu ba a sọ asọye nipa ti ododo, airekọja, ati idajọ ti o n bọ wá.

Eliabu,Arẹwà Ọkunrin

Bi awọn ọmọ Jesse ti n jade wa siwaju Samuẹli, o ri Eliabu, ẹni ti o ṣe arẹwa ti o si singbọnlẹ, o si wi pe “Nitõtọ ẹni-àmi-ororo OLUWA mbẹ niwaju rè̩.” Bawo ni o ti rọrun to fun ọmọ-eniyan lati ṣe aṣiṣe! Eniyan le wò ẹni kan ki o si pe e ni ẹni pipé; ṣugbọn Ọlọrun, ti O ri ọkàn le sọ pe, o kún fun “ọgbé̩, ipalara, ati õju ti nrà” (Isaiah 1:6). Nigba miiran, ireti a maa ga pe ẹni kan ti o ni ẹbun nla kan yoo wulo ninu iṣẹ Ọlọrun, ṣugbọn Ọlọrun a wi pe “Emi kọ ọ: nitoriti OLUWA ki iwò bi enia ti nwò; enia a ma wò oju, OLUWA a ma wò ọkàn.” A ti kọ ọpọlọpọ eniyan ti wọn ni ohun amuyẹ nipa ti ara lati di oṣiṣẹ ninu ọgbà ajara Ọlọrun nitori pe ọkàn wọn wà ninu ohun ti ayé. Ipe Ọlọrun dún jakejado si “ẹnikẹni ti o ba fẹ”, ṣugbọn eniyan diẹ ni o n fẹ jẹ ipe yii.

Eliabu jẹ ọkan ninu awọn ti Saulu yàn sinu ẹgbẹ-ogun rè̩. Lai si aniani, ara rè̩ le koko, o ni laakaye ti o ga, ṣugbọn ipe Ọlọrun jẹ si iṣẹ ti o ga jù ti ẹgbẹ ogun Saulu lọ. Ọlọrun ni ero ti o ga pupọ jù ti ẹda lọ. “Nitori èro mi ki iṣe èro nyin, bḝni ọna nyin ki iṣe ọna mi, li OLUWA wi. Nitori bi ọrun ti ga ju aiye lọ, bḝni ọna mi ga ju ọna nyin lọ, ati èro mi ju èro nyin lọ” (Isaiah 55:8, 9). Bawo ni ọpẹ wa ti ni lati pọ to, bawo ni a si ti ni lati rin pẹlu iṣọra, ki a ba le kà wa yẹ bi ẹni ti a o kà kun ninu eto giga wọnni! Bawo ni anfaani wa ti pọ to! Lati jẹ ẹni ti a pè wa ṣe ọba ati alufa fun Ọlọrun! Ẹ jẹ ki a kiyesi ọkàn wa gidigidi, ki a ma ba kọ wa bi a ti kọ Eliabu.

Abinadabu, Atẹle

Ẹ wo bi anfaani Abinadabu, ọmọ Jesse keji ti pọ to! A fẹ fi ororo yàn ẹni kan ni ọba laarin ẹbi rè̩. A ti kọ ẹgbọn rè̩; nisisiyi, ayè ṣi silẹ fun un, anfaani wura ni eyi jẹ niwaju rè̩ -- Ọlọrun si n boju wo ọkan rè̩. Ohun naa fọ pe, “OLUWA kò si yan eleyi.” Kò mura tẹlẹ fun anfaani yii.

Ro bi yoo ti ri nigba ti awọn eniyan ba duro niwaju Onidajọ gbogbo ayé, nigba ti gbogbo orilẹ-ède ba pejọ siwaju Rè̩! Yoo sọ fun awọn kan pe, “Ẹ wá, ẹnyin alabukun-fun Baba mi”; fun awọn miiran ni Oun yoo si wi pe, “Ẹ lọ kuro lọdọ mi, ẹnyin ẹni ègun.” Akoko lati ronupiwada yoo ti kọja nigba naa. Anfaani miiran yoo ha tun wà bi? Ndao, ko ni si mọ titi ayé ainipẹkun. Isisiyi ni akoko lati mura silẹ fun Ọrun. Ẹ wo ọgbẹni ti Jesu sọ fun pe, “Ohun kan li o kù ọ kù.” Njẹ yoo ha le dide duro ni ọjọ naa, lati sọ pẹlu imi-è̩dun pe, “N ba mọ ki n ti ṣe e?” Iwọ yoo ha jẹ ki ohun kan dena rẹ lati gbọ wi pe, “Ẹ wa, ẹnyin alabukun-fun Baba mi”? Abinadabu kọja niwaju Samuẹli, ṣugbọn ohun ti o gbọ ni pe, “OLUWA kò si yàn eleyi.”

S̩amma

“Jesse si mu ki S̩amma ki o kọja.” A pe S̩amma sinu ẹgbẹ-ogun Saulu, ṣugbọn a kò yan an lati ṣe akoso ogun ti Oluwa. Oluwa a maa wò ọkàn, Oun a si maa wọn iwà wò. Bawo ni o ti jẹ ipe Ọlọrun si? Iwọ ha n sà gbogbo ipa rẹ lati wa ninu awọn wọnni ti a yàn?

Awọn Ọmọ Miiran

Awọn ọmọ Jesse miiran wá fun ayè̩wo, ṣugbọn ohùn kan naa ni o n fọ si wọn pe, “OLUWA kò yàn awọn wọnyi.” Gbogbo awọn ọmọ Jesse ni a o ha kọ? Ọlọrun kò ha ti sọ fun Samuẹli pe, Oun ti pese ọba silẹ laarin awọn ọmọ Jesse? Samuẹli beere lọwọ Jesse pe, “Gbogbo awọn ọmọ rẹ li o wa nihin bi?” Ndao, eyi ti o kere jù lọ, lara ẹni ti oju Ọlọrun wà, wà ni papá, o n ṣọ agbo-ẹran. Ọdọmọkunrin ni i ṣe, a ko tilẹ pe e sibi ase pẹlu awọn ẹgbọn rè̩, ẹni kan ko le ro pe ọba tọ si i. S̩ugbọn Samuẹli wi pe, “Ranṣẹ ki o si mu u wá: nitoripe awa ki yio joko titi on o fi de ihinyi.”

Fifi Ororo Yàn Dafidi

Bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun yàn Dafidi nitori awọn ẹwà ti inu ti a ko le foju ri, sibẹsibẹ irisi Dafidi dara pupo nigba ti a mu un wa siwaju Samuẹli. Oluwa si wi fun u pe, “Dide ki o si fi ororo sà a li àmi; nitoripe on na li eyi.” Samuẹli fi ororo sà a ni ami pẹlu ayẹyẹ kekere niwaju awọn arakunrin rè̩; ṣugbọn gẹgẹ bi igbesi-aye Dafidi ti ri, ni ti pe, ọṣọ inu rè̩ tayọ ti ode-ara, ifororoyàn naa tayọ titu ororo si i ni ori lasan. “Ẹmi OLUWA si bà le Dafidi lati ọjọ na lọ”

Oluwa ti o n pe ni a maa ṣe ipese oore-ọfẹ ati agbara lati jẹ ipe naa, ati lati di aayè pataki naa. Wo ọpọlọpọ ohun ti awọn eniyan ti ṣe ni aṣeyọri nigba ti Ẹmi Ọlọrun ba bà le wọn! Ẹmi Ọlọrun bà le Gideoni, o si fun ipe nigba ti awọn Ọmọ Israẹli n gbe inu ihò ati inu apata nitori awọn ara Midiani. Ẹmi naa wà pẹlu rè̩ sibẹ nigba ti oun, pẹlu ọọdunrun ọkunrin ṣẹgun awọn ọmọ-ogun Midiani ti o pọ jọjọ. Ẹmi Oluwa bà le Samsoni, o si pa ẹgbẹrun ninu awọn ara Filistini pẹlu pari-ẹrẹkẹ kẹtẹkẹtẹ kan. Ẹmi Oluwa bà le Dafidi nigba ti a fi ororo yàn an. Ẹmi kan naa ni o lo o lati bá omiran ara Gati nì jà nigba ti awọn ọmọ-ogun Israẹli daamu tan, ti aya si fo wọn. Ẹmi Oluwa ni o ran an lọwọ ni ọjọ ibi wọnni, nigba ti Saulu n lepa rè̩. Dafidi fi ara mọ Oluwa ni gbogbo ọjọ aye rè̩, Oluwa si wa pẹlu rè̩ titi de opin.

Ipo ti Saulu Wà

Nigba ti Dafidi n gba ibukun Ẹmi, ipo ti Saulu wà buru pupọ. “Ẹmi OLUWA fi Saulu silẹ, ẹmi buburu lati ọdọ OLUWA si nyọ ọ li ẹnu.” Paulu Aposteli kilọ fun wa wi pe ki a má ṣe “mu Ẹmi Mimọ Ọlọrun binu, ẹniti a fi ṣe èdidi nyin dè ọjọ idande.” Bawo ni edidi ti a nì ti logo to – a ni Ẹmi Mimọ Ọlọrun! S̩ugbọn wo bi ọkàn yoo ti di korofo to nigba ti a ba mu Ẹmi Mimọ binu ti O si ba ti Rè̩ lọ! Afo a ṣi silẹ ninu irú ọkàn bẹẹ fun awọn ẹmi meje ti o buru jù eyikeyi ti ọkàn naa ti mọ ri. Lai si aniani, igbesi-aye Saulu fi hàn pe igbẹyin oluwarè̩ yoo buru jù ti iṣaaju lọ. Eyi ko yẹ ki o ri bẹẹ bi a ba feti si ikilọ ti a kò si “mù Ẹmi Mimọ Ọlọrun binu.” Ẹ jẹ ki a ṣe bi ti Dafidi ti o duro de Oluwa, ti o si mọ pe O wa pẹlu oun bi oun tilẹ wà ni afonifoji ojiji ikú.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ero Samuẹli nipa Eliabu?
  2. Ki ni iyatọ laarin oṣuwọn ti eniyan fi n diwọn eniyan ati oṣuwọn ti Ọlọrun?
  3. Ki ni orukọ ọmọ Jesse akọbi ati ọmọ rè̩ abikẹyin?
  4. Nibo ni a gbe bi Dafidi?
  5. Ki ni iṣẹ ti Dafidi n ṣe ki a to yàn an ni ọba?
  6. Ki ni ohun ti iranṣẹ Saulu sọ nipa Dafidi?
  7. Ta ni wa nibi ti a gbe fi ororo yàn Dafidi?
  8. Ki ni a le fi Ẹmi Ọlọrun ti o bà le Dafidi we ni akoko ti wa yii?
  9. Ki ni iwọ rò pe, o mu ki ẹrù ba awọn agba Bẹtlẹhẹmu nigba ti wọn ri Samuẹli?
  10. Lati inu è̩ya wo ni Dafidi ti wá?