Lesson 211 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Nitorina ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ ki ẹnyin ki o le duro tiri si ọjọ ibi, nigbati ẹnyin bá si ti ṣe ohun gbogbo tan, ki ẹ si duro” (Efesu 6:13).Cross References
I. Akinkanju Ọgagun awọn Filistini
1. Awọn ẹgbẹ-ogun Israẹli ati ti Filistini tẹgun si ara wọn, . I Samuẹli 17:1-3
2. Goliati, omirán kan ti o ga to ẹsẹ mẹsan ati inṣi mẹsan, gbe ihamọra ti o wuwo to igba iwọn wọ, I Samuẹli 17:4-7
3. O pe ẹgbẹ-ogun Israẹli ni ijà, I Samuẹli 17:8-10; I Peteru 5:8
4. Ẹru ba Saulu ati awọn eniyan rẹ gidigidi, I Samuẹli 17: 11, 24; Luku 12:4, 5
II. Lilọ Dafidi si Oju-Ogun
1. Jesse rán Dafidi lati lọ bẹ awọn arakunrin rè̩ wò, I Samuẹli 17:12-22
2. Dafidi gbọ ọrọ ipenijà ti Goliati sọ, I Samuẹli 17:23-25
3. Ọrọ naa rú ọkàn Dafidi soke, I Samuẹli 17:26, 27;Iṣe Awọn Apọsteli 17:16
4. Eliabu fi ẹgàn ba Dafidi wi, I Samuẹli 17:28-31;II Kronika 36:16
III. Dafidi Gba Ipenija Goliati
1. Dafidi ba Saulu sọrọ, I Samuẹli 17:32-37
2. A fi ihamọra ogun Saulu paarọ awọn ohun ija oluṣọ-agutan ti kò ni laari ṣugbọn ti a ti danwo, I Samuẹli 17:38-40;Efesu 6:13; II Korinti 10:4
3. Goliati funnu, Dafidi si da a lohun, I Samuẹli 17:41-47; I Awọn Ọba 20:11; I Johannu 4:4
4. Okuta kan ṣoṣo bi omirán naa ṣubu, awọn ẹgbẹ-ogun rè̩ si sa, I Samueli 17:48-58;Heberu 11:32-34.
Notes
ÀLÀYÉLai si Ẹmi
“Ẹmi OLUWA fi Saulu silẹ” (I Samuẹli 16:14). Apa kan ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun yii ṣe alaye nipa ifoya ati ẹrù ti o n ba Saulu nigba ti omirán ara Gati pe oun ati awọn ọmọ-ogun Israẹli nijà. Sibẹsibẹ, Saulu le fi ẹgbẹ ọmọ-ogun rè̩ seto ni imurasilẹ fun ogun, ṣugbọn ko ni igboya to lati ba wọn lọ si oju ija. Ọlọrun ti ṣeleri pe Ọmọ Israẹli kan yoo le ẹgbẹrun, ṣugbọn nisisiyi, Filistini kan n gan gbogbo ẹgbẹ-ogun Israẹli. Fun ogoji ọjọ ni awọn alagbara ọkunrin ni Israẹli fi n gbọn pè̩pè̩ nitori pe Ẹmi Oluwa ti fi aṣiwaju wọn silẹ.
Nigba ti Ẹmi Ọlọrun ba fi ẹni kan silẹ, o le sọ bi i ti Samsoni pe, “Emi o jade lọ bi igba iṣaju, ki emi ki o si gbọn ara mi” (Awọn Onidajọ 16:20), ṣugbọn ko ni pẹ ti oun yoo fi mọ pe a ti de oun tọwọ tẹsẹ, a si ti fi oun silẹ sọwọ ọta lai si iranwọ. Ẹgbẹ ọmọ-ogun ti a ti to lẹgbẹẹgbé̩ wa sibẹ, awọn ti o wa niwaju wa ni ipo wọn, ṣugbọn wọn dabi ibọn ti kò ni ọta, ọkọ ogun ti ko ni epo, batiri mọto ti ko ni iná ninu. Niwọn igba ti wọn ko ni iye ninu lati dahun si ipenijà, ti wọn ko si ni igboya lati duro tiiri, wọn da ohun-ijà wọn silẹ, wọn si sa niwaju ẹyọ Filistini kan ti o n pe wọn nija.
Awọn ti Wọn Ni Ẹmi Ọlọrun Ko Pọ To
Dajudaju, Ẹmi Ọlọrun ni lati maa kaanu bi O ti n wò ọkàn awọn ọmọ-ogun ti o wa niwaju titi de awọn ti o wa lẹyin, lati wò bi Oun yoo ri ẹni kan ti Oun le fọkan tan lati fi Ẹmi Ọlọrun fun lati jade lọ ni orukọ Rè̩. S̩ugbọn ninu gbogbo ẹgbẹ ọmọ-ogun Saulu, Oun ko ri ẹni kan. A sọ fun ni pe, “oju OLUWA nlọ siwa sẹhin ni gbogbo aiye, lati fi agbara fun awọn ẹni ọlọkàn pipe si ọdọ rè̩” (II Kronika 16:9).
Ni igba ewu ti a wà yii, ti ọta n gbogun lọtun losi, Oluwa n fẹ lati tú Ẹmi Rè̩ da sori gbogbo ẹda, ki Oun ki O le ri awọn ọkunrin ati obinrin ti yoo dojujà kọ ogun ọrun apaadi. Ẹ wo irú anfaani nla ti Ọlọrun fẹ fi fun wa! Sibẹ, diẹ ni o n jẹ ipe naa! “Emi si wá ẹnikan lārin wọn, ti ibá tun odi na mọ, ti ibá duro ni ibi ti o ya na niwaju mi fun ilẹ na, ki emi má bà parun: ṣugbọn emi kò ri ẹnikan” (Esekiẹli 22:30). A ko ha ni ri ẹni kan ti yoo dahun bi?
Oluṣọ-agutan Kan
Lati inu agbo-ẹran nitosi Bẹtlẹhẹmu, ọdọmọkunrin kan fi agbo agutan rè̩ sabẹ itọju ẹlomiran lati lọ jiṣẹ kan fun baba rè̩. Pẹlu akara ati agbado yiyan ni ọwọ rè̩ lati fi i fun awọn ẹgbọn rè̩ ti o wà ninu ẹgbẹ-ogun Saulu, Dafidi mu ọna rè̩ pọn. Jesse ni o ran an niṣẹ, ṣugbọn iṣẹ yii di ti Ọlọrun, nitori oju Baba ti o wà ni Ọrun wà lara ilẹ naa. Fun ogoji ọjọ, ẹgbẹ-ogun Israẹli wà ni idakẹ rọrọ titi Ọlọrun fi ran oluṣọ-agutan ti yoo jẹ aṣiwaju awọn eniyan Rè̩. Lẹba oke wọnni ni oun ti maa n ṣe aṣarò nipa ogo Ọlọrun. O n rò bi Ọlọrun ti n ṣọ oun, bi oun naa ti n ṣọ agbo agutan – “OLUWA li oluṣọ-agutan mi.” O ti mọ aabo Ọlọrun bi o ti ko kiniun ati beari loju, ti ko si ni ipalara; o mọ pe oun n sin Ọlọrun alagbara.
Ọkàn ti a Rú Soke
Ireti rè̩ ni lati gbọ ihin iṣẹgun ati itàn akin ni ibudo; kàka bẹẹ, ẹrù ati ijayà ni o ba pade. Inu rè̩ ru gidigidi nigba ti o gbọ ọrọ è̩gàn ti ara Gati nì sọ. “Tali alaikọla Filistini yi iṣe, ti yio fi ma gan ogun Ọlọrun alāye?” Tani ẹda erupẹ ilẹ lasan i ṣe ti yoo fi maa gan Ẹlẹda rè̩?
Idahun
Ipenija yii rú idahun kan jade lati inu ọkàn rè̩, igboya rè̩ peleke si i nigba ti o ro ti Oluṣọ-agutan Israẹli ti ki i sun tabi toogbe. Kiniun, beari, omirán -- awọn wọnyii ha ja mọ ohun kan niwọn bi Ọlọrun ti jẹ Olupamọ Dafidi? Lati ọdọ awọn jagunjagun olokun mẹta titi de ọdọ balogun ati titi lọ de ọdọ olori-ogun ni ọrọ Dafidi tàn kalẹ de titi Saulu fi ranṣẹ pe e. “Ki aiya ki o máṣe fò ẹnikẹni nitori rè̩; iranṣẹ rẹ yio lọ, yio si ba Filistini yi jà,” ni ọrọ ti ipẹẹrè̩ yii sọ bi o ti n woju ọba Israẹli ti o singbọnlẹ yii, ẹni ti oun kò ga ju ejika rè̩ lọ.
Ọkàn Dafidi ko mi, bi ọba tilẹ sọ fun un pato pe, “Iwọ kò le tọ Filistini yi lọ lati ba a jà: nitori pe ọdọmọde ni iwọ, on si jẹ jagunjagun lati igba ewe rè̩ wá.” Oun ko kà ẹgàn awọn ẹgbọn rè̩ si, awọn ẹni ti o sọ fun un pe ki o pada sile ki o si lọ maa ṣe itọju awọn aguntan diẹ nì. Nigba ti eniyan ba ni Ẹmi Ọlọrun, ẹfè̩ ati ifini-ṣẹsin ko le yi i pada. A ti fi ẹsẹ rè̩ le ori Apata ti gbogbo ogun ọrun apaadi ko le mi.
Ihamọra ti a Kò Dan Wò
Itara Dafidi ko dinkù nipa idaduro ni ti pe ki a maa kaṣọ wọ ọ -- ni gbigbe ihamọra wọ ati bibọ ọ silẹ. Saulu fun un ni ihamọra rè̩ -- boya ti rè̩ ni o dara jù lọ ni gbogbo orilẹ-ède wọn -- ṣugbọn o ga ẹmi ọdọmọkunrin oluṣọ-agutan yii lara; “Emi kò le rù wọnyi lọ, nitoripe emi kò idan a wò. Dafidi si tu wọn kuro li ara rè̩.”
Iyatọ wa laarin ihamọra ti awọn ti aye yii fi n wọ eniyan ati eyi ti Ọlọrun lana silẹ fun eniyan lati ni. Awọn oniṣegun yoo ṣiṣẹ abẹ fun alaisan nigba ti adura ati igbagbọ yoo fun un ni imularada. Ẹlomiran yoo damọran gbigbe ẹwù irin wọ, nigba ti igbagbọ pẹlu okuta lati inu odò ti to. Ọlọrun ko ti ipa ọpọ ẹṣin gba ẹgbẹ-ogun kan là. Ti Rè̩ tayọ iwewe-ogun ti a ti ọwọ eniyan gbe kalẹ. O ran ọọdunrun ọkunrin pẹlu otufu, iṣa ati ipe, lati dojujà kọ ogunlọgọ eniyan. Nigba ti a ba pè ẹni kan lati waasu, awọn ti aye yoo kọ ọ ni ọpọlọpọ è̩kọ ọgbọn-ori, wọn ko si jẹ tọka rè̩ si ọna adura, igbagbọ ati igbala. A ti ṣẹgun ilẹ ọba pẹlu apata igbagbọ, ati idà Ẹmi, ṣugbọn lọjọ oni, awọn eniyan gbẹkẹ le awọn ọkọ ogun ati afọnja.
Dafidi bọ ihamọra Saulu silẹ, ṣugbọn o gbe ihamọra Ọlọrun wọ. “Ohun ija wa ki iṣe ti ara, ṣugbọn o li agbara ninu Ọlọrun lati wó ibi giga palẹ” (II Kọrinti 10:4). A ti dán igbagbọ ninu Ọlọrun wo. O mu awọn ọmọ Heberu mẹta la ina ileru ja, ina ko si jo wọn; o daabo bo Daniẹli kuro lọwọ awọn kiniun ni gbogbo oru; o gbe Paulu gunlẹ si ebute ni alaafia lẹyin ọsan kan ati oru kan ninu ibú. Ihamọra Saulu le dara loju awọn ẹni ti aye, ṣugbọn Dafidi wà ni ailewu ninu ihamọra ti Ọlọrun.
Iṣẹgun
Pẹlu adura, kànnàkànnà, ọpá darandaran, ati okuta wẹwẹ marun lati inu odo, Dafidi sare lati lọ pade Goliati. Filistini naa dide lati pade Dafidi, o si n fi i ré ni orukọ awọn oriṣa rè̩ bi o ti n bọ wa. O jẹ ohun è̩gàn fun un pe ọdọmọkunrin kekere ti ko ni ihamọra ni o n bọ wa ba oun jà pẹlu ọpá darandaran. “Emi ha nṣe aja bi, ti iwọ fi mu ọpá tọ mi wá?” Goliati niyi pẹlu aṣibori idẹ, ẹwù irin, o si wọ ibọsẹ ti a fi idẹ rọ; ẹni ti o ru ihamọra rè̩ si n lọ niwaju rè̩, o gbe apata nla kan soke. Bi Dafidi ti n sare lọ lati pade rè̩, o fi ọwọ sinu apo rè̩ lati mu okuta kan, o si fi i sinu kànnàkànnà rè̩ -- o si fi i! Pẹlu ida ninu akọ ati ọkọ nilẹ gbọnrangandan, Goliati ṣubu, o si doju bolẹ. Okuta ko tase ẹni ti a ta a si. Agberaga eniyan ṣubu doju bolẹ sinu erupẹ ilẹ. Lai ni ida lọwọ rè̩, lai si aṣibori lori rè̩, ṣugbọn pẹlu igbagbọ ninu Ọlọrun rè̩, Dafidi ṣẹgun omirán ara Gati.
Ariwo nla ta lati ibudo awọn Ọmọ Israẹli. Awọn ti o ti sọ ireti nu gbara jọ, wọn si lepa awọn Filistini. Itara ọtun sọji lọkàn awọn Ọmọ Israẹli lọjọ naa, nitori pe ọdọmọkunrin oluṣọ-agutan kan pere ni igbagbọ ninu Ọlọrun rè̩. Ẹni bi ti inu Ọlọrun lọ si oju ija ni akoko iṣoro fun Israẹli.
Ipe
Lode oni, Israẹli nipa ti Ẹmi n ṣafẹri awọn aṣiwaju --awọn akin ọkunrin ti yoo doju kọ gbogbo igbogunti eṣu. Woli kan sọ nigba kan ri pe, “Mo ri gbogbo Israẹli tukakiri lori awọn oke bi agutan ti kò ni oluṣọ” (I Awọn Ọba 22:17). Ọpọlọpọ agutan ni o wa lọjọ oni, ṣugbọn awọn oluṣọ-agutan kere niye. A o ha maa wò ọta bẹẹ lai doju kọ ọ bi o ti n pe wa nijà? Ko ha si ẹni kan ti yoo lọ ni orukọ Oluwa lati sọ ifẹ ọkàn awọn ti o n sun ninu ijọ ji? Ọlọrun má ṣe jẹ ki ina Igbagbọ kú nitori pe ko si akinkanju aṣiwaju!
Questions
AWỌN IBEERE- Bawo ni Goliati ti ga to (ẹsẹ melo ni)?
- Bawo ni ihamọra rè̩ ti wuwo to?
- Omirán melo ni a darukọ ninu Bibeli?
- Ki ni ṣẹlẹ si adehun ti Filistini mu wa ni ẹsẹ kẹsan?
- Bawo ni o ti pẹ to ti Goliati ti n pe Israẹli nijà, ki Dafidi to yọ si oju ogun?
- Bawo ni Dafidi ṣe de ọdọ awọn ọmọ-ogun?
- Iru ihà wo ni Eliabu kọ si Dafidi?
- Ki ni mu ki ọkàn Dafidi balè̩ lati ba Filistini naa ja?
- Ki ni ṣe ti Dafidi kò fi gbe ihamọra Saulu wọ?
- Ki ni ṣẹlẹ laarin awọn ọmọ-ogun Israẹli, nigba ti Dafidi pa Goliati?
- Ki ni a le fi eyi we lọjọ oni?