Lesson 212 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Eyi li ofin mi, pe ki ẹnyin ki o fẹràn ara nyin, gẹgẹ bi mo ti fẹràn nyin” (Johannu 15:12).Cross References
I Irẹpọ
1. Ọkàn Jonatani fà mọ ọkàn Dafidi, I Samuẹli 18:1; Gẹnẹsisi 44:30; I Samuẹli 19:2; II Samuẹli 1:26
2. Saulu mu Dafidi wa sile, Jonatani ati Dafidi si di ọrẹ gidigidi, I Samuẹli 18:2-4
II. Ikorira Saulu
1. Dafidi sọ fun Jonatani nipa ikorira ti Saulu ni si oun, I Samuẹli 20:1-4; Joṣua 2:14
2. Dafidi ati Jonatani ṣe eto lati mọ bi Saulu n wá ẹmi Dafidi, I Samuẹli 20:5-10
3. Wọn lọ sinu papa kan, wọn gbadura, wọn si tun è̩jé̩ wọn jé̩, I Samuẹli 20:11-17; II Samuẹli 9:1
4. Wọn pari eto wọn lati ni idaniloju irú ihà ti Saulu kọ si Dafidi, I Samuẹli 20:18-23
5. Ibinu Saulu ru soke nitori ti Dafidi ko wá si ibi ase, o si gbiyanju lati pa Jonatani, I Samuẹli 20:24-33
6. Jonatani fi ami tootọ hàn fun Dafidi, I Samuẹli 20:34-40
III. Ipinya pẹlu Ibanujẹ
1. Dafidi ati Jonatani pade, wọn si jumọ sọkun, I Samuẹli 20:41
2. Jonatani tù Dafidi ninu, o si fi tifẹtifẹ dagbere fun un, I Samuẹli 20:42
Notes
ÀLÀYÉIrẹpọ
Irẹpọ ti o wa laarin Dafidi ati Jonatani jẹ iru eyi ti ko lẹgbẹ, a ko si rò pe a le ri eyi ti o tayọ rè̩ ninu aye yii. Jonatani, ọmọ-ọba ati arole ni Israẹli ni ifẹ kan si Dafidi ti o tayọ eyikeyii ti akọsilẹ rè̩ wà nipa ẹni kan si ẹni keji rè̩. Nigba pupọ ni a n sọ nipa Jonatani pe, o fẹran Dafidi bi ẹmi oun tikara rè̩.
Ifẹ ẹda jinlẹ, paapaa ju lọ ifẹ obi si ọmọ tabi ti ọmọ si obi. S̩ugbọn nigba ti wọn ko ba tilẹ ba ara wọn tan rara, eyi mu ki ifẹ naa fara jọ ifẹ Ọlọrun.
Ai-mọ-ti-ara-ẹni-nikan Jonatani
Iṣẹgun ti o larinrin ti Jonatani ni lori awọn Filistini, pẹlu iwa rere rè̩ ti ko ni abuku jẹ ẹri rere ti a le fi mọ nipa ti ara pe Jonatani i ba jé̩ ọba rere ti i ba gbamuṣe. S̩ugbọn Ọlọrun ti yàn Dafidi. Nigba ti Dafidi ti ṣẹgun Goliati, ti gbogbo orilẹ-ède si kokiki rè̩, Jonatani bọ ẹwù ileke rẹ ti ọmọ ọba, o si fi wọ Dafidi. O tilẹ fi ida rè̩ le Dafidi lọwọ, ida ti o lo nigba ti oun ati ẹni ti o ru ihamọra rè̩ gun oke giga lọ, ti wọn si le awọn Filistini sá.
Ki i ṣe pẹlu ẹmi ainireti ati ibanujẹ ni o fi gbe ẹwù oye ati ida rè̩ fun un, bi o ti le ri pẹlu awọn ẹlomiran, ni irú ipo bayii. O ni ifẹ ti o peye si Dafidi ati iwa-bi-Ọlọrun ti o ya ni lẹnu. A le foju ẹmi wo o, bi o ti n gbe ẹwù naa wọ Dafidi, lẹyin ti o ti gba a mọra, pẹlu ifẹ ará, ti o si wi fun un pe, “Iwọ ni yio jọba lori Israẹli, emi ni yio si ṣe ibikeji rẹ” (I Samuẹli 23:17).
Ọpọlọpọ ni ko ni inu didun si igbega ẹlomiran, bi wọn ti le ni inu didun si igbega ti ara wọn. Bibeli sọ fun wa pe ki ẹnikẹni má ṣe wa ti ara rè̩ bi ko ṣe ire ti ọmọnikeji rè̩ (I Kọrinti 10:24; Filippi 2:4), eyi ti o fi iwa Onigbagbọ tootọ hàn, ti i ṣe ẹmi ti ko mọ ti ara rè̩ nikan, ti o si fi ẹlomiran ṣaaju ara rè̩. Kristi ti kọ wa pe o sàn lati wà ni ipo irẹlẹ jù lati maa lepa ohun ayé, ọlá, tabi ipo laarin awọn eniyan. A sọ fun ni lati maa ṣe afẹri awọn ohun ti o wa loke, ki a má si ṣe fẹ ohun ti ayé yii. Iwe Mimọ ti jẹ ki a mọ pe Ọlọrun ni O n fun wa ni igbega, Oun nikan ṣoṣo ni O n gbe ọkan leke, ti O si n rè̩ ẹlomiran silẹ (Orin Dafidi 75:6, 7). Bi a ba gbà Ọrọ Ọlọrun gbọ, ti O sọ fun ni pe lati ọdọ Ọlọrun ni igbega ti n wa, nigba naa ko ni ṣoro fun wa lati maa yọ nigba ti igbega ba de, bi o tilẹ ṣe pe ki i ṣe fun awa tikara wa.
Jonatani ko jẹ ki ifẹ tabi ilepa ti rè̩, bi o ba tilẹ ni in, dábù anfaani tabi ire Israẹli. Oore-ọfẹ nlá nlà ni eyi jẹ ni igbesi-aye Jonatani ati ẹni kọọkan wa pẹlu. Igba le wa ti a ni lati pa irọra, èrè, ati itura ti wa tì, ki ipa ti Ọlọrun le maa tè̩ siwaju. Bi a ba fi ti Ọlọrun ṣiwaju ninu igbesi-aye wa, Oun yoo fun wa ni èrè ni Ijọba Rè̩ ti yoo tayọ ohunkohun ti o wu ki a fi silẹ fun Un nihin.
Ilara Saulu
Ilara Saulu bè̩rẹ nigba ti wọn pada sile lati ibi ti wọn gbe ti ba awọn ara Filistini jagun ti a si pa Goliati omirán. Awọn obinrin ati awọn ọmọde jade lati aarin ilu wa lati fi orin pade wọn wi pe, “Saulu pa ẹgbẹgbẹrun tirè̩, Dafidi si pa ẹgbẹgbarun tirè̩.” Bawo ni ẹmi ti o wà ninu Saulu ti yatọ si ti Jonatani ọmọ rè̩ to! Jonatani fi Ẹmi ti Jesu hàn ni ti rè̩, ṣugbọn ẹmi buburu ba le Saulu. Lati ọjọ naa ni o ti bè̩rẹ si fura si Dafidi. S̩ugbọn gbogbo Israẹli ni o fẹran Dafidi.
Orin aladun ti harpu Dafidi n kọ ko le pana ẹmi buburu ti ilara ati ikorira ti o jọba lọkàn Saulu mọ. Saulu sọ è̩ṣín si Dafidi, ṣugbọn o yẹ ẹ silẹ. Ọwọ Ọlọrun daabo bo o. Ọpọlọpọ igba ni o ṣe pe eṣu i ba pa awọn eniyan mimọ bi ọwọ Ọlọrun ko ba daabo bò wọn.
Ọkàn Dafidi Rẹwẹsi
Ọkan Dafidi rẹwẹsi, o si bẹrẹ si sa fun Saulu. O ba Jonatani sọrọ, o si sọ iṣoro rè̩ fun un wi pe iṣisè̩ kan ni o wa laarin ọkàn oun ati iku.
Irẹwẹsi jẹ ohun ija ti o lagbara ti o si n ṣe ọṣé̩ pupọ ti ọta ẹmi wa maa n lo. Onigbagbọ wo ni ọfà mimu ti o si lagbara yii ko ti ba nigba kan tabi omiran ri? Igboya a maa mu ọkàn jí giri, ṣugbọn irẹwẹsi a maa mu ki ọkan ṣaarẹ. Nigba ti ọkan awọn ọmọ-ẹyin daru nigba kan, Jesu wi fun wọn pe, “Ẹ maṣe jẹ ki ọkàn nyin dàru: ẹ gbà Ọlọrun gbọ, ẹ gbà mi gbọ pẹlu” (Johannu 14:1). Itunu ti ọrọ wọnni fun ọkàn wọn ko ṣe e fẹnu sọ! Nihin yii, a rii ti Jonatani n tù Dafidi ninu.
Pipa Majẹmu Mọ
Jonatani sọ fun Dafidi pe, “Wá, jẹ ki a jade lọ si pápá.” Nibẹ ni wọn tun ba ara wọn dá majẹmu lọtun.
Majẹmu jẹ ohun ti o lọwọ. Ọlọrun ba awọn eniyan Rè̩ da ọpọlọpọ majẹmu, Oun a si maa ṣe ipa ti Rè̩ nigba gbogbo. Ọlọrun n fẹ ki a pa majẹmu ti a ba ba A da mọ, ati eyi ti a ba ba ara wa da pẹlu. Ohun ribiribi ni fun wa lati pa awọn majẹmu wa mọ.
O ni lati jẹ pe Jonatani ti mọ pe a o fi ijọba fun Dafidi, nitori pe o mu Dafidi bura pe, Dafidi yoo ṣaanu fun oun ni gbogbo igba ti oun (Jonatani) ba wa laaye, yoo si ṣaanu fun ile oun, titi lae. Dafidi mu ileri rè̩ ṣẹ. A ka a pe, nigba ti a pa Jonatani loju ogun ti ijọba si ti di ti Dafidi, o mu arọ ọmọ Jonatani wa si ile rè̩ o si n ṣe itọju rè̩.
Anfaani Kan Si i
S̩iwaju ipade Dafidi ati Jonatani yii, Saulu ti tọ Samuẹli lọ, o n wa Dafidi. Nigba ti o wà nibẹ, anfaani agbara Ọlọrun ti o wa ni igbesi-aye Samuẹli ati ile-ẹkọ awọn woli kan Saulu lara. Oluwa ba a lo.
Boya nigba yii, o ranti ọjọ ti Samuẹli fi ororo yàn an ni ọba lori Israẹli: ọjọ ti Oluwa yi i lọkàn pada ti o si sọ ọ di ẹda titun. Nigba naa o kere loju ara rè̩. Nigbooṣe, ọkàn rè̩ gbega. Ilara, ikorira ati ibinu ti wọ ọkàn rè̩, o ti di ọba afasẹyin, o wà niwaju Samuẹli ati Ọlọrun, sibẹ lai si ọkàn ironupiwada. Ẹmi Ọlọrun ti rọ ọpọlọpọ afasẹyin nigba ti wọn ba wa si ile Ọlọrun, ṣugbọn gẹgẹ bi Saulu, ọpọlọpọ ni o ti pada lọ lai ronupiwada.
Jonatani ni ero pe baba oun yoo yi pada lẹyin ti o ba pada ti ọdọ Samuẹli de, ṣugbọn è̩ru n ba Dafidi sibẹ. Wọn jumọ sọrọ nipa bi wọn yoo ti ṣe mọ ki ni ero ọkàn Saulu si Dafidi.
Akoko ase oṣu titun sun mọ etile. O yẹ ki Dafidi wa si ibi ase yii ki o si joko ni ayè ti rè̩ nibi tabili Saulu. Dafidi bẹ Jonatani ki o yọọda fun oun, ki oun le lọ sibi ase baba ti rè̩ ni Betlẹhẹmu. Bi aiwa sibi ase yii ba fa ibinu Saulu, eyi yoo fi hàn daju pe ikorira ati iwa ikà wa lọkàn Saulu sibẹ. Nigba ti Saulu beere eredi ti Dafidi ko fi wa sibi ase, ti Jonatani si sọ fun un, inu bi Saulu ki i ṣe si Dafidi nikan, ṣugbọn ninu irunu rè̩, o gbiyanju lati pa Jonatani pẹlu.
Ipinya pẹlu Ibanujẹ
Ni owurọ ọjọ keji, gẹgẹ bi adehun ti wọn ti ṣe tẹlẹ, Jonatani lọ si pápá pẹlu ọrun ati ọfa rè̩ lati jẹ ki Dafidi mọ pe o ni lati sa asala fun ẹmi rè̩. O mu ọrun ati ọfa rè̩ bi ẹni pe o n lọ ṣọdẹ, ki a ma baa fura si i pe o n lọ pade Dafidi, ẹni ti o fi ara pamọ nibi apata Eseli ni akoko yii.
Jonatani tafa rekọja aala, o si kọ si ọdọmọkunrin rè̩, pe “Ọfà na ko ha wà niwaju rẹ bi?” “Sare, yara, máṣe duro.” Eyi jẹ ami fun Dafidi. Nigba ti ọdọmọkunrin yii ti ṣa ọfa wọnni tan, Jonatani ran an pada sile, Dafidi si jade nibi ti o gbe fi ara pamọ si. O wolẹ, o si bu ọlá fun Jonatani. Wọn rọ mọ ara wọn, wọn si sọkun nitori pe ibanujẹ wọn ko ṣe e fẹnu sọ. Bibeli sọ fun ni pe, wọn sọkun titi “Dafidi fi bori.” Boya ẹkun ti rè̩ jù ti Jonatani. Jonatani tu u ninu wi pe, “Ma lọ li alafia, bi o ti jẹ pe awa mejeji ti jumọ bura li orukọ OLUWA, pe, Ki OLUWA ki o wà lārin emi ati iwọ, lārin iru-ọmọ mi ati lārin iru-ọmọ rẹ lailai.” Ibarẹ Jonatani mu Dafidi lọkàn le lati “ja ija rere ti igbagbọ.” Gbogbo Onigbagbọ ni o n ri ire gba nipa idapọ mimọ pẹlu ara wọn. Iṣọkan iyanu yii ni o n so wọn pọ ṣọkan, ti o si n fun wọn ni anfaani lati tubọ le ja ajaṣẹgun fun Ọlọrun ati Ọrun rere.
Akoko kan de ni igbesi-ayé Dafidi ti o le wi pe, “Nitorina li awa ki yio bè̩ru, bi a tilẹ ṣi aiye ni idi, ti a si ṣi awọn òke nla nipò lọ si inu okun” (Orin Dafidi 46:2).
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni n sọ ni di ọrẹ tootọ?
- Ki ni ṣe ti ẹrù fi n ba Dafidi?
- Ki ni ṣe ti Saulu ko fi fẹran Dafidi?
- Iru ipo wo ni ọkàn Saulu wà?
- Eeṣe ti o fi yẹ ki Dafidi wa sibi ase oṣu titun ti Saulu ṣe?
- Ki ni ṣe ti ko fi wa?
- Jonatani ha ba Dafidi ré̩ bi?
- S̩e apejuwe bi o ti ri nigba ti Dafidi n dagbere fun Jonatani.