I Samuẹli 22:1, 2, 6-19; 23:1-29; Orin Dafidi 52:1-9; 56:1-13; 120:1-7; 142:1-7

Lesson 213 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Emi o ma yìn ọ lailai nitoripe iwọ li o ṣe e: emi o si ma duro de orukọ rẹ; nitori ti o dara li oju awọn enia mimọ rẹ” (Orin Dafidi 52:9) .
Cross References

I . Dafidi pẹlu awọn Olupọnju ati Onirobinujẹ

1 Dafidi sa lọ si ihò Adullamu, awọn idile baba rè̩ si sọkalẹ tọ ọ lọ nibẹ, I Samuẹli 22:1; Heberu 11:37, 38; Orin Dafidi 56:1-13

2. Dafidi di olori awọn ti o fi tinutinu yọọda ara wọn lati tè̩ le e, I Samuẹli 22:2; Heberu 2:10;Marku 12:37; Orin Dafidi 142:1-7

II. Pipa awọn Alufa Oluwa

1. Saulu sùn awọn iranṣẹ rẹ ni ẹsùn pé wọn ko jẹ olootọ, I Samuẹli 22:6-8

2. Doegi sọrọ lati tako Dafidi, I Samuẹli 22:9, 10; Orin Dafidi 52:1-9

3. Awọn alufa ṣe alaye pe wọn kò jẹbi, ṣugbọn Saulu paṣẹ pe ki a pa wọn, I Samuẹli 22:11-16

4. Awọn iranṣẹ Saulu ṣe ohun ti o dara nipa kikọ lati pa awọn alufa, ṣugbọn Doegi ṣe ohun buburu naa, I Samuẹli 22:17-19; Orin Dafidi 120:1-7; Iṣe Awọn Apọsteli 4:19

III. Saulu Lepa Dafidi

1. Dafidi gbà awọn ara Keila là lọwọ awọn Filistini, I Samuẹli 23:1-5

2. Saulu dọdẹ Dafidi kiri ni Keila, I Samuẹli 23:7, 8

3. Ọlọrun fi iwa aimoore awọn ara ilu Keila hàn Dafidi, I Samuẹli 23:9-12.

4. Jonatani mu ọwọ Dafidi le ninu Oluwa, I Samuẹli 23:13-18

5. Igbogun awọn Filistini ko jẹ ki ọwọ Saulu ati ẹgbẹ ọmọ-ogun rè̩ tè̩ Dafidi, I Samuẹli 23:19-29.

Notes
ÀLÀYÉ

Sisa a Dafidi

Ẹkọ wa yii bè̩rẹ pẹlu ohun ti o ṣẹlẹ ni ibi ti Dafidi gbe wà ninu ihò apata Adullamu. O salọ sibẹ lati bọ lọwọ Saulu. A ranti ipinya rè̩ pẹlu Jonatani ati pe Jonatani mu un lọkan le o si tu u ninu. Lẹyin ti o pinya pẹlu Jonatani, Dafidi lọ si Nobu lọdọ Ahimeleki alufa, nibi ti alufa yii n gbe pẹlu awọn ẹlẹgbẹ rè̩. Dafidi beere akara, Ahimeleki si fun un ninu awọn akara ifihan, eyi ti o ṣe pe awọn alufa nikan ni o ni ẹtọ lati jẹ.

Jesu tọka si eyi nigba ti Oun ati awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ n la oko ọkà kọja ni Ọjọ Isimi kan. Ebi n pa awọn ọmọ-ẹyin Rè̩, wọn si bẹrẹ si i ya ipẹ-ọka, wọn si n jẹ ẹ. Nigba naa ni awọn Farisi wi pe, “Wò o, awọn ọmọ-ẹhin rẹ nṣe eyi ti kò yẹ lati ṣe li ọjọ isimi.” S̩ugbọn Jesu da wọn lohun wi pe, “Ẹnyin kò ti kà ohun ti Dafidi ṣe, nigbati ebi npa a, ati awọn ti mbẹ lọdọ rè̩: bi o ti wọ ile Ọlọrun lọ, ti o si jẹ akara ifihàn, eyiti kò tọ fun u lati jẹ, ati fun awọn ti mbẹ lọdọ rè̩, bikoṣe fun kìki awọn alufa?. . . . ti nwọn si wà li aijẹbi?” (Matteu 12:3-5). Ebi n pa Dafidi ati awọn ti o wa pẹlu rè̩; Jesu si fi hàn pe bi o ba di dandan, riru ofin aṣà igbekalẹ isin ki i ṣe è̩ṣẹ.

Bakan naa ni Dafidi beere ida, Ahimeleki si fun un ni ida Goliati ti a fi kọ sinu Agọ gẹgẹ bi ohun iranti. Dafidi wi pe, “Kò si eyi ti o dabi rè̩.” Ida yii ṣọwọn gidigidi fun Dafidi nitori pe, nigbakuugba ni eyi yoo maa ran an leti igba ti Ọlọrun fun un ni iṣẹgun lori Goliati, ọta rè̩; dajudaju, ninu gbogbo eniyan, Dafidi ni ẹni ti o ni ẹtọ si i.

Dafidi,Apẹẹrẹ Jesu

Lati Nobu, Dafidi sa lọ si ihò apata Adullamu. Baba ati iya Dafidi tọ ọ wa. Wọn n darugbo lọ, Dafidi ko si fẹ ki wọn fara wewu; nitori naa o tọ ọba Moabu lọ lati bẹbẹ pe ki awọn obi rẹ le maa ba a gbe. Iwe itan sọ fun ni pe ọba Moabu ba ile Jesse tan lati ipasẹ Rutu. Ọba Moabu pẹlu jẹ ọta Saulu, eyi yoo si fi Dafidi lọkàn balẹ pe awọn obi rẹ wa lai lewu nibẹ ju ibikibi miiran lọ.

Awọn olupọnju, ati awọn onigbese ati awọn onirobinujẹ kó ara wọn jọ sọdọ Dafidi, o si di balogun wọn. Nihin a ri apẹẹrẹ iyanu nipa Jesu, Ẹni ti awọn orilẹ-ède Oun tikara Rè̩ kọ silẹ, sibẹ o wi pe, “Ẹ wá sọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣiṣẹ, ti a si di ẹrù wuwo le lori, emi o si fi isimi fun nyin” (Matteu 11:28).

Saulu ti ṣeleri lati fi idaji ijọba rẹ fun Dafidi bi o ba pa Goliati, ṣugbọn nisisiyi Saulu n fẹ le Dafidi kuro ninu ijọba naa. A ka nipa awọn akọni igbagbọ ti igba nì pe, “Nwọn rìn kákiri ninu awọ agutan ati ninu awọ ewurẹ; nwọn di alaini, olupọnju, ẹniti a nda loro; Awọn ẹniti aiye kò yẹ fun: nwọn nkiri ninu aṣálè̩, ati lori òke, ati ninu ihò ati ninu ihò abẹ ilẹ” (Heberu 11:37, 38). Eyi jẹ ipin Dafidi fun igba diẹ. Nigba ti Dafidi wà ninu ihò yii Ọlọrun mu un lọ si ile-ẹkọ ki oye idanwo ati wahala awọn olupọnju le ye e, ki o le mu un yẹ si i lati le ṣe akoso ijọba rè̩.

A Ba Awọn Iranṣẹ Saulu Wi

Saulu fura si gbogbo eniyan. O sùn Jonatani ati Dafidi ni ẹsùn pe, wọn ditè̩ si oun lati doju ijọba oun bolẹ. O rú ọkàn ẹya Benjamini ti i ṣe ẹya rẹ soke wi pe: “Ọmọ Jesse yio ha fun olukuluku nyin ni oko ati ọgba ajara bi, ki o si sọ gbogbo nyin di olori ẹgbẹgbẹrun ati olori ọrọrun bi? Ti gbogbo nyin fi dimọlù si mi, ti kò fi si ẹnikan ti o sọ ọ li eti mi pe, ọmọ mi ti ba ọmọ Jesse mulẹ, bḝni kò si si ẹnikan ninu nyin ti o ṣanu mi. . . ?” Ẹ wo bi o ti n fi ikaanu ati ibakẹdun ara rè̩ han ni gbangba to!

Pipa Awọn Alufa

Doegi, ara Edomu, ẹni ti oun tikara rè̩ buru bi i Saulu paapaa, ẹni ti ko si kà awọn iranṣẹ Ọlọrun si rara sọ fun Saulu pe oun ri Dafidi ni Nobu nigba ti Ahimeleki beere lọwọ Oluwa fun Dafidi, ti o si fun un ni ounjẹ ati ida Goliati. Saulu ranṣẹ pe Ahimeleki ati gbogbo awọn alufa ti o wà ni Nobu, o si sùn wọn ni ẹsùn iṣọtẹ. Ahimeleki kò mọ nipa rogbodiyan ti o wa laarin Saulu ati Dafidi, o si jẹ ki eyi di mimọ. S̩ugbọn Saulu dahun pe, “Ahimeleki, kikú ni iwọ o kú, iwọ, ati gbogbo idile baba rẹ.” Nigba naa ni Saulu paṣẹ fun awọn ti n sare niwaju rè̩ lati pa wọn. S̩ugbọn wọn kọ lati kọlu awọn iranṣẹ Ọlọrun nitori ti wọn bẹru Ọlọrun ju aṣẹ ọba lọ. S̩ugbọn Doegi òṣonu ko ni ibẹru Ọlọrun, bẹẹ ni ko si ni ifẹ si ọmọ eniyan ninu ookan-aya rè̩, nitori naa ni kiakia ni o mu aṣẹ ọba ṣẹ ti o si pa awọn alufa, awọn obinrin ati awọn ọmọ wẹwé̩ ilu naa, ati gbogbo ohun-ọsin wọn.

Dafidi kọ akọsilẹ yii nipa Doegi, “Iwọ fẹ ibi jù ire lọ; ati eke jù ati sọ ododo lọ.. . . . kiyesi ọkunrin ti kò fi Ọlọrun ṣe agbara rè̩; bikoṣe li ọpọlọpọ ọrọ rè̩ li o gbẹkẹle, o si mu ara rè̩ le ninu iwa-buburu rè̩” (Orin Dafidi 52:3, 7).

Opitan Ju kan sọ pe awọn ti a pa to “okoo-din-nirinwo o le marun,” (385) boya gbogbo ẹbi awọn alufa pẹlu awọn alufa – gbogbo awọn olugbe ilu Nobu ni Saulu parun raurau. Pipa ailaanu ti Saulu pa awọn alufa ilu Nobu ni iwa ibi ti o buru ju lọ ti Saulu hù ni gbogbo igba ti o fi jọba. Itan atọwọ-dọwọ awọn Ju kan ti o fidi mulẹ sọ fun ni pe Doegi ni ẹni ti a tọka si pe o ru ihamọra Saulu ni akoko iku rè̩ (I Samuẹli 31:3-5). Nigba ti Saulu gbọgbẹ loju ogun nibi ti o gbe n ba awọn Filistini jà, o fi ida ẹni ti o rù ihamọra rè̩ pa ara rè̩, lẹyin eyi, ẹni ti o ru ihamọra Saulu si pa ara rè̩. Bayi ni awọn mejeeji yii parun; bi o ba si jẹ pe Doeji ni gẹgẹ bi iwe itan ti wi, o ni lati jẹ pe ida kan naa ti Doegi lo lati fi pa awọn alufa ni Nobu ni awọn mejeeji yii lo lati fi gbẹmi ara wọn.

Awọn Filistini ni Keila

Awọn Filistini n ji ọkà awọn ara Keila ni ilẹ ipaka wọn. Dafidi kó awọn ẹlẹgbẹ rè̩ mọra lati lọ pa awọn Filistini, o si gbà awọn eniyan wọnyi lọwọ awọn ọta wọn. Iroyin de eti Saulu pe Dafidi wà ni Keila, Saulu si rò pe, o to akoko wayi lati ka Dafidi mọ, nigba ti ilẹkun ilu se mọ ọn. S̩ugbọn igbẹkẹle Dafidi wà ninu Ọlọrun, nitori naa o lọ beere lọwọ Oluwa bi awọn ara Keila yoo fi oun le Saulu lọwọ. Oluwa sọ fun un pe awọn eniyan yoo gbagbe oore ti o ti ṣe fun wọn, wọn yoo si fi i le Saulu lọwọ. Nitori naa Dafidi ati awọn ẹlẹgbẹ rè̩ fi Keila silẹ, wọn si lọ n gbe ori-oke kan ni aginju Sifi.

Ibẹwò Jonatani

Ninu igbo yii ni Jonatani gbe lọ bẹ Dafidi wò. A ko le sọ boya iranṣẹ abẹlẹ ti n lọ laarin Jonatani ati Dafidi, ṣugbọn ni akoko yii, Jonatani mọ ibi ti Dafidi wà, o si wa bẹ ẹ wò, “o si gba a niyanju nipa ti Ọlọrun.” Wo iru ikiyà ti eyi le fi fun Dafidi! Nigba ti a ba mu wa lọkàn le nipa ti Ọlọrun, eyi ni i ṣe imulọkanle tootọ. Eyi yoo mu wa duro, yoo si fun ni lókun. O dabi ẹni pe ọkàn Jonatani balè̩ pe baba rè̩ ki yoo ri Dafidi, o si gbagbọ tọkantọkan pe nigbooṣe Dafidi yoo jọba lori Israẹli.

Ohun ti a ri tẹle eyi ni pe Saulu wa ni ihà kan oke, ati Dafidi ni ihà keji rè̩. Nipa ti ẹda, a ri i pe awọn ogunlọgọ ẹgbẹ ọmọ-ogun ti o n tẹle Saulu fẹrẹ gbe iba eniyan diẹ ti o wà pẹlu Dafidi mì. Igba melo ni eṣu ti duro lati pa awọn eniyan Ọlọrun run, ṣugbọn ọwọ Ọlọrun a dide fun iranlọwọ wọn! Oluwa mọ akoko naa gan an ti o yẹ ki awọn Filistini wa gbogun ti ilẹ Israẹli. Onṣẹ kan tọ Saulu wa wi pe, “Iwọ yara ki o si wá; nitoriti awọn Filistini ti gbe ogun ti ilẹ wa.” Saulu pada kuro ni lilepa Dafidi, o si lọ ba awọn Filistini jà. Nigba yi, Dafidi tun ni anfaani lati sọ wi pe, “Angẹli OLUWA yi awọn ti o bè̩ru rè̩ ká, o si gbà wọn” (Orin Dafidi 34:7).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Iru awọn eniyan wo ni o tọ Dafidi wa nigba ti o sa fun Saulu?
  2. Nibo ni Dafidi lọ fi baba ati iya rè̩ pamọ si fun aabo?
  3. Ki ni ṣe ti Saulu fẹ ki a pa awọn alufa Ọlọrun?
  4. Ta ni Saulu kọkọ paṣẹ fun pe ki o pa wọn? irú ihà wo ni wọn kọ si aṣẹ yii?
  5. Ta ni pa wọn nikẹyin?
  6. Sọ fun wa nipa ida ti a fi pa awọn alufa naa?
  7. Ta ni lọ bẹ Dafidi wò ninu igbo? Ki ni o si ṣe?
  8. Bawo ni ẹgbẹ ọmọ-ogun Saulu ti sun mọ Dafidi to?
  9. Bawo ni Ọlọrun ṣe ṣe iranwọ ti ọwọ ko fi tè̩ Dafidi?