Lesson 214 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ki olukuluku ọkàn ki o foribalẹ fun awọn alaṣẹ ti o wà ni ipo giga. Nitori kò si aṣẹ kan, bikoṣe lati ọdọ Ọlọrun wá: awọn alaṣẹ ti o si wà, lati ọdọ Ọlọrun li a ti làna rè̩ wá” (Romu 13:1).Cross References
I. Saulu Lepa Dafidi Kikankikan
1. Aṣayan ẹgbẹẹdogun ọkunrin ti Saulu pọ rekọja ju ọmọ-ogun ti Dafidi ni ilọpo marun, I Samuẹli 24:1-3; 23:13; Orin Dafidi 33:16-20
2. Inunibini ati idanwo Dafidi mu ki o ni igbẹkẹle nla ninu Ọlọrun, Orin Dafidi 57:1-
II. Iwa Ọmọluwabi Dafidi
1. Awọn ti ko wá itọni Ọlọrun fún Dafidi ni imọran buburu eyi ti o mu un huwa pẹlu iwarapapà, I Samuẹli 24:4; Orin Dafidi 1:1, 2; I Awọn Ọba 12:6-11; Jobu 2:9, 10
2. Dafidi kabamọ iṣe rè̩ bi o tilẹ jẹ pe kò ni ipalara ninu, I Samuẹli 24:5-7; Ẹksodu 22:28; Iṣe Awọn Apọsteli 23:5; Romu 13:1; I Peteru 2:17
3. Dafidi bọwọ fun Saulu gẹgẹ bi ọba ati gẹgẹ bi ẹni-ami-ororo Oluwa, I Samuẹli 24:8, 10; 15:30; 10:24; Daniẹli 6:21
4. Ẹri ti Dafidi jé̩ fi hàn pe oun ko ni àránkàn, bẹẹ ni ko si ṣe ojukokoro lati gba ijọba naa, I Samuẹli 24:9-11; Galatia 5: 20; Johannu 5:44
5. Dafidi fi idajọ ati ẹsan lé Ọlọrun lọwọ, o si ni ifẹ tootọ si awọn ọta rè̩, I Samuẹli 24:12-15; Ẹksodu 23:4, 5; Lefitiku 19:18; Deuteronomi 32:35; Orin Dafidi 20:6-8; 35:1-28; Owe 20:22; 24:17, 29; 25:21, 22; Matteu 5:43, 44; Heberu 10:30
III. Iyipada Iṣe Saulu fun Igba Diẹ
1. Aanu ati iwa-bi-Ọlọrun ti Dafidi fi hàn mu ki Saulu ba a lajà, ISamuẹli 24:16; Owe 15:1
2. Saulu jẹwọ titayọ ododo Dafidi, I Samuẹli 24:17-19;Owe 25:21, 22
3. Saulu mọ pe Ọlọrun wà pẹlu Dafidi ati pe oun ni yoo jẹ ọba lẹyin oun, I Samuẹli 24:20
4. Wọn da majẹmu alaafia, wọn si ṣe ibura kan nipa iru ọmọ Saulu, I Samuẹli 24:21, 22; 20:15; II Samuẹli 9:1-11
Notes
ÀLÀYÉSaulu, Ọba ti a Kọ ati Dafidi Isansa
Ẹkọ wa yii fi oriṣi eniyan meji ninu Bibeli siwaju wa, ti yoo ṣe wa ni ire bi a ba ṣe akiyesi igbesi-ayé wọn, ati ete ti o wà nidi ihuwasi wọn. Saulu jẹ ọba Israẹli, ti eniyan Ọlọrun fi ami ororo yàn ni igbọran si aṣẹ Ọlọrun, ti awọn eniyan orilẹ-ède si tẹwọ gba. Lẹyin ọpọ iwa aitọ, iṣọtẹ ati aigbọran Saulu, Ọlọrun kọ Saulu, ṣugbọn O fi i silẹ bi ọba, ṣugbọn O fi i silẹ sori oye. Ẹni keji ni Dafidi, ẹni ti ko lọjọ lori to bẹẹ, ẹni ti eniyan Ọlọrun pẹlu si fi ami ororo yàn ni ọba ni igbọran si aṣẹ Ọlọrun, ti awọn eniyan diẹ tẹwọ gbà bi alakoso wọn, ṣugbọn ti ọpọ si pọnle bi akin ati akọni ọkunrin. Nibikibi ti Ọlọrun ba fi Dafidi si, oun a maa fi irẹlẹ, ifẹ atinuwa ati igbọran ṣiṣẹ; ṣugbọn fun ọdun pupọ ni o fi wà bi isansa, jinna si awọn eniyan rè̩ ati orilẹ-ède rè̩ ti o fẹran lọpọlọpọ.
Igba pupọ wà, bi a ti n wo iṣẹ ati eto Ọlọrun fun igbesi-ayé wa ati ti awọn ẹlomiran, ti o n dabi ẹni pe o kun fun ọpọlọpọ adiitu. Dafidi paapaa, iranṣẹ Ọlọrun tootọ gbadura fun iranlọwọ ati agbara Ọlọrun nigba ti awọn eniyan buburu ṣe inunibini si i, ti wọn si dà ā laamu. O rán Ọlọrun leti pe, “eniyan buburu nṣogo ifẹ ọkàn rè̩, o si nsure fun olojukokoro, o si nkẹgan OLUWA.” O si tun sọ wi pe, “eniyan buburu, nipa igberaga oju rè̩, kò fẹ ṣe afẹri Ọlọrun: Ọlọrun kò si ni gbogbo ironu rè̩. . . . O ti wi li ọkàn rè̩ pe, A ki yio ṣi mi ni ipò: lati irandiran emi ki yio si ninu ipọnju” (Orin Dafidi 10:3, 4, 6). S̩ugbọn ninu gbogbo wọnyi, a kọ Dafidi lé̩kọ ti o niyelori; nitori pe nipa awọn idanwo kikoro wọnyi, agbara ati ọgbọn rè̩ pọ sii, igbẹkẹle rè̩ ninu Ọlọrun si tubọ fidi mulẹ. O mọ pe Ọlọrun yoo ran iranwọ lati Ọrun wa, yoo si gbà oun kuro lọwọ ẹgàn awọn eniyan buburu ti o fẹ gbe e mì, bi o tilẹ jẹ pé wọn ti dẹ awọn silẹ fun ẹsẹ rè̩, ti wọn si ti wa ihò silẹ niwaju rè̩. Lai si aniani, Dafidi ri i pe Ọlọrun dahun adura rè̩, ati pe ohun gbogbo si ṣiṣẹ pọ fun ire rè̩, nitori o sọ fun ni pe awọn eniyan buburu tikara wọn ṣubu sinu ọfin ti wọn wà ati awọn ti wọn dẹ silẹ de e. Ninu gbogbo eyi, Dafidi fi iyin fun Ọlọrun (Orin Dafidi 57:3, 6-11).
Idanwo ati wahala ko fi hàn pe Ọlọrun ti kẹyin si wa. Pẹlu inu didun ati ifẹ ni Ọlọrun fi n bojuwò awọn ọmọ Rè̩ ti o wa ninu irora, awọn ẹni ti o wu U lati mu la idanwo ati iṣoro kọja, ki a ba le mu awọn aipe ti o wa ni igbesi-ayé wọn kuro. Nitori pe oju ọrun ṣu dùdù ti ikuuku si boju oorun iyọnú Ọlọrun si wa ko fi hàn pe oorùn ifẹ Rè̩ ti dẹkun lati maa ràn. Awọn akoko idanwo wọnyi a maa de ba gbogbo awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun ti o fẹ ododo, ti o si n lepa lati di pipe. Nigba ti a ba n la iru idanwo bayi kọja, o yẹ ki a sọ bi Dafidi ti wi, pe “Ọkàn mi ti mura, Ọlọrun, ọkàn mi ti mura: emi o kọrin, emi o si ma kọrin iyin. . . Gbigbe-ga ni ọ, Ọlọrun, jù awọn ọrun lọ ati ogo rẹ jù gbogbo aiye lọ” (Orin Dafidi 57:7, 11).
Ki i ṣe ibanujẹ diẹ ni ẹni ti a lé kuro nile, lọdọ awọn olufẹ rè̩ yoo ni. Ki a mu ni lọta, ki a si maa lepa ẹni bi arufin ko ni fi eniyan lọkan balẹ bi o tilẹ jẹ, ẹni bi Dafidi, paapaa nigba ti ko ba si ero ibi tabi idalẹbi lọkan ẹni naa ti a n lepa rè̩. Ki o di dandan fun ni lati lọ maa fi inu ihò ṣe ibugbe ninu aginju, ki a di ẹni ti n fi ori jágbo kiri ki a to ri ounjẹ oojọ jẹ, ki a dù wa ni itura, alaafia ati itunu ti a n ri labẹ ile, ki paṣan ebi maa na wa faifai, ki oungbẹ maa gbẹ wa, ki a wà lai sun, lai wo, pẹlu gbogbo ipaya ti ẹran-ara ẹda le fara dà mọ -- iwọnyi yoo fi ẹnikẹni làkalàka bi o ti wu ki o jẹ ẹni iwa-bi-Ọlọrun to. S̩ugbọn gbogbo idanwo wọnyi de ba ẹni ti Ọlọrun ti yàn ni ọba -- ẹni bi ti inu Ọlọrun – eyi si kọ ọ ni otitọ ti o jinlẹ ti oun ko mọ tẹlẹ ri, o si fun un ni igbẹkẹle pipe ninu Ọlọrun jù bi o ti ro pe o yẹ tabi ti o ṣe e ṣe lati ni lọ. “Ohun gbogbo li o nṣiṣẹ pọ si rere fun awọn ti o fẹ Ọlọrun” (Romu 8:28). Dafidi wi pe, “Nigbati ọkàn mi rè̩wẹsi ninu mi, nigbana ni iwọ mọ ipa-ọna mi” (Orin Dafidi 142:3). O sọ bẹẹ pẹlu igbagbọ, nitori pe o ni idaniloju, bi o tilẹ jẹ pe ikuuku ṣu dùdù, ti inilara pọ, ṣugbọn o mọ pe nikẹyin “awọn olododo yio yi mi ka kiri; nitori iwọ o fi ọpọlọpọ ba mi ṣe” (Orin Dafidi 142:7).
Saulu yatọ si Dafidi. Nigba ti a kọ fi ami ororo yàn Saulu ni ọba, o ni ẹmi irẹlẹ, ṣugbọn ko pẹ ti o fi di a-ṣe-ti-inu-ẹni ati olori-kunkun. Oun ko lọ lati “ipa de ipa” ninu afonifoji idanwo, lati mọ oju rere Ọlọrun ninu idanwo iwẹnumọ Rè̩; bakan naa ni ko lọ lati “igbagbọ de igbagbọ” lati ri ododo Ọlọrun bi a ti maa n fi hàn fun ni nigba ti a ba tẹle ilana ayeraye ni: “Olododo yio wà nipa igbagbọ” (Orin Dafidi 84:7; Romu 1:17). Yatọ si eyi, Saulu lọ ninu agbara ara rè̩, ninu ọgbọn ti rè̩, ni idanú ara rè̩ gẹgẹ bi ifẹ ọkàn rè̩ ati igbekalẹ ti ara rè̩. Igbesi-ayé ìkuna patapata ni o gbe. Aṣeyọri patapata ni igbesi-ayé rẹ i ba jasi bi o ba tẹle ọna Ọlọrun.
Ẹni Ami-Ororo Oluwa
A maa n fi ami ororo yàn awọn woli, awọn alufa, ati awọn ọba fun iṣẹ wọn ni igba Majẹmu Laelae. Eyi ni o fi hàn pe lati ọdọ Ọlọrun wa ni ipe wọn, ati pe niwọn igba ti wọn ba wà ninu ifẹ Ọlọrun, Ọlọrun yoo gbe wọn ro, yoo daabo bo wọn, yoo si maa tọ wọn pẹlu. Ifororoyàn yii jẹ apẹẹrẹ ifororoyàn ti o tun tobi jù eyi lọ -- ifororoyàn ti ẹmi – ti yoo jẹ ti awọn ti Ọlọrun yoo pè lati jẹ ọmọ Rè̩ ni akoko Majẹmu Titun. Ifororoyàn ti akoko Majẹmu Laelae ṣe danindanin fun awọn iranṣẹ Ọlọrun wọnyi, ipokipo ti o wu ki a pè wọn si, niwọn bi iṣẹ wọn ko ti le yege patapata lai si rè̩. Bakan naa ni ifi Agbara Ẹmi Mimọ ati ina wọni -- Ifororoyan ti Ẹmi ti a n fi fun awọn ti o ba fara balẹ wa a pẹlu igbagbọ -- ṣe pataki, o si ṣe danindanin fun aṣeyọri ninu iṣẹ-isin wa si Ọlọrun, ipokipo ti o wu ki a pè wa si ninu iṣẹ Rè̩.
Samuẹli ti fi ami-ororo yàn Saulu. Ẹmi Ọlọrun si ti ba le e nigba naa lati fi hàn pe inu Ọlọrun dun si i. Ọlọrun fun un ni ọkàn titun, eyi ti a fi mọ pe, o wa ni ipo ẹni iwa-bi-Ọlọrun. Saulu sọ asọtẹlẹ laarin awọn woli, eyi fi hàn pe Ẹmi Ọlọrun wà pẹlu rè̩, o si ni agbara Ọlọrun de ayè kan, ati pe, o n ba Ọlọrun rin timọ-timọ ni igba naa. S̩ugbọn a mọ pe ko ṣoro lati mu Ẹmi Ọlọrun binu. A kilọ fun ni pe ewu wà ninu mimu Un binu, nitori yoo mu ki Ọlọrun kọ ẹni naa silẹ bi o ba fi ori-kunkun takú sinu aṣà yii. Akoko naa de ti Saulu mu Ẹmi Ọlọrun binu to bẹẹ ti Ẹmi Ọlọrun kò tun dari rè̩ mọ. S̩ugbọn Dafidi mọ pe Ọlọrun ni o fi Saulu si ayè ọba, ati pe lati mu un kuro lori oye wa ni ọwọ Ọlọrun, ani ọwọ Ọlọrun nikan ṣoṣo.
Ninu ijọba ilu nibi ti a n bọwọ fun ofin ati eto iṣakoso lọna ẹtọ, o ti di mimọ pe ẹni ti o lagbara lati ṣe ofin nikan ni o lagbara lati yi ofin naa pada, ọwọ ti o ba si fi ẹni kan si ayè ibi ti a gbe fi ọkan tan ẹni naa nikan ni o lagbara lati mu un kuro ni ayè naa. Awọn wọnni ti ko fara mọ igbekalẹ yii ni awọn adalurú ati awọn ọlọtè̩ ti ko fẹ tẹriba fun akoso ti o lọ leto-leto. Ko si ayè fun ibi wọnyi nibi ti Ọlọrun gbe n ṣe akoso otitọ ati ododo tabi ninu ọkàn awọn ọmọ Ọlọrun. Dafidi ko si ninu awọn ẹgbẹ mejeeji wọnyi, gẹgẹ bi ẹkọ wa yii ti fi hàn.
A fi ami-ororo yàn Dafidi si ipò ọba ni gẹrẹ ti Ọlọrun kọ Saulu silẹ. S̩ugbọn ẹmi kan wà ninu Dafidi ti ki yoo gbe ọwọ rè̩ soke lati wa ẹtọ rè̩ tabi lati jà fun un, bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun ni o fun un ni anfaani lai jẹ pe o fi ọwọ ara rẹ wa a. (I Kọrinti 13:5). O yẹ ki o le rò pe, nitori ti Ọlọrun ti fi oun jọba, iṣẹ oun ni lati maa ṣe akoso ijọba ododo fun ogo ati ọlá Ọlọrun, ki o si mu ohunkohun ti o ba doju kọ Ọlọrun ti o si n ṣọtè̩ si aṣẹ Rè̩ kuro. O yẹ ki o le rò wi pe niwọn bi o ti jẹ pe lẹyin ikọsilẹ Saulu ni a fi ororo yàn oun, ti a si ti sọ fun Saulu pe ẹlomiran yoo gba ijọba rè̩, o jẹ è̩tọ ati iṣẹ oun lati mu ifẹ Ọlọrun ti o hàn gbangba to bayi ṣẹ.
Igba pupọ ni o wà ti a le ri ifẹ Ọlọrun dajudaju ninu awọn ohun kan, ṣugbọn sibẹ, a ko le tẹ siwaju ki a ma baa gbesẹ ṣiwaju akoko Ọlọrun. Ifẹ Ọlọrun le di mimọ fun wa lai jẹ pe akoko ti O fẹ mu ifẹ Rè̩ yii ṣẹ di mimọ fun wa. A ni lati ri i pe a ko duro lati mọ ifẹ Ọlọrun nikan ninu ohunkohun, ṣugbọn a ni lati duro de akoko Rè̩ pẹlu.
Niwọn igba ti o ṣe pe gbogbo agbara ni ti Ọlọrun, bi O ba fẹ mu ohun kan ṣẹ, O ni ipa lati mu ohunkohun ti yoo tako ifẹ Rè̩ tabi ti o le ṣe idena ifẹ Rè̩ kuro. Otitọ ni ọrọ yii pe, nigba ti awọn eniyan ba n huwa bi wọn ti yàn ni idanú ara wọn, Ọlọrun maa n lo igbesẹ wọn lati mu ifẹ ti Rè̩ ṣẹ. Alagbara Nla ni Ọlọrun, O si le lo titobi-julọ agbara Rè̩ sibẹ ki o ma si pa ifẹ-inu eniyan lara eyi ti O ti yọọda fun ọmọ-eniyan.
Nipasẹ idagbasoke eto Ọlọrun ninu ohunkohun ni a le fi mọ daju, ohun ti ifẹ Ọlọrun ninu eto naa ja si. Bi Ọlọrun ko ba pese ni kikun fun ohun kan, a le sọ pe ki i ṣe ifẹ pipe Rè̩ ni lati dawọ le ohun naa ni akoko naa.
Ki o to di pe a di ayè pataki kan mu, Ọlọrun le jẹ ki àyè pataki naa di mimọ fun wa, ki a ba le mura silẹ, nipa adura, nipa ifi-ara-rubọ ati nipa ẹkọ fun ayè naa. Ki i ṣe igba pupọ ni Ọlọrun n fi inu hàn ẹnikẹni ninu wa lọna bayi. S̩ugbọn bi o ba ṣe ọna bayi ni Ọlọrun fẹ gbe e gbà, O ni ẹtọ ati aṣẹ lati ṣe bẹẹ. Bi o ba si wu U lati mu wa gba ọna jijin ati lile nipa lilọ si ile-ẹkọ iriri, lai sọ fun wa tẹlẹ, fun ire wa, lati mu wa yẹ fun ayè ti O fẹ pè wa si, ọla nla Rè̩ ni pẹlu. S̩ugbọn bi a ba bẹrẹ si ṣeto fun ara wa ti a ko si duro lati ri ọna ti Ọlọrun fẹ gbe ọran naa gba, gẹgẹ bi awamaridi ọgbọn ati ilana pipe Rè̩, a o ri i pe a ti mu ki ifẹ Ọlọrun fun wa ati eto Rè̩ nipa ti wa falẹ nipa iwa wèrè wa. A o ri i pe a pẹ “ni aginju iriri,” ati pe anfaani lati sin Ọlọrun kara-kara yoo si falẹ ju bẹẹ lọ.
Diẹ ninu imọràn awọn ti o yi Dafidi ká ti a le rò pe o jẹ imọràn ọlọgbọn ni Dafidi tẹle. Ninu ṣiṣe eyi paapaa, o di ohun ti o kabamọ si lẹsẹkẹsẹ. O le dabi ẹni pe gige diẹ ninu iṣẹti aṣọ ọba ko jamọ nkankan nigba ti o ṣe pe pipa ni wọn tilẹ sọ pe ki o pa a. Ohun ti o ṣe yi jẹ tita abuku si ọba, ṣugbọn eyi kere lẹgbẹ ohun ti o le ṣe ti o si dabi ẹni pe o tilẹ ni ẹtọ lati ṣe. Awọn alamọràn fi ileri ti Ọlọrun ti ṣe fun Dafidi gbe imọràn wọn lẹsẹ lọna odi, ani awọn ileri ti Ọlọrun ti fi mu un lọkan le ti Dafidi pẹlu si fẹyin ti gbọningbọnin lakoko idanwo yii.
S̩ugbọn awọn eniyan wọnyi ko mọ ohùn Ọlọrun bi ti Dafidi, o si hàn gbangba pe wọn ko fẹ tẹle akoso Ọlọrun patapata gẹgẹ bi Dafidi ti ṣe. Dafidi ti ni ipinnu lati fi gbogbo ọràn naa le Ọlọrun lọwọ patapata, nitori ti o mọ pe lọna bayi nikan ni ogo ati ọlá le jẹ ti Ọlọrun, ti ohun gbogbo yoo si yọri si rere. Awọn ẹlomiran yoo da a lare fun ohun ti o ṣe, niwọn igba ti yoo le maa fi iṣẹti aṣọ yii hàn pe oun ko fẹ lati pa Saulu; ṣugbọn ifarahàn rẹ ni ẹnu ihò ti Saulu ṣẹṣẹ ti kuro jẹ ẹri ti o daju bakan naa. Nitori abukù diẹ si ẹni ami-ororo Ọlọrun yii, Dafidi jẹ irora ninu ẹmi. O ni ọkàn tité̩ si Ọlọrun ati si ifẹ Ọlọrun. Dafidi a maa gbadura nigba gbogbo pe ki aya oun má ṣe yigbi lọnakọna ninu iwa ati iṣe rè̩ si Ọlọrun tabi awọn eniyan Ọlọrun. Eyi jẹ idi kan ti Ọlọrun fi pe Dafidi ni ẹni bi ti inu Oun ati pe o ni ọkàn pipe. Dafidi wa ogo ati ọlá Ọlọrun ati ire awọn eniyan Ọlọrun ninu ohunkohun ti o ba n ṣe ati pe bi o tilẹ jẹ pe o ṣe awọn aṣiṣe pataki kan, o ṣetan nigba gbogbo lati jẹwọ wọn ati lati ronupiwada pẹlu ẹkún kikoro (Orin Dafidi 51:1-19). Dafidi fi ọlá pupọ fun ẹni ti Ọlọrun ti pè ti O si fi ami-ororo yàn, nitori ti o rò ninu ọkàn rè̩ pe, Ọlọrun le ṣe iké̩ ati igè̩ oun ki O si fi oun si ayè nigba ti akoko Rè̩ ba to.
Bi Dafidi ba fi oju yẹpẹrẹ wo ifororoyàn Saulu, yoo tumọ si pe o fi oju yẹpẹrẹ wo ifororo yan ti oun tikara rè̩, bi ko tilẹ lero lati ṣe bẹẹ. Ko si aniani pe Ọlọrun ni O n ṣe akoso nigba ti Samuẹli mu ki awọn ọmọ Jesse meje kọja niwaju rè̩ lai ta ororo si ẹnikẹni wọn lori, nitori Ẹmi Ọlọrun ko fi hàn pe ẹni ti Ọlọrun yàn ti fara hàn. Lai si aniani, Dafidi ti bẹrẹ si fi ara rẹ rubọ fun Ọlọrun bi o ti n bọ kankan lati pápá lati gba ami ororo rè̩. O ti n ṣe eyi fun oṣu ati ọdun pupọ ṣiwaju akoko yii, lai si aniani. Oun ki ba ti yẹ fun ifororoyàn yii bi ko ba ti wà ni imurasilẹ. Bi o ba si fi oju yẹpẹrẹ wò anfaani pataki ifororoyàn yii ninu ẹlomiran, eyi yoo fi hàn pe, ifororoyàn ti oun paapaa ko nilaari ju eyi ti ẹnikẹni le fọwọ rọ tì bi o ti wu u.
Gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun ati alabaṣiṣẹpọ ninu ọgba ajara Ọlọrun, a beere ohun kan naa lọwọ wa ninu iwa ati iṣe wa si awọn ẹni ami-ororo Ọlọrun ti O fi si ayè pataki ninu ọgba ajara Rè̩. Ipè awọn wọnyi ga jù ti awọn ọba ti aṣẹ wọn i ṣe ti ayé yii. Ti wọn ki i ṣe ade, ọpa-alade tabi ité̩ aye yii. Wọn ko ni iru agbara idanikan paṣẹ bi ti awọn ọba aye. Gbogbo ayé le ṣe ainaani aṣẹ ati akoso wọn. S̩ugbọn sibẹsibẹ ipè ati yiyàn wọn ati iṣẹ ti a fi le wọn lọwọ daju.
Awọn wọnni ti Ọlọrun yàn lati maa bọ agbo Ọlọrun, lati maa ṣe abojuto wọn, lati ba wọn wi ati lati ṣe akoso nigba ti o ba tọ yẹ ni ẹni ti a ba ka si lọna ti ko rẹlẹ si eyi ti Dafidi kà Saulu si gẹgẹ bi ẹni ami-ororo Oluwa. Iduro tabi iṣubu wọn jẹ niwaju Ọlọrun, ki i si ṣe niwaju eniyan. Wọn yoo jihin ohun gbogbo ti wọn sọ ati eyi ti wọn ṣe fun Ọlọrun. Bi wọn ba ṣe alaiṣootọ ninu eyi ti a pè wọn si, Ọlọrun ni yoo ba wọn wi, ti yoo si pa wọn ti, bi o ba ṣe pe eyi ni o tọ loju Rè̩. Ti wa ni lati bu ọlá fun awọn ẹni ami-ororo Ọlọrun ki a si fi ohun wọnni ti i ṣe ti Rè̩ nikan le E lọwọ patapata ki O le ṣe ohunkohun ti O ba fẹ fun wọn, ni akoko ti O wu U
Ọpọlọpọ iwa rere ti o yani lẹnu ni o wa ninu igbesi-ayé ọba Israẹli ti i ṣe eniyan Ọlọrun yii. Ohun pupọ ni a le sọ nipa eyi, ati awọn miiran gbogbo ti awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun ti a yàn ninu ẹkọ yii tọka si. Ninu ẹkọ ọjọ iwaju, nibi ti Dafidi tun gbe da ẹmi Saulu si, a o tun ni anfaani lati tubọ kẹkọ nipa iwa rere wọnyi ti o sọ nipa odiwọn giga ti Ọlọrun beere lọwọ awọn ti igba a nì. A o si tun kẹkọ nipa awọn ohun ti o ga jù eyi lọ ti Ọlọrun n beere lọwọ awa ti o wa nigba ibukun kikún ti akoko Ihinrere – akoko ti awọn eniyan mimọ Ọlọrun igba a ni n foju sọna si pẹlu iyanu ati imurasilẹ, ti ibukun ologo wọnni ti a o tu jade lọfẹ sori awọn ti o ba wá Ọlọrun pẹlu igbagbọ ati ọkàn isin tootọ.
Questions
AWỌN IBEERE- Awọn wo ni a n fi ororo yàn ni akoko Majẹmu Laelae?
- Bawo ni a ṣe n fi ami ororo yàn eniyan lọjọ oni? Ki ni awọn anfaani kikun ti o wa ninu awọn ileri ti a fi lelẹ fun awọn ti o ba ni ifororoyàn bayii?
- Ki ni ṣe ti Dafidi di isansa?
- O ha ṣe anfaani lati saba maa gba imọran awọn wọnni ti ko kuku tẹle itọni Ẹmi Ọlọrun patapata?
- Bawo ni eniyan ṣe le mọ akoko ti o jẹ ifẹ Ọlọrun lati ṣe ohun kan?
- Ki ni ohun miiran ti a ni lati tun kiyesi ninu eto wa lẹyin ti a ba mọ ifẹ Ọlọrun?
- Njẹ Ẹmi Ọlọrun maa n tọni ni ọna meji ti o tako ara wọn lori ohun kan naa? (Ka I Kọrinti 14:33, 40).
- Ti ta ni ẹsan i ṣe?
- Iru ihà wo ni Dafidi kọ si ifororoyàn Saulu?
- Ileri wo ni Dafidi ṣe fun Saulu lẹyin ti wọn ti ba ara wọn lajà?