I Samuẹli 26:1-25; Orin Dafidi 54:1-7

Lesson 215 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Fi ọna rẹ le OLUWA lọwọ; gbẹkẹle e pẹlu; on o si mu u ṣẹ” (Orin Dafidi 37:5).
Cross References

I. Saulu Ba Ibura rè̩ Jẹ

1. Saulu bura niwaju Oluwa pe, oun yoo da ẹmi Dafidi si, I Samuẹli 19:6

2. Saulu ba ibura rè̩ jẹ nigba ti o ju ẹsín naa, I Samuẹli 19:10

3. O tun ba a jẹ nipa diditè̩ si Dafidi, I Samuẹli 22:7, 8

4. O ba a jẹ nipa lilepa Dafidi ni Maoni, I Samuẹli 23:25, 26

5. O ba a jẹ nigba ti o n dọdẹ Dafidi ni Engedi,I Samuẹli 24:1, 2

6. O tun ba a jẹ nigba ikẹyin ni Sifi, I Samuẹli 26:1, 2; fi wé I Samuẹli 24:20-22; Orin Dafidi 54:1-7

II. Lilọ Dafidi sinu Agọ Saulu

1. Awọn amí Dafidi fi idi ọrọ mulẹ pe, ni tootọ ni Saulu tun wa lati pa Dafidi run, I Samuẹli 26:3, 4

2. Dafidi wadi iroyin awọn ami naa wo, I Samuẹli 26:5

3. Abiṣai yọọda lati ba Dafidi lọ si ibudo Saulu, I Samuẹli 26:6, 7

4. Abiṣai fi itara bẹbẹ pe ki a pa Saulu run, I Samuẹli 26:8

5. Iwa-bi-Ọlọrun Dafidi fara hàn ninu idahun rè̩ si Abiṣai, I Samuẹli 26:9-11; Orin Dafidi 37:5; 27:14

6. Ọlọrun ran oorun ijikà si awọn ọkunrin Saulu ki O le pa Dafidi mọ, I Samuẹli 26:12; Orin Dafidi 76:5, 6; Romu 11:8

III. Dafidi ba Abneri ati Saulu Sọrọ

1. Dafidi kẹgàn Abneri, olori-ogun Saulu, I Samuẹli 26:13-16

2. Dafidi fi ọrọ rè̩ siwaju Saulu, I Samuẹli 26:17-20

3. Saulu jẹwọ aṣiṣe rè̩ gbogbo, I Samuẹli 26:21, 25

4. Dafidi fi ara rè̩ si abẹ aabo Ọlọrun, I Samuẹli 26:22-24

Notes
ÀLÀYÉ

Awọn Ẹni Iwa-bi-Ọlọrun ati awọn Oninunibini awọn Ẹni Iwa-bi-Ọlọrun

Ninu awọn ẹkọ wa ti o kọja, a ti ri ohun pupọ ti o fi iwa-bi-Ọlọrun Dafidi, ọba Israẹli ti a ṣẹṣẹ fi ami-ororo yàn hàn; bakan naa ni a si ti ri awọn ohun ti o fi iwa aiṣootọ Saulu, ọba Israẹli hàn. Awọn iṣẹlẹ ti ẹkọ wa yii fara jọ ti ẹkọ ti a ṣe kọja, ṣugbọn wọn ṣe iyebiye fun wa lọna pataki nitori ti wọn fun wa ni anfaani lati kiyesi awọn iwa-bi-Ọlọrun miiran gbogbo ti Dafidi ni, ati lati tun ri aiwa-bi-Ọlọrun Saulu, ki a ba le fi ọran wọn ṣe arikọgbọn.

Lai si ariyanjiyan, Dafidi jẹ ọkan ninu awọn “awọsanma ti o kun fun ẹlẹri” ti o jẹri si agbara igbagbọ ati ipese Ọlọrun fun awọn ọmọ Rè̩. Lọna miiran ẹwè̩, lai si aniani, Saulu jẹ apẹẹrẹ kan ninu Bibeli lati fi idi otitọ yii mulẹ pe eniyan le ri awọn ọtọtọ ẹbun ọrun gba, ṣugbọn lẹyin eyi ki o kọ Ọlọrun silẹ, ki o si pada di ẹni ibajẹ patapata, asẹyinwa-asẹyinbọ ki Ọlọrun wa kọ ọ silẹ lai si ireti miiran jù pe ki o fi ọrun apaadi ti ko lopin ṣe ibugbe.

Nigba ti a tun bojuwò è̩yìn lati ṣe ayẹwo itan ti a ti kẹkọ nipa rè̩ lati ibẹrẹ, a ri i pe Jonatani ọmọ Saulu mu ki baba rè̩ bura niwaju Oluwa pe oun ki yoo pa Dafidi. S̩ugbọn o fẹrẹ ma i tii bura tan ti o fi ju ẹṣín si Dafidi lati pa a ni ẹsẹkẹsẹ. Saulu ko tọrọ idariji fun iwa ti o hu yii, bẹẹ ni ko bẹ Ọlọrun pe ki O ran oun lọwọ lati le mu ileri ti o ti ṣe ṣẹ, ṣugbọn lera lera ni o n da è̩jé̩ ti o ti jé̩ bi o tilẹ jẹ pe o ri ikilọ gba, a si ran an leti iwa buburu rè̩ ati iwa otitọ Dafidi nibi iho ti o wa ni aginju Engedi. Ẹkọ yii n fi ye ni pe eyi ni igba karun ti akọsilẹ fi hàn pe Saulu da è̩jé̩ rè̩; ati pe niwọn bi oye wa ti mọ, eyi ni igba ikẹyin ti o foju kan Dafidi tabi ti o ba a sọrọ.

A ko le sọ pe ohun ti o ṣẹlẹ ninu ẹkọ wa yii kan ṣeeṣi ni. Ohun ti o ṣẹlẹ ni, kò ṣeeṣi rara. Eyi tun jẹ igba kan sii ti ifẹ Ọlọrun n rọ ọkàn Saulu oniwakiwa lati mu un wá si ironupiwada. Saulu gba ẹbi rè̩, ṣugbọn ko ronupiwada. Ko beere fun idariji ti Ọlọrun ṣetan lati fi fun un.

Ọpọlọpọ eniyan ni wọn maa n sọ ohun nla nla ati ọrọ didun-didun, ti wọn si maa n jẹ è̩jé̩ ti o le ṣilẹkun aanu Ọlọrun, ṣugbọn ti wọn ko ni ayọ igbala tabi ẹri pe a dari è̩ṣẹ wọn ji. Saulu jẹ apẹẹrẹ iru awọn eniyan bẹẹ. Ẹnu ara Saulu ni o fi jẹjé̩ pe oun ko ni pa Dafidi, ṣugbọn ipaniyan wà ni ipamọ ninu ookan-ayà rẹ ni gbogbo igba yii.

Nigba ti Ẹmi Ọlọrun ba fi eniyan silẹ, ẹmi eṣu yoo wọ inu rè̩ dipo. Ni ọran dandan gbọn, Dafidi maa n kiyesara lati rii pe oun fi ara oun si ipo ọwọ niwaju Ọlọrun ki oun ba le gbọ ohùn Ọlọrun. Dafidi ko fẹ ki oju rere Ọlọrun fi oun silẹ rara. O fi gbogbo ọran rè̩ le Ọlọrun lọwọ, a si maa fara da ohunkohun ti o wu ki o de lai kùn. Yatọ si eyi, Saulu ko naani ohùn Ọlọrun, ṣugbọn o tẹra mọ ọna ara rè̩ lati maa tẹ ifẹ ọkàn ara rè̩ lọrùn. Ọna rè̩ mú iparun ba a patapata; ṣugbọn iwa Dafidi lati maa tẹle Ọlọrun fun un ni iṣẹgun ainipẹkun ati ologo.

O hàn gbangba pe ki i ṣe ọpọlọpọ ninu awọn Ọmọ Israẹli ni o ba Saulu gbogun ti Dafidi. Wọn gbọran si ọba wọn gẹgẹ bi wọn ti ni lati ṣe; ṣugbọn ọpọlọpọ ni kò ni jẹ ran an lọwọ to gẹgẹ bi o ti n reti, nitori Saulu sọ pe o ni lati jẹ pe wọn ti dimọ pọ pẹlu Dafidi. Ẹmi ibi ko gbé awọn Ọmọ Israẹli wọ patapata bi ti Saulu. Nigba ti Saulu paṣẹ fun awọn iranṣẹ rè̩ lati pa awọn alufa Oluwa nitori pe awọn alufa ṣe iranlọwọ fun Dafidi lati sa asala, awọn iranṣẹ rè̩ kọ. Ẹrù ati gbe ọwọ wọn soke si awọn alufa Oluwa ba wọn jù ohun ti yoo ṣẹlẹ lọ nitori aigbọran ti wọn ṣe si ọba wọn. Saulu ni lati ke si ara Edomu kan, ẹni ti ki i ṣe ọkan ninu awọn ẹni ti Ọlọrun pè lati fi ṣe ayanfẹ Rè̩, lati mu aṣẹ rè̩ pe ki a pa awọn alufa Ọlọrun ṣẹ.

Yatọ si eyi , Dafidi ni awọn diẹ pẹlu rè̩ ti wọn mọ pe, ẹmi otitọ wà ninu alakoso wọn, ti wọn gbọran si i patapata, bi aṣẹ rè̩ tilẹ lodi si ifẹ inu wọn. Wọn ṣe tan lati fori la iku nitori alakoso wọn, ki wọn si gbọran si i patapata nigba ti wọn ba wa lẹnu iṣẹ yii. Iṣoro pupọ ni wọn la kọja nitori ọrọ Dafidi ti wọn ri pe i ṣe ẹtọ. Wọn ṣe eyi nitori ti wọn mọ pe ẹmi otitọ wà ninu Dafidi.

Abiṣai jẹ ọkan ninu awọn ti o sin Dafidi tọkan-tọkan. O fi tifẹtifé̩ yọọda ara rè̩ lati ba Dafidi lọ si ajo kan ti o lewu si ibudo awọn ọta, ki Dafidi le rii gbangba pe Saulu wa nibẹ lati dọdẹ ati lati pa oun. S̩ugbọn igbọran ati ijolootọ Abiṣai si alakoso rè̩ tayọ ọkan akin rè̩. O ṣiro rè̩ pe bi wọn ti ni anfaani lati wọ aarin ibudo Saulu jé̩ apẹẹrẹ ifẹ Ọlọrun, nitori pe Ọlọrun ni O fi oorun ijikà kùn Saulu ati awọn oluṣọ ti n ṣọ ọ. Loju Abiṣai, o dabi ẹni pe Ọlọrun ti fi Saulu le wọn lọwọ, ko tilẹ tọ ki Dafidi gbe ọwọ lati gbeja ara rè̩. Ẹẹkan ṣoṣo ni Abiṣai yoo pari Saulu, ẹni ti Ọlọrun ti kọ! Gbogbo wahala wọn yoo dopin lẹsẹkẹsẹ! Abiṣai yoo tilẹ fogo fun Ọlọrun pe, Oun ni O gba wọn silẹ.

Ninu gbogbo nnkan wọnyi, ki i ṣe pe a ri Abiṣai olootọ, bi ẹni ti n lepa ẹtọ nikan, ṣugbọn a ri iwa-bi-Ọlọrun ati iwa irẹlẹ Dafidi. Lati igba ewe Dafidi ni o ti mọ nipa ogun jijà. Awọn ẹgbọn rè̩ tilẹ wa ninu ẹgbẹ ọmọ-ogun labẹ akoso Saulu. O ti bẹrẹ igbesi-aye rè̩ bi i olutọju awọn agutan baba rè̩, o si di ẹni ti gbogbo orilẹ-ède mọ nipa ijà ti o ba Goliati jà, o si ti ko awọn ọmọ-ogun Israẹli lọ soju ija ninu ogun pupọ labẹ akoso Saulu. Ni akoko ti a le e lugbẹ, o ti kó awọn ẹgbẹ jagunjagun lọ ba awọn ọta Israẹli jà nigba pupọ. Sibẹsibẹ, Dafidi sun mọ Ọlọrun to bẹẹ ti igboke-gbodò ki a maa ṣigun kiri pẹlu gbogbo iṣoro ti lile-lugbẹ kó ba a kò mú ki ọkàn rẹ sele. O ni ọkàn titẹ, ko si jẹ ki itara ti ara ti o le gbera sọ lookan-ayà rè̩ lai ro tẹlẹ nitori iru ẹkọ ti o ni nigba ewe rè̩, tabi nitori iṣoro ti o ti ni tẹlẹ di i leti si ohùn Ọlọrun.

Iru iwa rere bayii ninu Dafidi fi hàn wa pe ko si ohunkohun ni ayika wa tabi ninu iriri wa ti o yẹ ki o lagbara lati mu wa ṣe ibi bi a ba jẹ le feti si ohun Ọlọrun. Eniyan ko pẹ ri awawi ṣe lati fi hàn pe ẹkọ ti wọn ti gba, tabi iwa ajogunba, tabi ailẹkọ giga, aini iriri tabi ohun ti o yi wọn ka gbogbo ni ko jẹ ki wọn le ṣe rere. S̩ugbọn Ẹmi Ọlọrun yoo maa dari awọn ti o ba fẹ gba itọni. A ko ni lati tẹle ero ti ara wa; Ọlọrun ni a ni lati tẹle.

Jijiya fun Kristi

Ohun ti o le ti Onigbagbọ ni lati ba pade ni awọn ẹsùn ti a n fi sùn un, bi o tilẹ jẹ pe oun ni o jẹbi ti awọn ẹsùn naa si fẹsẹ mulẹ ni gbogbo ọna. Boya o jẹbi tabi o jàre, ohun ti ara yoo kọ gbe dide ni pe ki o gbeja ara rè̩. Nigba pupọ, ohun kin-in-ni ti yoo ṣe ni lati ṣe awawi tabi alaye dipo ati jiya fun Kristi gẹgẹ bi Oun ti jiya fun wa nigba ti a ko ri ẹtàn lẹnu Rè̩, bẹẹ ni ko si huwa è̩ṣẹ rara. (Ka I Peteru 2:19-23).

Nigba pupọ, nigba ti ẹni kan ba ṣe aṣiṣe, yoo sọ eredi rẹ ti oun fi ṣe ohun ti o ṣe yi gan an lati da ara rè̩ lare. Oun yoo fẹ di ẹbi naa lori eredi ti oun fi ṣe e kaka ki o gba ẹbi rè̩. Bi oluwarè̩ ko ba si jẹbi ẹsùn ti a fi kan an, o ṣoro fun un lati dakẹ lai wa ọna lati da ara rẹ lare lẹsẹkẹsẹ. O ṣoro fun ọpọlọpọ eniyan lati jẹ ki Ọlọrun fi àre wọn hàn ki O si gbeja wọn, ṣugbọn eyi ni o yẹ ki wọn ṣe bi wọn ba fẹ tọ ipasẹ Olugbala wọn.

A ti le Dafidi lugbẹ lai nidi, ko si ni anfaani lati de ibi isin Ọlọrun. A ti le e – lai nidi – kuro nile, kuro lọdọ awọn olufẹ rè̩ lai ni anfaani mọ lati maa ba awọn Ọmọ Israẹli iyoku lọ si Ile Ọlọrun lẹẹmẹta lọdun, lati mu Ofin Ọlọrun ṣẹ. O le rò pe Ọlọrun ko gbọ adura oun, ati pe, Ọlọrun ti kọ oun silẹ, ati pe, awọn eniyan kò tilẹ ni ifẹ si oun mọ -- lai nidi.

S̩ugbọn eyi ko mu ki Dafidi sọ ireti nu tabi ki o ni ikánnu. O mura tan lati jẹ ki Ọlọrun mu ifẹ Rè̩ ṣẹ. Dafidi ṣetan lati tọ ọna ti Ọlọrun la silẹ, ati lati fara dà ohunkohun ti Ọlọrun ba gba laye lati de ba a, o si ṣetan lati jẹ ki Ọlọrun da oun lare. A le rii ni opin gbogbo rè̩ bi Ọlọrun ti ṣe daabo bò ọmọ Rè̩ ti o gbẹkẹle E, bi Ọlọrun ṣe gbeja ẹni ti ko jẹ gbe ọwọ rè̩ soke lati gbeja ara rè̩, ati bi Ọlọrun ti fi idi ijọba naa mulẹ laelae ni orukọ ẹni ti ọkàn rè̩ pe si I.

Dafidi bu ọlá fun Ọlọrun ati fun ẹni ami-ororo Ọlọrun; nitori eyi, Dafidi jẹ ẹni kan ti Ọlọrun le fi ọkàn tan ni fifi iṣẹ pataki le e lọwọ, ki a si fi i si ayè ti yoo fun un ni ere ayeraye.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Niwaju ta ni ati ta ni o daba pe ki Saulu bura pe oun ki yoo pa Dafidi?
  2. O ha pa ibura rè̩ mọ? Sọ awọn igba ti o pa a mọ tabi ti ko pa a mọ.
  3. Psalmu pataki wo ni Dafidi kọ ni akoko iṣoro yii?
  4. Otitọ pataki ti o duro lori Bibeli wo ni a ri kọ ninu apẹẹrẹ Dafidi ni kikọ ọpọlọpọ Psalmu ni akoko idanwo kikoro rè̩?
  5. Sọ itàn igba ikẹyin ti Dafidi ba Saulu pade.
  6. Ki ni awọn iwa-bi-Ọlọrun ti o fi ara hàn ninu iṣesi Abiṣai?
  7. Ki ni jijẹ ọmọ-lẹyin Jesu yoo gbà wa?
  8. Lọna wo ni Dafidi fi gbeja ara rè̩?
  9. Ki ni Saulu fi gbeja ara rè̩?
  10. Onigbagbọ ha ni lati ri inunibini? Ki ni ihà ti wọn ni lati kọ si inunibini ati awọn ti o n ṣe e?