I Samuẹli 28:3-25

Lesson 216 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Si ofin ati si ẹri: bi nwọn kò ba sọ gẹgẹ bi ọrọ yi, nitoriti kò si imọlẹ ninu wọn ni” (Isaiah 8:20).
Cross References

I. Ipo Ainireti Saulu ti a Kọ

1. Samuẹli, Woli Ọlọrun, alabarò Saulu ti kú, I Samuẹli 28:3; 25:1; 9:27

2. Awọn Filistini tun gbara jọ lati gbogun ti Israẹli, I Samuẹli 28:4

3. Ibẹru ni ipilẹṣẹ ẹsan ti a ran si Saulu, nitori kikọ Ọlọrun silẹ ati nitori aigbọran rè̩, I Samuẹli 28:5; 13:13; 15:26-29

4. Saulu kò le gbọ esi lati ọdọ Ọlọrun, I Samuẹli 28:6

II. Saulu Lọ sọdọ Ajẹ Endori

1. Ofin Ọlọrun ti o lodi si awọn ajẹ ati oṣo hàn gbangba, Ẹksodu 22:18; Lefitiku 19:31; 20:27;Deuteronomi 18:9-12; Isaiah 8:19, 20

2. Ni atetekọṣe, Saulu ti mu iduro rè̩ nipa titako iṣe-ajẹ, I Samuẹli 28:3, 9

3. Ni wiwa ajẹ kiri, Saulu mọọmọ tun pada di alarekọja ofin Ọlọrun, I Samuẹli 28:7-10; 15:23

III. Ifarahàn Samuẹli, Eniyan Ọlọrun

1. Ajẹ naa gba lati lo agbara ẹmi eṣu rè̩, o si gbọ ohun ti Saulu n fẹ lọwọ Samuẹli, I Samuẹli 28:11

2. Iyalẹnu obinrin yii nigba ti Samuẹli fara hàn, fi hàn gbangba pe Samuẹli kò ti ipa agbara ajẹ naa wa, tabi nitori pe ajẹ naa pe e, I Samuẹli 28:12; Esekiẹli 14:7, 8

3. Saulu mọ Samuẹli nigba ti ajẹ naa ṣe apejuwe rè̩, I Samuẹli 28:13, 14

4. Saulu gbiyanju lati bu ọla fun Samuẹli gẹgẹ bi ti atẹyinwa, I Samuẹli 28:14; 13:10; 15:13

IV. Iṣẹ ti Ọlọrun Ran Lati Ẹnu Samuẹli

1. Saulu n fẹ igbimọ ati imọràn, niwọn igba ti Ọlọrun kò tun gbọ adura rè̩ mọ, I Samuẹli 28:15

2. Ki i ṣe iṣẹ titun miiran ni Samuẹli jẹ fun Saulu, tabi gẹgẹ bi ifẹ inu rè̩, ṣugbọn asọtunsọ ibawi ti iṣaaju ni, I Samuẹli28:16-18; 13:13, 14; 15:26-29

3. A sọ fun Saulu pe oun ati awọn ọmọ rè̩ yoo kú ni ọjọ keji, ati pe a o ṣẹgun Israẹli, I Samuẹli 28:19

4. Saulu, ayanfẹ Ọlọrun latẹyinwa ṣubu lulẹ lai nireti, ṣugbọn sibẹ o mọọmọ ṣe aironupiwada, I Samuẹli 28:20-25.

Notes
ÀLÀYÉ

Ipo Ainireti Ẹni ti o Lọ Kuro ninu Igbagbọ

Itàn igbesi-ayé Saulu, ọba kin-in-ni ni Israẹli, jẹ itàn igbesi-ayé ẹni ti ko duro si oju kan ninu erò tabi iwà ayé rè̩. Nigba miiran o buru jai, nigba miiran ẹwè̩, ọkàn rè̩ rọ; Saulu a maa ṣaanu ti ko lẹsẹ nilẹ fun awọn ọta rè̩, a si maa lepa awọn ọrẹ-iyọrẹ rè̩ pẹlu ibinu ẹlẹmi eṣu. Lakọkọ o jẹ onirẹlè̩ iranṣẹ Ọlọrun, ṣugbọn lai pẹ jọjọ o di olori-kunkun, ọlọtè̩ ati ajọ-ara-rè̩-loju. Ni ibẹrẹ ipe rè̩ o feti si ohùn Ọlọrun kinnikinni, ṣugbọn gẹrẹ ti o ti gun ori oye ni o ti bẹrẹ si ṣọtẹ si Ọlọrun lọna ti o fẹrẹ má si iru rè̩ mọ, titi Ọlọrun ati eniyan fi kọ ọ silẹ nikẹyin.

Eṣu, atan-ni-jẹ ni ti mu awọn ẹsẹ Bibeli kan ti n kọ ni ni awọn otitọ pataki kan, o si lọ wọn pẹlu ọgbọn ẹwẹ ati arekereke, o si mu ki awọn ti kò ni ifẹ si otitọ ro wi pe idakeji ẹkọ ti a n kọ ni ni otitọ. Awọn kan n kọ ni pe awọn ẹsẹ ọrọ Ọlọrun ti a yàn fun ẹkọ yii n kọ ni pe o ṣe e ṣe lati maa ba awọn ti o ti kú lò; ṣugbọn a le rii gbangba kedere nigba ti a ba fi ọkàn balẹ ṣe ayẹwò ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun wọnyi wi pe eyi ko ri bẹẹ rara. Ẹri ti o to wà ninu iṣẹlẹ kan ṣoṣo yii lati jadi gbogbo ẹkọ-kẹkọ lori ọran yii patapata.

Saulu sún kan ogiri. Awọn ọta Israẹli n gbogun kikan-kikan. Saulu ko ni alabarò, yala Ọlọrun tabi eniyan lati fun un ni itọni. Ohun gbogbo dabi ẹni pe o dakẹ kesekese, afi otitọ kan yi pe Ọlọrun ti kọ ọ silẹ ni o n dún leti rè̩ bi agogo. Awọn ohun ti o le fun wa ni igboya lati sọ pe Ọlọrun ko kọ ọ silẹ patapata, ni bi Ọlọrun ti ṣe dide tikara Rè̩ lati sọ opin Saulu, ati pe Ọlọrun ko jẹ ki eṣu para da lati fi ara rè̩ hàn gẹgẹ bi Samuẹli, lati le fi ẹsẹ ajẹ ni mulẹ pe oun lagbara giga kan.

Nisisiyi, a rii pe ọba Israẹli, ẹni ti o ti ga nigba kan to bẹẹ ti ori ati ejika rè̩ tayọ gbogbo Israẹli ti fi itiju para dà ki ẹnikẹni ma ba mọ ọn, ẹrẹkẹ rè̩ ti papó, oju rè̩ si ti jin sinu, ebi ati wahala ti mu ki aarè̩ mu un, nisisiyi o wá beere lọdọ ajẹ. Ibajẹ ti ba a gidigidi nipa ti ẹmi to bẹẹ ti o fi gbagbọ pe ajẹ le pe Samuẹli jade lati ipo-oku. O ti rin jinna to bẹẹ ti kò mọ pe ohunkohun ti o wu ki awọn iranṣẹ Satani yii fi agbara ti o ga jù ti ẹda ṣe jẹ agbara lati ọdọ eṣu tabi ki o jẹ ẹtàn.

Ohun rere kan kò le ti inu ohun ti ipilẹ rẹ i ṣe ibi jade wa. Baba eké kò jẹ sọ otitọ laelae, a fi bi o ba le fi i boju lati mu ki o ṣe e ṣe lati gba ẹtàn lile. Nihin yii, kò si iyemeji pe eṣu fẹ gbe ẹtàn kan kalẹ gẹgẹ bi apẹẹrẹ ti awọn eniyan yoo maa tọka si, eyi ti yoo ṣe ikú pa ọpọlọpọ eniyan lọjọ iwaju, ṣugbọn Ọlọrun Olodumare da a lọwọ kọ ninu iṣẹ ibi yii. Awọn ti wọn kò fẹ otitọ le yàn lati maa yi ohun ti o ṣẹlẹ yi po lati fi idi è̩tan wọn mulẹ, ṣugbọn awọn ti o fẹ Ọlọrun ati otitọ Rè̩ ri i pe gbogbo aṣiiri eṣu ni o tú nihin patapata.

Ikọsilẹ Patapata ati Idahun Ọlọrun

Saulu ni lati rin ibusọ mẹwa laarin awọn ọta, ni pipa ara rẹ dà ti ẹnikẹni ki yoo fi le mọ ọn ki o to de Endori. Lẹyin ti o wá obirin naa ri, o ni lati rọ ọ lati ru ofin Ọlọrun, ki i si ṣe bẹẹ nikan, ati ofin ti rè̩ pẹlu ti o ti fi lelẹ pe gbogbo awọn ti o ba ru ofin Ọlọrun yii ni a o jẹ niya. Ni ṣiṣe eyi, o ru ofin Ọlọrun ati ti oun tikara rè̩. O mọọmọ ṣe bẹẹ ni nitori bi obirin yii ti n kọ ni Saulu n fi idi ti kò fi ni lati kọ ye e, o si fi obinrin yii lọkàn balẹ pe ohunkohun ki yoo ṣe e bi o ba gbọ ti oun. O mọ pe ohun ti oun n ṣe kò tọnà nitori ti obinrin yii ran an leti, ṣugbọn o mọọmọ takú lati mu ifẹ inu rè̩ ṣẹ. O mọ pe ọna ti oun ni o wà ni iṣọtẹ si Ọlọrun patapata, ṣugbọn o tẹle ọna ara rè̩ pẹlu ipinnu ti kò yi pada. O ti mura tan lati ṣe ibi.

Kò si ohun ti o ya ajẹ naa lẹnu tabi ti o daya fo o ninu ibeere rè̩. S̩ugbọn ohun ti o ri gẹrẹ lẹyin ibeere yii da a niji, o si ya a lẹnu gidigidi. Eyi jẹ ẹri ti o daju lati fi hàn pe kò lọwọ ninu iṣẹlẹ ti o ṣẹlẹ lẹsẹkẹsẹ gẹrẹ lẹyin ti Saulu sọ pe oun fẹ ba Samuẹli sọrọ.

Ajẹ Endori, nipa agbara afọṣẹ ti eṣu fi fun un le ba awọn ẹmi lò, de àyè kan ṣugbọn ni akoko yii, Ọlọrun jẹ ki o riran tayọ ibi ti agbara rè̩ mọ nitori pe ẹnu ya a gidigidi nigba ti o ri i ti “ọlọrun kan nṣẹ ti ilẹ wa.” Eyi yatọ si ilana ti o ṣe silẹ. Ki i ṣe ohun ti o n reti ni o ri. Kò ti i ni anfaani lati lo ẹmi afọṣẹ rè̩ rara, bẹẹ ni akoko kunà fun un lati lo ẹtàn rè̩ tabi ki o mu agbara Satani ti o gbe wọ lo. Ki i ṣe oun ni o pe ẹni ti o ri jade. Iran ti o tobi jọjọ ni eyi jẹ, o si yatọ si ohunkohun ti o wu ki o ti ri tẹlẹ ri. Eredi rè̩ ni pe Ẹni ti o lagbara jù oun ati eṣu oluwa rè̩ ni o ṣe eyi.

Bi a ti n ṣe ayẹwo iṣẹlẹ ti o buru yii, a le ri i pe Ọlọrun ṣiṣẹ lọna àrà nitori ti iṣẹlẹ yii ki i ṣe ohun ti o maa n ṣẹlẹ bẹẹ rara. Saulu jẹ abami eniyan, abami ọba ti akoko ti rè̩ ṣe pataki ninu itàn iran orilẹ-ède ti oun tikara rè̩ ta gbogbo orilẹ-ède aye yọ.

Ohun ti o ti ṣẹlẹ ri, ofin tabi aṣa, kò ka Ọlọrun lọwọ kò. Bi Ọlọrun ba fẹ gba ọna bayi, O le pa gbogbo ọna ati eto nipasẹ eyi ti Oun ti maa n gba ṣiṣẹ tẹlẹ tì. S̩ugbọn eyi ko fi hàn wi pe O n gbe ọna miiran kalẹ lati maa tẹle. Bi Ọlọrun ba yàn lati gbe Samuẹli dide lati inu okú lati sọ igbẹyin buburu ti yoo jẹ ti Saulu apẹyinda-kuro-ninu-Igbagbọ, O le ṣe bẹẹ lai fi i lelẹ fun ni bi aṣa pe ẹnikẹni le maa pe òkú jade lati inu iboji wọn. Nitori pe O ṣe e lẹẹkan kò fi hàn pe Oun yoo tun ṣe ohun kan naa ni ọjọ iwaju. Ọlọrun ṣe ofin fun eniyan, ki i ṣe fun ara Rè̩. O n ṣe eyi ti o wu U ninu ọgbọn ati agbara Rè̩. A kò ṣì sọ rara lati sọ pe Ọlọrun gbe Samuẹli dide lati inu ipo-okú -- ati pe O dide lati ṣe eyi ti o tọ ninu ọran yii, O pa ajẹ yii tì, ati lọna kan ẹwè̩, O pa Saulu tì – nitori idi kan ati lati mu awọn ipinnu ti Rè̩ ṣẹ.

Saulu beere imọran. O beere fun itọni pẹlu. S̩ugbọn ko ri eyikeyi gba ninu mejeeji wọnyi. A ko ni akọsilẹ pe o foju ri Samuẹli. Apejuwe ti ajẹ yii ṣe to fun un lati mọ pe Samuẹli wà nibẹ, ati pe ohùn ti o gbọ jẹ ti Samuẹli. Iwà ajẹ yii fi hàn pe Samuẹli fi ara hàn gan an, ki i ṣe pe obirin yii ni o para da gẹgẹ bi Samuẹli, gẹgẹ bi awọn atannijẹ ẹlẹmi-eṣu wọnyi ti maa n ṣe. Ohun ti o ṣẹlẹ yii ko fi idi aṣiro yii pe eniyan le ri imọran gbà lati ọdọ awọn ti o ti kọja lọ mulẹ nitori pe ninu eyi paapaa ti o ti ọwọ Ọlọrun wa yii, a rii pe ibi ti o n bọ wa ba Saulu ni ihin ti o gbọ lẹẹkan sii, pẹlu idaniloju pe a o mu ibi yii wa sori rè̩. Awọn wọnni ti o ba pa ilana Ọlọrun tì, ti wọn si n wa itura ati itunu ti kò tọ si wọn nipasẹ awọn ẹmi ti o ti kọja lọ, tabi lati ọdọ iranṣẹ eṣu lọna miiran gbogbo ki yoo ri itunu tootọ gbà bi ko ṣe ohùn ti yoo fọ si wọn leti pe, ibi de ba wọn tan. Ọna kan ṣoṣo ni o wà, eyi yii ni ọna ti Ọlọrun!

Iyọrisi Kikọsilẹ

Lai si aniani, eyi jẹ ọkan ninu awọn ẹkọ ti o ba ni ninu jẹ jù lọ ti a le ri ninu Iwe Mimọ. Kò si ohun kan ti o le dùn mọ ẹnikẹni ninu wi pe ọkàn eniyan ti ki i ku n ṣegbe lọ si ọrun aremabọ laelae. Ẹni kan ni yii ti o ti mọ ifẹ Ọlọrun nigba kan ri, ti o si ti tọ ibukun alailẹgbẹ Ọlọrun wò. Nisisiyi, a ri i pẹlu ibanujẹ, lai nireti nitori pe kò ronupiwada kikọ ti o kọ Ọlọrun silẹ, ani a kò tilẹ ri ami ironupiwada diẹ kinun ninu rè̩ ni akoko ti ohun gbogbo ṣoro fun un yii.

Ohun kan ti o ṣi silẹ niwaju Saulu ni ẹnu ọna si ayeraye. Awọn ọrọ ti o tun gbọ pẹlu lẹnu Samuẹli ni eyi pe, “Li ọla ni iwọ ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio pẹlu mi.” Eyi fi hàn pe a kò ni pẹ ke e kuro lori ilẹ alaaye nibi ti ireti gbe wà, yoo si lọ si ibi ti wọn gbe n kú aku-tun-ku, nibi ti ireti kò si mọ. Oun ki yoo wà nibi ayọ ati itura pẹlu Samuẹli, nitori pe a kà nipa ọkunrin ọlọrọ ati Lasaru pe ọgbun nla wà ni aarin okú awọn eniyan buburu ati awọn ti o wà ni ọdọ Oluwa. Ẹ wò bi iyatọ naa ti pọ to laarin ọrọ idalẹbi ti o ti ẹnu Samuẹli jade si Saulu ati ireti ti o wà ninu ọrọ wọnni ti olè ni ti o n kú lọ lori agbelebu gbọ lẹnu Jesu: “Loni ni iwọ o wà pẹlu mi ni Paradise.” Ole nì ronupiwada; ṣugbọn Saulu kò ronupiwada!

Saulu ṣubu lulẹ gbọrangandan lai nireti, pẹlu ibanujẹ ati abamọ. Nikẹyin, a rọ ọ lati dide, o joko lori akete o si jẹ ounjẹ ti a fi ikanju gbọ. Ki i ṣe ifẹ inu rè̩ ni o fi jẹ ounjẹ yii nitori pe ireti rè̩ ti pin, ire ati adùn ti o wà ninu igbesi-ayé ọmọ-eniyan ti fi i silẹ. Ẹ jẹ ki a fi oju inu wo idakẹrọrọ ti o ni lati de ba awọn ti o wà nibẹ. Kò si apará, ifunnu ati igbọnriri ifojusọna ti o maa n mu awọn jagunjagun nigba ti ọjọ ogun ba di ọla. Lai si aniani, pẹlu idakẹrọrọ ni wọn fi jẹun, pẹlu iwuwo ọkàn fun ọrọ idájọ ti wọn gbọ ni alẹ ọjọ ti kò ni igbagbe yii.

Ojumọ mọ. Ẹni ti Ọlọrun yàn fun aye giga -- ẹni ti o ti ni iriri nigba kan pe Ẹmi Ọlọrun ti o mọ ti kò si ni abula wà lara oun, lati gba ẹnu rè̩ sọrọ, lati maa tọ ọ -- bọ sinu okunkun biribiri!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti Ọlọrun kọ Saulu silẹ?
  2. Ta ni alamọran Saulu tẹlẹ ri?
  3. Iṣoro wo ni o de ba Israẹli, ati Saulu alakoso wọn ni akoko yii?
  4. Ta ni awọn alamọran Saulu ni akoko yii?
  5. Ki ni Saulu ṣe ni akoko iṣoro yii?
  6. Ki ni iwà Saulu fi hàn, paapaa jù lọ nipa ipo ti oun paapaa wa nipa ti ẹmi?
  7. Ki ni ofin Ọlọrun nipa awọn abokusọrọ ati àjẹ?
  8. Ihà wo ni Saulu kọ si ofin yii tẹlẹ ri? Iṣe rẹ ha yi pada ni akoko iṣoro bii?
  9. Ẹsẹ ọrọ Ọlọrun ti a yàn fun ẹkọ yii ha kin awọn eke woli lẹyin lati gbe ẹkọ wọn kalẹ bi?
  10. A ha fun Saulu ni imọran ti o beere? Ire wo ni o ri gbà lọna ti o gbà ni akoko yii?