I Samuẹli 27:1, 2; 29:1-11;30:1-25

Lesson 217 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Nitori OLUWA mọ ọna awọn olododo: ṣugbọn ọna awọn enia buburu ni yio ṣegbe” (Orin Dafidi 1:6).
Cross References

I. Dafidi ni Ilẹ awọn Filistini

1. Ibẹru Saulu le Dafidi lọ si ilẹ awọn Filistini nikẹyin, I Samuẹli 27:1, 2; 21:10-15; I Awọn Ọba 19:1-3

2. Ọba Akiṣi fi Dafidi ṣe è̩ṣọ rè̩, ṣugbọn awọn ijoye Filistini korira awọn ọmọ Heberu, I Samuẹli 28:1, 2; 29:1-11

II. Iparun ni Siklagi

1. Awọn ara Amaleki ti kọlu ihà gusu, wọn si ti fi Siklagi jona, I Samuẹli 30:1

2. A ti ko gbogbo awọn eniyan ti o wà ni Siklagi ni igbekun, I Samuẹli 30:2, 3

3. Ẹgbẹ-ogun Dafidi sọkun fun adanù wọn, wọn si gbero lati sọ Dafidi ni okuta, ṣugbọn Dafidi mu ara rè̩ ni ọkàn le ninu Oluwa, I Samuẹli 30:4-6; Orin Dafidi 34:4; 56:2, 3, 11; Romu 8:31; Heberu 13:6

III. Ilepa ati Iṣẹgun

1. Ni idahun si ibeere Dafidi, Ọlọrun fun un laṣẹ lati lepa awọn ọta naa, I Samuẹli 30:7, 8;Orin Dafidi 91:15; Owe 3:5, 6

2. Wọn fi igba eniyan sẹyin ni odo Besori, I Samuẹli 30:9, 10

3. A ri ẹrú awọn ara Egipti kan, ẹni ti o mu ẹgbẹ-ogun Dafidi lọ si agọ awọn ara Amaleki, I Samuẹli 30:11-15

4. Awọn eniyan Amaleki wà ninu irọra, eyi si mu ki Dafidi ati awọn eniyan rè̩ ki o ni iṣẹgun ti o rọrun, I Samuẹli 30:16-19; Daniẹli 5:1-4, 30; Luku 12:19, 20; 17:27-30

IV. Pipin Ikogun

1. Dafidi mu agutan ati malu awọn eniyan Amaleki fun ara rè̩, I Samuẹli 30:20

2. Irinwo ọkunrin ti o ba Dafidi lọ kò fẹ ba awọn igba ọkunrin ti o wà ni ibi-odo pin ikogun, I Samuẹli 30:21, 22;Numeri 31:27

3. Ọrọ ti Dafidi kede di ilana fun gbogbo Israẹli, I Samuẹli 30:23-25;Orin Dafidi 68:12.

Notes
ÀLÀYÉ

Igbà Iṣoro

“Gẹgẹ bi ẹmi rẹ ti tobi loni loju mi, bẹni ki ẹmi mi ki o tobi loju OLUWA, ki o si gbà mi lọwọ ibi gbogbo” (I Samuẹli 26:24). Eyi ni ọrọ ti o kẹyin ti Dafidi ba Saulu sọ, eyi si fi hàn pe Dafidi ti fi ọrọ rè̩ le Oluwa lọwọ patapata, ṣugbọn è̩rù tun wọle. “Njẹ ni ijọ kan l’emi o ti ọwọ Saulu ṣegbe.” Aṣiro ti kò nilaari ni eyi. Ọlọrun ti dide fun iranlọwọ Dafidi nigba pupọ to bẹẹ ti kò fi si ìdí fun un lati bẹrù.

Nigba ti è̩ru ba wọ inu ọkàn, aarè̩ yoo bẹrẹ si mu igbagbọ; nitori pe ifoya ati igbagbọ dabi ọsan ati oru ti o lodi si ara wọn. Nigba ti ilẹ ba mọ, okunkun a para da; ṣugbọn nigba ti imọlẹ ba ká kuro, okunkun yoo ṣu; bayi ni ọran ifoya ati igbagbọ ri. Nigba ti ina igbagbọ ati ifẹ pipe ba n ku ni ibè̩ru maa n mókè. “Ifẹ ti o pé nlé ibẹru jade” (I Johannu 4:18).

Bawo ni o ti rọrun to fun eniyan lati ko agbako lọna ti ẹmi bi a ba fi i silẹ lati tẹle imọ ara rè̩! Kò si ẹri pe Dafidi ke pe Ọlọrun tabi pe o beere imọran lọwọ Rè̩ ki o to lọ si ilẹ Filistini. Iṣoro nlá nlà ni o yọri si.

O dabi ẹni pe Dafidi tẹle ọna ara rè̩, titi o fi ba ara rè̩ ninu wahala ti o yatọ! Akiṣi, ọba Gati, ẹni ti o n daabo bò Dafidi, yàn Dafidi lati jẹ è̩ṣọ rè̩. Lai pẹ jọjọ, awọn Filistini bẹrẹ si mura silẹ lati gbogun ti Israẹli. Akiṣi paṣẹ pe ki Dafidi ati awọn eniyan rè̩ ba awọn Filistini lọ soju ija. Bi Dafidi ba kọ lati ba Israẹli ja, eyi yoo fi hàn pe kò fi imoore hàn fun ọrẹ rè̩, ati pe, arojuṣe ni ijolootọ ti Dafidi ti fi hàn si Akiṣi. Lọna miiran è̩wè̩, bi Dafidi ba bá Filistini lọ gbogun ti Israẹli, yoo jẹ iṣọtẹ si awọn ara ilu rè̩; ki i ṣe bẹẹ nikan, yoo si jasi pe o n ba Ọlọrun jà. O le jẹ pe wahala yi ni o ji Dafidi kuro ninu oorun rè̩ lati lọ gbadura. O ni lati jẹ pe Dafidi gbadura, nitori pe Ọlọrun gba a kuro ninu iṣoro yii lọna àrà.

Ni Ibi ti Kò tọ

“Kìni awọn Heberu yi nṣe nihin yi?” ni ibeere ti awọn ijoye Filistini bi ọba Gati. Dajudaju awọn ọkunrin Israẹli wọnyi ti kọja àyè wọn lati wà ninu ẹgbẹ ọmọ-ogun Filistini. Oye awọn ijoye ṣi kankan lati rii pe ki i ṣe eto ti o bọ sii rara lati gbà wọn mọra, wọn si yi Akiṣi lọkàn pada pe ki o le Dafidi pada. Lai si aniani, Ọlọrun ni o fi si awọn ijoye lọkàn lati ṣe bẹẹ.

Irú ohùn kan naa kọ ni o ha n fọ lati ẹnu awọn ẹni ti aye yii nigba ti Onigbagbọ ba fẹ lati fara mọ ohun aye yii ju bi o ti yẹ lọ? Ọpọlọpọ eniyan ni o n fi oju giga wò Igbagbọ. Nigba ti awọn ẹni aye ba rii ti alafẹnujẹ Onigbagbọ kan ba n fi iwọra lepa aye ati igbadun inu rè̩, n jẹ wọn kò ha le fi gbogbo ẹnu beere wi pe, “Ki ni ọgbẹni yi n fẹ nihinyi?” Nigba ti ẹni kan ba jẹwọ pe ọmọ Ọlọrun ni oun i ṣe, awọn ẹni aye ni ẹtọ lati maa reti pe ki oluwarè̩ maa rin ni ọtun iwà gẹgẹ bi aṣẹ Baba wa ti o wà ni Ọrun. Ọlọrun a maa yi ọkàn ẹni ti o fi tọkantọkan ronupiwada pada, yoo si wẹ ẹ mọ kuro ninu è̩ṣẹ gbogbo, yoo si fun un ni agbara lati maa gbe inu aye yii lai dẹṣẹ. Onigbagbọ tootọ a maa pa ara rè̩ mọ kuro ninu abawọn ayé yi (Jakobu 1:27). “Nitorina ẹ jade kuro larin wọn, ki ẹ si yà ara nyin si ọtọ, li Oluwa wi, ki ẹ máṣe fi ọwọ kàn ohun aimọ; emi o si gbà nyin. Emi o si jẹ Baba fun nyin, ẹnyin o si jẹ ọmọkunrin mi ati ọmọbirin mi, li Oluwa Olodumare wi” (II Kọrinti 6:17, 18).

Imọkanle Dafidi

Nigba ti Dafidi ati awọn ẹlẹgbẹ rè̩ pada si ilu wọn, wọn rii pe awọn ara Amaleki kan ti do ti ilu ihà guusu, wọn si ti dana sun Siklagi raurau. Gbogbo awọn eniyan ti o kù ni ilu nigba ti Dafidi ba awọn Filistini lọ ni a ti kó lẹrú. Ibanujẹ ti o wọ inu awọn ọmọ-ogun ti o le koko wọnyi ko ṣe e fẹnu sọ; nitori ti wọn sọkun “titi agbara kò fi si fun wọn lati sọkun.” Awọn eniyan naa daba lati sọ Dafidi ni okuta pa, boya nitori pe o jẹ ki gbogbo awọn ọkunrin wọnyi fi ilu silẹ lai si oluṣọ ti yoo daabo bo o. Ibanujẹ ati wahala Dafidi pọ si i gidigidi.

“S̩ugbọn Dafidi mu ara rè̩ li ọkàn le ninu OLUWA Ọlọrun rè̩.” Eyi ni ibi kin-in-ni ti a gbe ri akọsilẹ pe Dafidi wa Ọlọrun ni ilẹ awọn Filistini. Ọlọrun wà nitosi lati yọ Dafidi kuro ninu wahala rè̩, paapaa ni ilẹ Keferi yii. “Ẹ sunmọ Ọlọrun, on o si sunmọ nyin” (Jakọbu 4:8). Dafidi sọkun pẹlu awọn eniyan rè̩ nitori iparun Siklagi, ṣugbọn lai si aniani, ki i ṣe ofo ohun ti ara nikan ni o pa Dafidi lẹkun.

Dafidi ni lati ranti ni akoko yii pe igba pupọ ni Ọlọrun ti dide fun iranlọwọ oun ni akoko ewu. Boya o ranti ọjọ ti kiniun ati beari wa ba a ni aarin igbẹ lati ji ninu agbo ẹran baba rè̩, ṣugbọn Ọlọrun ran agbara si i ni ọjọ naa lọhun lati pa awọn ẹranko buburu wọnyi. Iranti Goliati omiran kò ni ṣalai wá si ọkàn Dafidi. O ranti bi Ọlọrun ti fi ẹni ti o kẹgàn Ọlọrun Israẹli le oun lọwọ, nipa bayi ti o mu ẹgàn kuro laarin awọn eniyan Ọlọrun. Boya ẹkun Dafidi jẹ ẹkun ironupiwada fun è̩rù ti o wọ ọkàn rè̩ ṣiwaju akoko yii.

Lootọ Ọlọrun ọdun ti o kọja ni Ọlọrun eyi ti o n bọ wa, nitori naa Dafidi mu ọkàn ara rè̩ le ninu Ọlọrun. Onigbagbọ a maa rii pe ọna ti o yá jù lọ lati gbà jade kuro ninu afonifoji ibè̩ru tabi iyemeji ni lati joko lati ka ibukun wọnni ti Ọlọrun ti tu le e lori.

Ọna Aṣeyọri

Dafidi ti pa ọna ara rè̩ tì. Lati igba yi lọ, Dafidi ṣetan, o si ti pinnu lati gba imọran lati ọdọ Ọlọrun wa. Kò pẹ lẹyin ti Dafidi bẹrẹ si gba imọran lati ọdọ Ọlọrun ti ẹkún rè̩ pada di ayọ. Dafidi pe Abiatari alufa (ẹni ti o ni lati ti wà pẹlu Dafidi ni gbogbo akoko yii), o si beere lọdọ Oluwa. Oluwa paṣẹ fun Dafidi ati awọn eniyan rè̩ lati lepa awọn Amaleki, nitori pe lai si aniani, gbogbo ẹrù wọn ni wọn yoo gbà pada.

Awọn eniyan a maa lepa ọna ara wọn laye yii titi ohun gbogbo yoo fi bọ lọwọ wọn. Nigba ti ohun kan ṣoṣo ti o kù lọwọ wọn ba bọ, nigba yii ni wọn to ṣẹṣẹ ṣetan lati fẹ ke pe Ọlọrun fun iranwọ. Aanu Ọlọrun ni pe O n gbọ adura ni iru akoko bayi, bẹẹ ni Oun a maa gbọ. Ire ti o tobi jù eyi lọ kò ha ni tẹ eniyan lọwọ bi wọn ba jẹ ke pe Ọlọrun lati ibẹrẹ ayé wọn, ki wọn si jẹ ki O maa tọ iṣisẹ kọọkan ti wọn n gbe? “Mọ ọ ni gbogbo ọna rẹ: on o si ma tọ ipa-ọna rẹ” (Owe 3:6). Ma ṣe daba lati tẹle Ọlọrun ninu awọn ohun kan, ki o si tẹ si imọ ara rè̩ lọna iyoku, nitori eyi kò le mu ire wa. Onigbagbọ ni lati fi gbogbo igbesi-aye rè̩ mọ Ọlọrun.

Iṣẹgun fun Dafidi

Iṣẹgun lori awọn Amaleki kò kù si ibi kan. Igba ọkunrin ni wọn fi silẹ sẹyin leti odo Besori, nitori ti aarè̩ mu wọn ti wọn kò fi le re odo kọja, sibẹsibẹ awọn irinwo ọkunrin ti o wà pẹlu Dafidi to lati ja ogun naa ni ajaṣẹ, nipa iranlọwọ Ọlọrun. Wọn ba awọn Amaleki ni ibudo wọn, nibi ti wọn gbe n hó yanmu nidi ikogun ti wọn ko. Wọn ti rò pe awọn wà lai lewu, ṣugbọn egbe ni fun ẹni aye nigba ti o ba n ro pe oun wà lai lewu, ninu ọna rè̩! “Nigba ti nwọn ba nwipe, alafia ati ailewu; nigbana ni iparun ojiji yio de sori wọn” (I Tessalonika 5:3).

Dafidi ati awọn eniyan rè̩ gba aya wọn, awọn ọmọ wọn ati ohun-ini wọn pada, ki i ṣe bẹẹ nikan, wọn gba ọpọ ikogun lọwọ awọn Amaleki, eyi ti awọn paapaa ti kó lati ilu wọnni ti wọn gbogun tì. Ibanujẹ di ẹrin lẹsẹkẹsẹ, ẹkún ati ikaanu di ẹrin ati orin ayọ, nitori ti ẹni kan mu ara rè̩ lọkàn le ninu Oluwa Ọlọrun rè̩. Ohun ti o ṣẹlẹ lẹyin eyi fi hàn pe ki i ṣe gbogbo awọn ọmọ-ogun wọnyi ni o n gbadura.

Nigba ti awọn ẹgbẹ aṣẹgun yi pada de ibi odo nibi ti wọn gbe fi igba (200) ọkunrin silẹ nidi “ẹrù”, awọn irinwo ọmọ-ogun wọnyi pinnu lati da awọn aya ati awọn ọmọ awọn igba ọkunrin wọnyi pada fun wọn lai ni ipin miiran mọ ninu ikogun, lẹyin eyi ki wọn si maa ba ọna wọn lọ. Dafidi kò fara mọ imọran yii. O ṣe ofin ti awọn Ọmọ Israẹli bẹrẹ si tẹle ni gbogbo igbesi-ayé wọn gẹgẹ bi orilẹ-ède. “Bi ipin ẹniti o sọkalẹ lọ si ija ti ri, bḝni ipin ẹniti o duro ti ẹrù; wọn o si pin i bakanna.” Awọn Onigbagbọ si n tẹle ilana yii titi di oni-oloni.

Ki i ṣe gbogbo Onigbagbọ ni a pe lati jade lọ ṣe iṣẹ ẹfangẹlisti, tabi lati di ojiṣẹ Ọlọrun, tabi irú awọn iṣẹ bẹẹ ti yoo gba wọn ni aapọn ninu ọgbà ajara Ọlọrun; ṣugbọn a pè gbogbo awọn Onigbagbọ lati gbadura. Jesu n fẹ awọn afadura-jagun ati awọn ọmọ-ogun fun irú iṣẹ miiran gbogbo bakan naa. Onigbagbọ ti o ba duro laye rè̩ ti o si n gbadura kikan-kikan fun awọn ẹni ti o n ṣiṣẹ ninu ọgba ajara yoo gba ere. “Ẹnikẹni ti o ba fi kiki ago omi tutù fun ọkan ninu awọn onirẹlẹ wọnyi mu nitori orukọ ọmọ-ẹhin, lõtọ ni mo wi fun nyin, ki o padanù ère rè̩” (Matteu 10:42).

Okunkun S̩iwaju Imọlẹ

Akoko ti Dafidi lo ni ilẹ awọn Filistini fẹrẹ jẹ akoko okunkun ti o buru jù lọ ninu gbogbo igbesi-ayé rè̩. Iṣẹ ṣé̩ Dafidi pupọ ni akoko yii, ṣugbọn oun ni o fi ọwọ ara rè̩ fa pupọ ninu wọn. Bi Dafidi ba ti duro nibi ti Ọlọrun fi i si, wahala wọnyi kò ni de ba a. Sibẹsibẹ, Ọlọrun jolootọ, O si ṣaanu fun ẹni ti O ti pe lati jẹ ọba Israẹli. “Nitori ti o mọ ẹda wa; o ranti pe erupẹ ni wa” (Orin Dafidi 103:14).

Oluwa fẹ ki Dafidi pada si ilẹ Israẹli, ki awọn Ọmọ Israẹli baa le fi i jọba lai pẹ. A sun Siklagi, a ko awọn aya Dafidi ati awọn ọmọ rè̩ nigbekun, gbogbo ini rè̩ nipa ti ara si lọ patapata; ṣugbọn akoko ti o korò bi iwọ yii ni o ṣiwaju ọjọ ti o dara jù lọ nigbesi aye Dafidi. Nipa awọn ohun ti o ṣẹlẹ wọnyi, a tun mu Dafidi pada si ibi ti o gbe le gbẹkẹ le Ọlọrun ninu ohun gbogbo ki o tilẹ to ri abayọrisi ohun naa. Ọwọ Ọlọrun lè le nigba miiran, ṣugbọn Ọlọrun mọ ọkàn Oun yoo si ṣe ohun ti o tọ ti o si yẹ lati mu eniyan wá si ibi ti yoo gbe wulo ninu iṣẹ-isin Ọlọrun.

Ọjọ ti a o de awọn aṣẹgun ni kikún lade kù si dè̩dẹ. O dabi ẹni pe Ọlọrun n yọ idarọ kékèké ti o kù kuro lọkàn awọn eniyan mimọ Rè̩, lati pese wọn silẹ fun akoko naa. O le jẹ pe a o dana sun awọn “Siklagi”, tabi ki awọn alumọni aye yii parẹ lojiji. Ohunkohun ti Ọlọrun ba ri ni igbesi-ayé awọn ọmọ Rè̩ ti kò ni mu wọn yẹ fun Ọrun, ni Oun yoo mu kuro, bi wọn ba jẹ gba A laye lati ṣe bẹẹ. Akoko idanwo le nira, ṣugbọn imọlẹ fẹrẹ mọ si awọn ẹni ti o ba ni igbẹkẹle pipe ninu Ọlọrun, ti wọn si la idanwo naa ja. A fi ade ododo lelẹ fun gbogbo awọn ti o fẹ ifarahàn Kristi (II Timoteu 4:8).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti Dafidi ati awọn ẹlẹgbẹ rè̩ sa lọ si ilẹ Filistini?
  2. Njẹ Dafidi beere lọwọ Ọlọrun ki o to lọ?
  3. Ninu iṣoro wo ni Dafidi ati awọn ẹlẹgbẹ rè̩ ba ara wọn?
  4. Bawo ni Dafidi ṣe yọ ninu ipo iṣoro yii?
  5. Ki ni Dafidi ri nigba ti o pada si ilu rè̩?
  6. Ki ni awọn ọmọ-ogun sọ pe wọn yoo ṣe? Ki ni Dafidi ṣe?
  7. Ki ni abayọrisi ogun ti o ba awọn Amaleki ja?
  8. Bawo ni Dafidi ṣe pinnu pe ki wọn maa pin ikogun?