Lesson 218 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Nitoripe, ère ki yio si fun enia ibi; fitila enia buburu li a o pa” (Owe 24:20).Cross References
I. Ikú Saulu
1. A ṣẹgun Israẹli patapata ninu ijà pẹlu awọn Filistini, I Samuẹli 31:1;I Kronika 10:1
2. A pa awọn ọmọ Saulu loju ijà, oun paapaa si gbọgbẹ gidigidi, I Samuẹli 31:2, 3;I Kronika 10:2, 3
3. Saulu pa ara rè̩ ki o le bọ lọwọ awọn ọta rè̩, ẹni ti o ru ihamọra rè̩ si ṣe bẹẹ pẹlu, I Samuẹli 31:4-6;II Samuẹli 17:23; Orin Dafidi 52:1-9; Matteu 27:5; I Kronika 10:4-6
II. Iṣẹgun Awọn Keferi
1. Awọn Filistini fi ayọ iṣẹgun gbe okú Saulu ati ti awọn ọmọ rè̩ lọ ṣe afihàn, I Samuẹli 31:7-10; Awọn Onidajọ 16:23, 24; Mika 1:10; II Samuẹli 1:20; I Kronika 10:8-10
2. Awọn ọkunrin Jabeṣi-Gileadi gbe okú Saulu ati ti awọn ọmọ rè̩ pada, wọn si sin wọn bi o ti tọ, I Samuẹli 31:11-13; II Samuẹli 2:5-8; I Kronika 10:10-12
3. Ogunlọgọ ninu awọn ọmọ Israẹli ni wọn sá kuro ni ile wọn, I Samuẹli 31:7; I Kronika 10:7
III. Ẹkún Dafidi
1. Ara Amaleki kan mu iroyin ikú Saulu wa fun Dafidi, II Samuẹli 1:1-4; I Samuẹli 4:12-18
2. Ọkunrin Amaleki yii ro lati ri ojurere Dafidi nipa mimu iroyin ikú ọta rè̩ wa fun un, II Samuẹli 1:5-10; 4:9-12
3. A pa ara Amaleki naa nipa ọrọ ẹri ẹnu ara rè̩, II Samuẹli 1:11-16; Gẹnẹsisi 9:6; I Awọn Ọba 2:32, 33; Luku 19:22
4. Dafidi pohun-rere ẹkún nitori ikú Saulu ati ti awọn ọmọ rè̩, II Samuẹli 1:17-27; Ẹkún Jeremiah 1:12-17; 4:1-12; Hosea 13:11; I Samuẹli 15:35; 16:1
Notes
ÀLÀYÉÈrè È̩ṣẹ
Ori iwe pupọ ninu Iwe Mimọ ni akọsilẹ igbesi-ayé ati iku Saulu gbà, ki gbogbo ẹni ti o n kà wọn le mọ pe igbẹyin apẹyinda ati ọlọtè̩ si Ọlọrun buru jai.
Nipa ti ara ati ni ti pe Saulu jẹ ogiripa, ohun pupọ ni Saulu ni gẹgẹ bi anfaani. Idi pupọ ni o wà ti a fi le ni ero pe igbesi-ayé Saulu i ba niyelori ki o si wulo lọpọlọpọ fun iṣẹ Ọlọrun, ṣugbọn kò yọrisi bẹẹ rara. Saulu wa di onigberaga ninu ipo oyè ọba ti Ọlọrun fi i si; bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun du u gidigidi lati ba a wi, lati tọ ọ ati lati duro ti i ninu gbogbo wahala rè̩, ṣugbọn Saulu kunà patapata.
Aigbọran aṣe-idabọ Saulu si Ọrọ Ọlọrun mu ki Ọlọrun ja ijọba Israẹli gbà kuro ni ọwọ rè̩ ki O si fi i fun Dafidi. Saulu bẹrẹ si jowu Dafidi kikan-kikan, kaka ki o ronupiwada è̩ṣẹ rè̩ ti o n kó wahala ba a, o jẹ ki è̩ṣẹ sin oun de ibi ti o gbe pa ara rè̩, o si ṣegbe titi laelae.
Saulu wa dabi ẹni ti Jesu sọ nipa rè̩ pe: “Nigbati ẹmi aimọ ba jade kuro lara enia, ama rin kiri ni ibi gbigbẹ, ama wá ibi isimi; nigbati kò ba si ri, a wipe, Emi o pada lọ si ile mi nibiti mo gbé ti jade wá. Nigbati o si de, o bá a, a gbá a, a si ṣe e li ọṣọ. Nigbana li o lọ, o si mu ẹmi meje miran ti o buru jù on tikararè̩ lọ; nwọn wọle, nwọn si joko nibè̩: igbẹhin ọkunrin na si buru jù iṣaju rè̩ lọ” (Luku 11:24-26).
Saulu ti ni iyipada ọkàn gidi tẹlẹ ri; Ọlọrun fun un ni ọkàn titun; nigba ti Ẹmi Ọlọrun si ba le e, o sọ asọtẹlẹ (I Samuẹli 10:9, 10). Laifi eyi pe, è̩ṣẹ wọ inu ọkàn Saulu; nigba ti o si kọ lati ronupiwada awọn aṣiṣe rè̩, o di ohun-elo lọwọ eṣu, “nitori ẹniti o ba ṣẹgun ẹni, on na ni isi sọ ni di ẹrú” (II Peteru 2:19).
Saulu, gẹgẹ bi apẹyinda ati ọlọtè̩ si akoso Ọlọrun di eniyan buburu. Iwà rere ti o yẹ ki a maa ri lọwọ rè̩ lojoojumọ, di ọran ẹẹkọọkan; orikunkun ati igberaga si mu ki o maa ṣe buburu leralera. O wa jingiri sinu iwa buburu rè̩; ati lati ibi owu ti o ni ninu ọkàn rè̩ si Dafidi, è̩ṣẹ rè̩ bẹrẹ si gbeeràn titi o fi bẹrẹ si lepa Dafidi ni gbangba, pẹlu è̩jé̩ lati pa a gẹrẹ ti ọwọ rè̩ ba tẹ ẹ.
Ni igba kan lakoko ijọba Saulu, ibinu fufu bi ibinu apaniyan wọ inu rẹ, nitori pe Dafidi yọ ọ silẹ lọ nipa iranlọwọ Ahimeleki alufa. Saulu pa Ahimeleki ati awọn ara ile rè̩, ati ọpọlọpọ ninu awọn alufa ati awọn ara ilu Nobu, o si fi ina kun ilu naa. Saulu ṣe eyi nitori ọkàn buburu ti o wà ninu rè̩ (I Samuẹli 22:18, 19). Iwa buburu Saulu kò mọ ẹni kan yatọ. Ileri Ọlọrun ni pe: “Temi li ẹsan, emi ó gbẹsan” (Romu 12:19); iṣọtè̩ Saulu, ilepa ikà ti o n lepa Dafidi ati ibinu rè̩ ti kò lẹgbẹ, eyi ti o mu ki o fẹ pa ọmọ oun tikara rè̩, ati pipa ti o si pa awọn alufa Ọlọrun ni Ọlọrun kò gboju fo da, bẹẹ ni Kò ṣalai gbẹsan rè̩.
Opin Ijọba
Ogun ti o bé̩ silẹ laarin Filistini ati Israẹli ni o fa iku Saulu. Awọn Filistini ni ohun-elo ti Ọlọrun yàn, lati mu idajọ Rè̩ ṣẹ lori Saulu.
Saulu gbọgbẹ kikoro lati ọwọ awọn tafatafa Filistini; ki o má baa ṣubu si ọwọ wọn, Saulu bẹ ẹni ti o n ru ihamọra rè̩ lati pa oun. S̩ugbọn o kọ lati ṣe bẹẹ; nitori idi eyi, Saulu gba ida ẹni ti o rù ihamọra rè̩ o si ṣubu le e, o si kú. Ẹni ti o rù ihamọra rè̩ naa tun ṣe bẹẹ gẹgẹ, wọn si fi ọwọ ara wọn pa ara wọn.
Itàn sọ fun ni pẹlu idaniloju pe, Doegi ara Edomu, ti o pa awọn alufa ni Nobu ni ẹni naa ti o n rù ihamọra Saulu. Bi eyi ba ri bẹẹ, idajọ Ọlọrun wa sori awọn mejeeji nitori ti o dabi ẹni pe ida kan naa ti wọn fi pa awọn alufa Ọlọrun ni o pa awọn paapaa. Ọrọ Ọlọrun ni o wi pe, “Ẹnikẹni ti o ba ta è̩jẹ enia silẹ, lati ọwọ enia li a o si ta è̩jẹ rè̩ silẹ” (Gẹnẹsisi 9:6). “Bḝni Saulu kú ninu è̩ṣẹ rè̩ ti o da si OLUWA, nitori ọrọ OLUWA, ti on kò kiyesi, ati pẹlu nitori o lọ bère ọràn lọwọ ajẹ, lati ṣe ibere. Kò si bère lọwọ OLUWA; nitorina li o ṣe pa a, o si yi ijọba na pada sọdọ Dafidi ọmọ Jesse” (I Kronika 10:13, 14).
Filistini Bori
Saulu gàn ọna Oluwa, nitori naa o ku ikú è̩ṣín. Awọn ọta rè̩ fi abuku ti kò ṣe e fẹnu sọ kan an. Awọn Filistini gbé okú rè̩ ati ti awọn ọmọ rè̩, wọn si gbe wọn lọ si ilu Betṣani nibi ti a gbe kan wọn mọ ogiri, ki gbogbo eniyan ba le ri wọn. Iṣẹgun nlá nlà ni fun awọn Filistini, o si jẹ ọkan ninu awọn ijatilẹ ti o buru jù lọ ti o ti i de ba Israẹli titi di igbà naa.
A tú ago ibinu Ọlọrun sori Saulu, o si gbe ikoro ti o wa ninu ago yii mu tan patapata. “Nitoripe li ọwọ OLUWA li ago kan wà, ọti-waini na si pọn: o kún fun àdalu: o si dà jade ninu rè̩; ṣugbọn gè̩dẹgẹdẹ rè̩, gbogbo awọn enia buburu aiye ni yio fun u li afun-mu” (Orin Dafidi 75:8).
Iwa Akin
Saulu kò ṣalai hu iwọn iba iwa rere diẹ nigba ayé rè̩; bi o tilẹ ti kú, a san oore ọkan ninu awọn iwa rere rè̩ fun un. Awọn Ammoni gbogun ti ilu Jabeṣi-Gileadi nigba kan bayi; ijigiri Saulu ni o gbà ẹmi ati ile wọn là (I Samuẹli 11:1-11). Nigba ti wọn gbọ iwa ẹsín ti awọn Filistini hù si oku Saulu ati awọn ọmọ rè̩, awọn ọkunrin wọnyi fi igboya dide lọ si ilu awọn ọta wọn ni oru, wọn si gbe okú wọn bọ. Bayi ni a sin Saulu tẹyẹ-tẹyẹ nitori inu rere kan ti o ti ṣe nigbà ayé rè̩.
Ibanujẹ Dafidi
Suuru atọkanwa ati ẹmi idariji Dafidi nigba ti Saulu n lepa rè̩ kikan fi ẹmi Ihinrere tootọ ti Jesu Kristi hàn; ibanujẹ nlá nlà ni o jẹ fun Dafidi nigba ti o gbọ nipa ikú aipe ọjọ ti Saulu kú. Kò si agalamaṣa ninu ibanujẹ Dafidi, o si ṣọfọ paapaa jù lọ nitori Jonatani, ọkan ninu awọn ọmọ Saulu. Ọrẹ timọtimọ ni Dafidi ati Jonatani ti jẹ, ibanujẹ nlá-nlà ni o si jẹ fun Dafidi lati gbọ ikú ọrẹ rè̩.
Ọlọrun kò ni inu didun si ikú eniyan buburu (Esekiẹli 33:11), bakan naa ni awọn eniyan Ọlọrun kò ni inu didun wi pe ki ọkàn kan ki o ṣegbe laelae. Awọn miiran le maa sọ pe Dafidi jare bi o ba tilẹ ni inu didun wi pe ọta rè̩ kú, ati pe o le gba ijọba wayi lai si idojukọ mọ. S̩ugbọn ẹmi igbẹsan kò si ninu Ihinrere Jesu Kristi rara. “Máṣe yọ nigbati ọta rẹ ba ṣubu, má si ṣe jẹki inu rẹ ki o dùn nigbati o ba kọsè̩” (Owe 24:17).
Dafidi duro de Ọlọrun lati gba a kuro lọwọ ibinu were ti o wa ninu Saulu, Ọlọrun si gba a lai jẹ pe Dafidi tikara rè̩ gbe ọwọ rè̩ soke lati gbeja ara rè̩.
Iyatọ nlá-nlà ti o wa laarin irú ọkàn ti Dafidi ni ati eyi ti ọkunrin ara Amaleki nì ní, nipa eyi ti o wi pe oun ni o fi opin si ẹmi Saulu han kedere nipa idahun Dafidi si iru iroyin bayi. Ọkunrin Amaleki yii rò pe oun yoo ri erè gbà ni pipa Saulu ẹni ti a ti kọ ti, ati pe oun ni o tun mu iroyin naa wa fun Dafidi; ṣugbọn eniyan Ọlọrun ni o n ba lò. Ki i ṣe ẹni ti ọkàn rè̩ kún fun iwa buburu, igbẹsan ati iwa ipá. Ki i ṣe ihin ayọ fun Dafidi wi pe, awọn ọkunrin wọnyi kú, ati pe wọn ti lọ si ọrun egbe, afi Jonatani nikan. Onigbagbọ yoo kuku yàn lati jiya ohun pupọ lọwọ awọn eniyan buburu ju pe ki o ṣe okunfa ki ẹni kan kú sinu è̩ṣẹ lai pe ọjọ.
Ẹni – Ami - Ororo Ọlọrun
Nigba ti ọkunrin Amaleki yii sọ fun Dafidi pe oun ni o gbà ẹmi Saulu, kaka ki o ri oju rere Dafidi, ẹmi ara rè̩ ni o fi di i. Dafidi bi i leere wi pe, “E ti ri ti iwọ kò fi bè̩ru lati nà ọwọ rẹ lati fi pa ẹni-àmi-ororo OLUWA?” o si paṣẹ fun ọkan ninu awọn ọmọdekúnrin lati kọlu u ki o si pa a. Dafidi wi fun un pe, “Ẹjẹ rẹ mbẹ li ori ara rẹ; nitoripe ẹnu ara rẹ li o fi jẹwọ pe, Emi li o pa ẹni-àmi-ororo OLUWA.” Bayii ni ọkunrin ara Amaleki yii kú nitori eke ṣiṣe. (Wo Orin Dafidi 105:14, 15).
Orin Arò
Ibanujẹ Dafidi lori iku Jonatani ọrẹ rè̩ ati iku aipe ọjọ ti Saulu kú wà ni akọsilẹ fun wa ninu orin ọfọ ti Dafidi kọ. A saba maa n pe e ni “Orin Arò.”
Dafidi mọ pe awọn Filistini yoo maa yọ gidigidi nitori iṣẹgun wọn lori Israẹli, ati nitori ikú Saulu. Ọjọ buburu ni o jẹ fun Israẹli. Israẹli ti beere fun ọba, a si ti fi i fun wọn, ṣugbọn è̩ru jè̩jè̩ ni o jẹ fun wọn ki i ṣe ibukun. Ọlọrun jẹ Israẹli niya nitori pe wọn kọ Ọ, (Wo I Samuẹli 8:7). Ọlọrun mu Saulu wa si idajọ nitori iṣọtè̩ ati è̩ṣẹ ti rè̩.
Saulu ti ṣi ayè silẹ fun awọn Keferi lati mu ẹgàn ba orukọ Jehofa, Ọlọrun Israẹli. Eyi le mu ki orin Dafidi ki o ye wa ti o wi pe, “Ẹ máṣe sọ ọ ni Gati, ẹ má si ṣe kokiki rè̩ ni igboro Aṣkeloni; ki awọn ọmọbirin Filistini ki o má ba yọ, ki ọmọbirin awọn alaikọla ki o má ba yọ.” S̩ugbọn pẹlu gbogbo eyi ti Dafidi kò fẹ ki o ṣẹlẹ yii, ni wakati naa gan an ni wọn so oku Saulu rọ ni iso ẹsín ati ẹlẹyà ni igboro Bẹtṣani.
Jẹ ki gbogbo awọn ti o fi ọwọ yẹpẹrẹ mu Ọrọ Ọlọrun, ti wọn kò si naani lati gbe Ọlọrun ga ronu igbẹyin Saulu ọba. “Bi agutan li a ntẹ nwọn si isa-okú: ikú yio jẹun lara wọn; ẹni diduro-ṣinṣin ni yio jọba wọn li owurọ; ẹwà wọn yio si rè̩ kuro, isa-okú si ni ibugbe wọn” (Orin Dafidi 49:14).
Questions
AWỌN IBEERE- Ta ni ṣe okunfa ikú Saulu?
- Ki ni ṣe ti Saulu fi pa ara rè̩?
- Njẹ ẹni ti o ba pa ara rè̩ yoo wọ Ọrun rere?
- Ki ni ṣe ti awọn ara Jabeṣi-Gileadi fi lọ si Betṣani lati lọ gbe oku Saulu ati ti awọn ọmọ rè̩ pada?
- Bawo ni Dafidi ṣe gbọ pe Saulu ti kú?
- Ki ni ṣe ti Dafidi kò fi yọ nipa ikú ọta rè̩?