Matteu 22:15-33, 41-46

Lesson 219 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun” (Matteu 22:21).
Cross References

I. Owo - Ode

1. Awọn Farisi gbiyanju lati ko Jesu sinu wahala nipa ibeere è̩tan, Matteu 22:15-17; Orin Dafidi 2:2;Marku 12:13, 14; Isaiah 29:21

2. Jesu ba awọn Farisi wi fun iwa agabagebe wọn, Matteu 22:18; Luku 10:25; Iṣe Awọn Apọsteli 5:9

3. Jesu fi ọgbọn mu ki awọn Farisi funra wọn dahun ibeere wọn, Matteu 22:19-21; Luku 20:1-8; Johannu 8:5

4. Jesu sọ fun awọn Farisi lati san owo-ode fun ẹni ti owo-ode i ṣe ti rè̩, Matteu 22:21, 22; I Timoteu 1:9; 2:1-3; Romu 13:1-7; Titu 3:1; I Peteru 2:13, 14

II. Awọn Sadusi Onibeere

1. Awọn Sadusi fi ofin Mose kan beere ọrọ ti o dikoko lati fi dẹkun mu Jesu, Matteu 22:23-28; Marku 12:18-23

2. Jesu sọ fun awọn Sadusi pe, wọn kò mọ Iwe Mimọ ati agbara Ọlọrun, Matteu 22:29; Efesu 4:18; I Peteru 2:15; II Peteru 3:5

3. Jesu dahun ibeere awọn Sadusi nipa igbeyawo, Matteu 22:30; I Johannu 3:2; I Kọrinti 7:29-31

4. Jesu sọ fun awọn Sadusi pe, Ọlọrun ki i ṣe Ọlọrun awọn okú bi ko ṣe Ọlọrun awọn alaaye, Matteu 22:31-33; Ẹksodu 3:6, 16; Iṣe Awọn Apọsteli 7:32; Luku 20:37

III. Jesu Bori awọn Oludanwo

1. Jesu beere ibeere kan lọwọ awọn olubeere Rè̩ nipa ipo Kristi gẹgẹ bi Ọmọ Ọlọrun, Matteu 22:41, 42; 14:33; Johannu 1:49

2. Jesu beere lọwọ awọn Farisi ọrọ ti Dafidi sọ nipa Kristi, Matteu 22:43-45; Heberu 1:13; Iṣe Awọn Apọsteli 2:34; Heberu 10:12, 13; Orin Dafidi 110:1

3. Kò si ẹni kan ti o tun jẹ beere ọrọ lọwọ Jesu mọ, Matteu 22:46; Jobu 32:15, 16; 40:1-3; Isaiah 50:8.

Notes
ÀLÀYÉ

Lilu Lẹnu Gbọrọ

Awọn Farisi dimọ pọ bi wọn yoo ti ṣe wa ẹsùn si Jesu lẹsẹ, nitori naa wọn bi I lere bi o tọ lati san owo-ode fun Kesari tabi kò tọ. Awọn Farisi rò pe, bi Jesu ba sọ fun wọn pe wọn kò gbọdọ san owo-ode fun Kesari, wọn yoo fi I sùn awọn ara Romu wi pe O fẹ da ọtè̩ ati irukerudo silẹ. Bi O ba si fara mọ ọn pe o tọ ki awọn ara Romu maa gba owo-ode, wọn yoo sọ pe Oun ki i ṣe Messia tootọ. Gẹgẹ bi ero ti wọn, Messia tabi Kristi, Ẹni ti awọn woli sọ nipa Rè̩ ni Ẹni ti yoo mu Israẹli pada si ipo aṣẹgun. Bi Jesu ba fara mọ ijọba Romu, eyi yoo fun awọn Farisi ni anfaani lati wi pe, Jesu kò ni inudidun pe ki Israẹli tun pada di orilẹ-ède nla. Lọna ekinni ati ekeji ni awọn Farisi gbe rò pe wọn yoo gbà ri ohun ti wọn yoo lò lati sùn Un ni ẹsùn eke.

Ogún ti o ti Sọnu

Ibeere ti awọn Farisi mu wa ni ti pe o tọ tabi kò tọ lati san owo-ode fun Kesari kun fun abuku lọpọlọpọ. Wọn jokoo ti eyi pe orilẹ-ède ominira ni Israẹli i ṣe, kò si si labẹ ẹnikẹni bi ko ṣe Ọlọrun. Israẹli n jiya gẹgẹ bi orilẹ-ède ti a ti ṣẹgun rè̩, ṣugbọn sibẹ wọn takú pe kò si ẹni ti o le gba aṣẹ ti wọn ni gẹgẹ bi orilẹ-ède lọwọ wọn bi o ti wù ki orilẹ-ède ajeji ti tè̩ wọn lori ba to.

Israẹli pe ara rẹ ni ominira nipa otitọ yii pe Ọlọrun ti yan an kuro ninu gbogbo eniyan aye lati jẹ ọtọọtọ iṣura fun Un. Nitori naa, wọn wi pe awọn ko jẹ ẹnikẹni ni gbese itẹriba, bi o tilẹ ṣe pe wọn wa ninu itẹriba patapata fun ẹlomiran ti o n ṣe ijọba wọn. Iwa ijọra-ẹni-loju ati igberaga Israẹli, nipa eyi ti wọn ki i bọwọ fun ofin miran, afi ti wọn nikan ṣoṣo, jẹ atako nigba gbogbo si Jesu, oun si ni ipilẹṣẹ awọn iru ibeere bayii ti awọn Farisi beere nipa owo-ode.

Israẹli a maa tẹnu mọ ẹtọ ti wọn ni labẹ majẹmu ti Ọlọrun ba wọn da, ṣugbọn wọn kuna lati mọ pe majẹmu naa ni adehun ninu. Wọn gbagbe pe niwọn bi Ọlọrun ninu ọla-nla Rè̩ ti lagbara lati sọ wọn di orilẹ-ède, awọn ti ki i ṣe orilẹ-ède nigba kan ri, lori adehun yii pe, bi wọn ba jẹ gbọran si aṣẹ Rè̩, bakan naa ni O tun lagbara lati pa ominira wọn rẹ bi wọn kò ba gbọran. Eyi si ti ṣẹlẹ: nitori ti Israẹli kò gba Kristi ni Messia, iwọn iba ominira diẹ ti o kù si wọn lọwọ bọ sọnu. Sibẹ wọn tẹnu mọ awọn aṣayàn ire ati anfaani ti majẹmu Ọlọrun sọ wi pe yoo jẹ ti wọn, ṣugbọn wọn kuna lati ṣe ojuṣe wọn ni jijẹ eniyan ọtọ fun Ọlọrun, eyi ti i ṣe ọna kan ṣoṣo ti ire ati anfaani ti Ọlọrun ti ṣeleri fi le jẹ ti wọn.

Nitori pe awọn Ju taku sinu iwa iṣọtè̩ wọn fun ọpọlọpọ iran-iran, iyè wọn ra, oyé wọn si ṣokunkun to bẹẹ ti wọn kò fi mọ pe awọn kò pa ofin Ọlọrun mọ mọ. Ohun ti wọn kà si ofin Ọlọrun ti o pé ti o si tọnà ti kún fun ọpọlọpọ afikún ofin atọwọdọwọ ọmọ eniyan ati arosọ awọn Farisi (Wo Marku 7:1-13).

Gbogbo akitiyan awọn Ju lati lodi si ijọba Romu dabi ẹni ti ori aake rè̩ ti yọ bọ sinu omi, ti o si n kigbe pe, “Yẽ! Oluwa mi, a tọrọ rè̩ ni” (II Awọn Ọba 6:5). Wọn kò mọ pe a fun wọn ni anfaani ti wọn ni ni, kò si le jẹ ti wọn titi lai jẹ pe wọn gbọran si Ẹni ti o fi i fun wọn.

Wọn Jẹwọ Ohun ti i S̩e Ojuṣe Wọn

Pẹlu irọrun ni Jesu fi sọ ibeere wọn dofo mọ wọn lọwọ nipa bibeere pe akọle tani wa lara owo ti wọn fi n san owo-ode. Lẹsẹkẹsẹ ni wọn dahun pe, “Ti Kesari ni.” O jẹ ilana ni igba ni pe akọle ati aworan ẹni ti o ba wà lara owo ti wọn n na ni alaṣẹ. Nigba ti awọn Farisi gbà bẹẹ lai jiyan, wọn tun gba pe awọn fara mọ akoso naa pẹlu, ati pe awọn ti wà labẹ akoso naa na. Nipa gbigbà pe Kesari ni alakoso wọn, wọn gbà pe, wọn jẹ ajigbese lati san owo wọnni ti i ṣe ẹtọ ijọba lati gbà.

Jesu da wọn lohun pe, “Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun”, eyi si jẹ ibawi ati idahun bakan naa. Wọn gba awọn ara Romu ni alaṣẹ wọn nipa ti ara; eeha si ti ṣe ti wọn kò fi gba akoso Ọlọrun ninu ohun wọnni ti i ṣe ẹtọ Rè̩ lati gbà?

Jesu ba awọn Farisi wi nitori agabagebe wọn lati maa tẹnu mọ ohun ti i ṣe ẹtọ Israẹli labẹ majẹmu niwọn-igba ti wọn ti n sọ ọ nu leralera nipa aigbọran. O si tun ba wọn wi nitori pe wọn n dan An wò, ati pe wọn n yẹ Ẹ lọwọ wò nipa igbọran Rè̩ si Ọlọrun nigba ti awọn paapaa kún fun agabagebe ati è̩ṣẹ. Idahun Rè̩ ṣẹ awọn Farisi lapa patapata, wọn si tuka pẹlu iyalẹnu nipa ọgbọn Jesu.

Ibeere awọn Sadusi

Awọn Sadusi kan tun wa sọdọ Jesu, wọn si mu ibeere tọ Ọ wa, ni ireti lati fi hàn pe ajinde okú kò si. Arosọ ati agalamaṣa ti kò le ṣẹ laelae ni ibeere wọn nipa obinrin ti o ni ọkọ meje leralera duro le lori. Bi ajinde okú ba wà, aya tani yoo jẹ nigba naa? Awọn Sadusi ti ro pe kò si ẹni ti o le dahun ibeere yi, wọn si rò pe nipa bẹẹ, wọn yoo doju ti Jesu ati ẹkọ nipa ajinde.

Jesu sọ fun wọn pe wọn kò mọ Iwe Mimọ ati agbara Ọlọrun. Takọ-tabo ni Ọlọrun da eniyan, ki wọn le maa gbilẹ ati lati ṣe ikawọ ayé (Gẹnẹsisi 1:27, 28). Ki yoo si igbeyawo ni ajinde, ṣugbọn eniyan gbogbo yoo dabi awọn angẹli Ọlọrun.

Ara ati ọkàn awọn eniyan yoo pade, wọn yoo si gbe aikú ati ara ologo wọ. A o di ọmọ ibilẹ ilu ti ẹmi. Awa yoo ni ara ati egungun (Luku 24:39), a o si dabi Kristi, nitori ti a o ri I bi Oun ti ri (I Johannu 3:2). Awọn eniyan yoo dabi angẹli nipa ọran aikú ati ti ibugbe; ṣugbọn ninu ohun miiran gbogbo, awọn eniyan yoo tayọ awọn angẹli. (Wo I Kọrinti 6:3).

Ọlọrun awọn Alaaye

Jesu fi hàn fun awọn Sadusi pe ajinde yatọ si bi wọn ti n ro o si, nipa riran wọn leti otitọ ti wọn ti gboju fo da. Ọlọrun sọ pe Oun ni Ọlọrun Abrahamu, Isaaki ati Jakọbu. Yala ẹmi awọn eniyan wọnyi ti lọ wà lọdọ Oluwa tipẹtipẹ, tabi bi bẹẹ kọ Ọlọrun jẹ Ọlọrun okú. Ki ni anfaani Ọlọrun awọn eniyan ti o ti kú tipẹ-tipẹ, ti a si ti té̩ si iboji ti a ki yoo si ri wọn mọ? Bi ẹmi awọn eniyan wọnyi kò ba wa laaye lati dapọ mọ ara ologo wọn ni akoko ajinde, n jẹ kò si Ọlọrun alaaye nigba naa. Awọn Sadusi kò sọ pe Ọlọrun alaaye kò si; nitori naa è̩wè̩, lori alaye ti Jesu ṣe, wọn kò le sẹ otitọ ajinde, “ẹnu si ya wọn si ẹkọ rè̩.”

Ibeere Jesu

Lẹyin ti awọn Farisi ati Sadusi ti da ibeere bo Jesu lọtun losi tan, Jesu beere ọrọ kan lọwọ wọn wi pe: “Ẹnyin ti ro ti Kristi si? ọmọ tani iṣe?” Wọn si dahun wi pe “Ọmọ Dafidi ni.” Jesu tun beere lọwọ wọn wayi pe, tani Dafidi n tọka si nigba ti o wi pe “OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ?” (Matteu 22:42-44).

Ibeere yi da awọn Ju ribo-ribo. Oyé kò yé awọn Ju tabi wọn kò fẹ lati gbagbọ pe Kristi tayọ eniyan kiku kan ṣa. Wọn mọ pe ọmọ Dafidi ni o ni lati jẹ, ati pe Oun ni yoo jogun itẹ Baba Rè̩, ati pe a o gbe Israẹli ga si ipo ọlá laarin awọn orilẹ-ède labẹ akoso Rè̩; ṣugbọn wọn kò le ri iṣọkan Kristi pẹlu Baba gẹgẹ bi Ọmọ Ọlọrun.

Ọdọ-Agutan Irubọ

Ninu gbogbo itan iran Israẹli ni Ọlọrun ti n fi suuru kọ awọn Heberu nipa otitọ Kristi ti O n bọ wa. Gbogbo ẹbọ ni o n tọka wọn si pe ohun danindanin ni ẹbọ pipe fun è̩ṣẹ, ẹbọ ti kò ni abuku tabi àbawọn. Nibo ni wọn gbe ni ireti lati le ri irú ẹbọ bẹẹ, lati mu ẹbi è̩ṣẹ wọn kuro, bi ko ṣe lati Ọrun wa? Israẹli mura tan lati gba oludande ti i ṣe ẹni ayé yii, ti yoo mu wọn pada bọ si ipò ọlá ati okiki ti ayé yii ; ṣugbọn wọn kò fẹ ẹlomiran yatọ si iru eyi, oye ohun ti ijọba Rè̩ jẹ kò tilẹ ye wọn dajudaju.

Nigbakuugba ti Jesu ba fẹ fi otitọ yii ye awọn eniyan pe, Ọmọ Ọlọrun ni Oun i ṣe, Ẹni ayeraye, ati pe Oun ti wà pẹlu Baba lati atetekọṣe ati pe Oun yoo si wa pẹlu Rè̩ titi lae, eyi a maa da iyapa silẹ laarin wọn. (Wo Johannu 5:18; 10:30). Ero yii pe Jesu, ọmọ Josẹfu ati Maria, jẹ Ọmọ Ọlọrun kò ṣe deede pẹlu ero ọpọlọpọ ninu awọn Ju rara.

Psalmu Dafidi yii jẹ eyi ti gbogbo Israẹli gbà lai ṣiyemeji pe o jẹ asọtẹlẹ nipa Kristi. Sibẹ ohun ti o hàn gbangba ni pe ẹni meji ni Dafidi n sọ nipa rè̩, awọn Ẹni mejeeji wọnyi si para pọ pẹlu Ẹni kẹta ninu Mẹtalọkan Mimọ. Eeha si ti ṣe ti inu fi bi wọn nigba ti Jesu wi pe Ọmọ Ọlọrun ni Kristi i ṣe? Nipa ta ni Dafidi n sọrọ bi kò ba ṣe Ọmọ Ọlọrun? Bi Kristi ba jẹ Oluwa Dafidi, bawo ni Kristi ti ṣe le jẹ ọmọ Dafidi?

Awọn Farisi kò le dahun awọn ibeere wọnyi. Bi wọn ba ti gbagbọ pe ọna iyanu ni a gbà bi Jesu, oye i ba ye wọn bi Jesu ti ṣe le jẹ Oluwa Dafidi, ki O si tun jẹ ọmọ rè̩.

A rii pe awọn Farisi ri firifiri otitọ ti wọn kò ti ri tẹlẹ nigba ti Jesu bi wọn leere wi pe ki ni ero wọn nipa pe Ọmọ Ọlọrun ni Kristi i ṣe. Wọn kò jẹ daba lati tun beere ibeere lọwọ Rè̩ mọ, nitori ọgbọn ati imọ ti O ni nipa ohun wọnni eyi ti awọn kò mọ ohunkohun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti awọn Farisi rò pe wọn ni ẹtọ lati kọ lati san owo-ode fun Kesari?
  2. Bawo ni Jesu ṣe jẹ ki ojuṣe awọn Farisi si ijọba Romu di mimọ fun wọn?
  3. Ki ni gbese ti wọn jẹ Ọlọrun?
  4. Iru ète wo ni awọn Sadusi pa lati fi hàn pe kò si otitọ ninu ajinde?
  5. Bawo ni Jesu ṣe fi hàn pe ajinde wà?
  6. Ki ni ṣe ti awọn Farisi kò le dahun ibeere Jesu?
  7. Ta ni Oluwa Dafidi?
  8. Ọmọ Dafidi ni Kristi ha i ṣe ni tootọ bi?