Johannu 12:20-36

Lesson 220 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ati emi, bi a ba gbé mi soke kuro li aiye, emi o fà gbogbo enia sọdọ ara mi” (Johannu 12:32).
Cross References

I Awọn Hellene S̩afẹri

1. Awọn Hellene kan wa si ajọ, wọn si n fẹ ri Jesu, Johannu 12:20, 21; 6:40; Marku 7:25-30; Iṣe Awọn Apọsteli 16:1;Romu 1:16

2. Wọn tọ Filippi wa pẹlu ibeere wọn; Filippi sọ fun Anderu, wọn si jumọ lọ sọ fun Jesu, Johannu 12:21, 22

II. Ijiya Jesu ati Ogo ti Yoo Yọri Si

1. Wakati ti a o ṣe Ọmọ-Eniyan logo sun mọ tosi, Johannu 12:23; 17:1-5;Isaiah 49:6, 7

2. Jesu fi hàn pe Oun ni lati jiya oro iku ati isinku ṣiwaju ayọ iṣẹgun ayeraye, Johannu 12:24, 25, 27; Isaiah 53:10-12; I Kọrinti 15:36-38; Heberu 2:9, 10

3. Awọn ti o n sin Jesu ni lati tẹle Jesu, Johannu 12:26; 10:26; 13:16; 14:15; Efesu 5:1, 2; I Tẹssalonika 4:16, 17

4. A gbọ ohun Baba ni idahun si adura Jesu, Johannu 12:28-30; Matteu 3:17; 17:5; II Peteru 1:17

III. Oofa Nla

1. Jesu sọ asọtẹlẹ ti aṣepari iṣẹgun patapata lori Satani, Johannu 12:31; Gẹnẹsisi 3:15; Isaiah 14:12-15;Ifihan 12:9-11; 20:2, 3

2. Gbigbe Jesu soke yoo yọri si fifa ọpọ eniyan sọdọ ara Rè̩, Johannu 12:32; 3:14, 15; Romu 5:17-19;I Timoteu 2:3-6;II Timoteu 1:9

3. Awọn eniyan gbọ ọrọ Jesu, ṣugbọn itumọ rè̩ kò ye wọn, Johannu 12:33, 34; 8:53; Matteu 16:13, 14

4. Jesu fi hàn gbangba, anfaani iyebiye ti o n bẹ nipa ririn ninu imọlẹ, Johannu 12:35, 36; 1:9; 8:12; 11:10;Owe 4:19; I Johannu 2:8-11.

Notes
ÀLÀYÉ

Wakati Iṣelogo

Wiwọ ti Jesu fi Ayọ Iṣẹgun wọ Jesuralẹmu da okiki pupọ silẹ laarin awọn eniyan, si idaamu awọn olori alufa ati awọn Farisi. Akoko Ajọ Irekọja jẹ igbà kan ti o larinrin pupọ laarin awọn Ju. Ọpọlọpọ ninu wọn gbà pe Messia ni Jesu i ṣe, Ẹni ti a ti sọtẹlẹ nipa Rè̩, nitori naa kò ni ṣoro pupọ lati rú ifẹ awọn eniyan soke ki wọn rọ Jesu lati gbe Ijọba Rè̩ kalẹ, ki O si bọ ajaga lile ijọba Romu kuro lọrùn wọn. Ayà awọn Farisi ti domi nitori pe wọn rò pe fifi ayọ iṣẹgun wọ Jerusalẹmu Jesu ati gbigbà ti awọn eniyan gba A ti bẹrẹ iṣẹ yi naa. Wọn tubọ wa pinnu kikan-kikan ni wiwá ọna ti wọn yoo fi pa Ọmọ Ọlọrun.

O fẹrẹ jẹ pe, nigba gbogbo ṣiwaju akoko yii ni Jesu maa n kọ fun ogunlọgọ awọn eniyan ti wọn n fẹ ki O jẹ Ọba wọn. S̩ugbọn, Jesu mọ pe akoko Rè̩ de tan wayi, O si dabi ẹni pe Ọmọ Ọlọrun ti mura tan lati san gbese irapada to bẹẹ ti O fẹrẹ le mu ki wakati naa yara de kankan.

Jesu mọ daju wi pe kẹtẹkẹtẹ ti Oun gun wọ Jerusalẹmu yoo fi hàn pe, Iwe Mimọ yii ṣẹ si Oun lara, “Kiyesi i, Ọba rẹ mbọwá sọdọ rẹ: ododo li oun, o si ni igbalà; o ni irè̩lẹ, o si ngùn kẹtẹkẹtẹ, ani ọmọ kẹtẹkẹtẹ” (Sekariah 9:9). Jesu mọ bi ọkàn awọn Farisi ati awọn alaṣẹ awọn Ju yoo ti ri, ṣugbọn Oun kò ka ẹmi ara Rè̩ si mọ. Jesu mọ pe a kò le ṣalai mu Iwe Mimọ ṣẹ kinnikinni, O si fi pẹlẹpẹlẹ ati iwa tutu tẹra mọ iṣẹ Baba Rè̩. Bawo ni ọpẹ awọn Onigbagbọ ti ni lati pọ to wi pe tọkantọkan ni Jesu fi pinnu lati fi ẹmi Rè̩ san gbese nla ti irapada!

Awọn Hellene Jubà

Nigba ti awọn Farisi n wá ọna bi wọn yoo ti ṣe pa Jesu, ohun miiran ṣẹlẹ ti o le dabi ẹni pe o kere loju, ṣugbọn kò si ohun ti kò nilaari nipa Ọmọ Ọlọrun. Awọn Hellene diẹ kan ti wọn wà pẹlu awọn ti o wà jọsin ni akoko Ajọ Irekọja, gbọ okiki Jesu. Wọn tọ Filippi wa wi pe, “Alagba, awa nfẹ ri Jesu.” Filippi kò mọ ohun ti oun i ba ṣe, nitori naa o mu ọrọ naa tọ Anderu, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹyin Jesu lọ. Awọn mejeeji mu ọrọ yii tọ Jesu lọ. Ohun danindanin ni fun awọn ọmọ-ẹyin Jesu lati jumọ ṣiṣẹ pọ lati mu ọkàn wá sọdọ Oluwa wọn.

Filippi ati Anderu kò mọ irú ọkàn ti Jesu yoo fi gba ọrọ awọn Hellene wọnyi. Lai si aniani, wọn ranti igba ti obinrin ara Sirofenikia, ti i ṣe Hellene, tọ Jesu wa fun iranwọ. O dahun nigba naa wi pe, “A kò rán mi, bikoṣe si awọn agutan ile Israẹli ti o nù” (Matteu 15:24); ṣugbọn wọn ranti pe obinrin yii takú ti Jesu, ati pe, Jesu mu ifẹ ọkàn rè̩ ṣẹ. Boya Filippi ati Anderu ti ṣe apero laarin ara wọn nipa ọna ti o tọ ti wọn i ba gbà nipa ọrọ yii, wọn si mu ọrọ naa tọ Ọmọ Ọlọrun wa. O ṣanfaani nigba pupọ lati ba awọn ojiṣẹ Ọlọrun sọrọ nipa iṣoro wa, ṣugbọn eyi kò gbọdọ di wa lọwọ lati mu ọrọ naa tọ Jesu lọ pẹlu. Agbara wà ninu iṣọkan. Eredi kan ṣoṣo ti o fi yẹ ki iṣoro wa di mimọ fun ẹlomiran rara ni lati tọrọ iranwọ awọn ara lati ba wa mu ọrọ naa tọ Jesu lọ ninu adura, nitori pe Oun ni o le tan gbogbo iṣoro.

Dajudaju a kò ni ṣalai gba awọn Hellene wọnyi laye lati tọ Jesu wa, nitori pe o dabi ẹni pe awọn ni Jesu da lohun ninu ọrọ ti O sọ. Ọmọ Ọlọrun le ri i pe awọn wọnyi jẹ aṣiwaju ninu ikede Ihinrere ati fun ogunlọgọ awọn Keferi wọnni ti yoo jẹ ipe Kristi ati ti irapada. O le jẹ pe iru ọkàn kan naa ti awọn Ju ni ni o n bẹ lọkàn awọn Hellene wọnyi, lati ri ẹni kan ti yoo gbe ijọba aye yi kalẹ lai pẹ; ṣugbọn pẹlu iba ọrọ diẹ kinun, Jesu fi iṣẹ ti O wa ṣe layé hàn wọn.

Woro Alikama

“Bikoṣepe wóro alikama ba bọ si ilẹ, ti o ba si kú, o wà on nikan: ṣugbọn bi o ba kú, a si so ọpọlọpọ eso” (Johannu 12:24). Jesu lo ohun ti a le fi oju ri lati ṣe apejuwe ki otitọ Ọlọrun ti o fara pamọ ba le di mimọ. Nigba ti a ba bo woro ọkà kan mọlẹ, nibi ti ilẹ gbe dara, kò ni pẹ ti yoo fi hù jade, “ekini ẽhù, lẹhinna ipé̩, lẹhinna ikunmọ ọkà ninu ipé̩” (Marku 4:28). Jesu lo woro alikama lati ṣe apejuwe ijinlẹ iṣẹ-iranṣẹ Rè̩, nitori pe alikama ni iyè ninu rè̩. Bakan naa ni iyè ainipẹkun wà ninu Jesu.

Jesu nikan ni Ẹni naa ti o wá sinu ayé yii nipasẹ Ẹni ti a le wi pe “Ninu rè̩ ni iye wa” (Johannu 1:4). Lootọ ni Ọlọrun mi eemi iyè sinu Adamu, ọkunrin kin-in-ni ti O kọ dá. O di alaaye ọkàn, o si ni iyè ti a fi fun un ninu rè̩; ṣugbọn Jesu tikara Rè̩ ni orisun iyè. Bi Adamu ba ti duro ninu ipo ti kò lẹṣè̩ gẹgẹ bi a ti da a, oun i ba ti wà titi laelae; ṣugbọn è̩ṣẹ ni o fa ikú. Ofin Ọlọrun ni pe, “S̩ugbọn ninu igi imọ rere ati buburu ni, iwọ kò gbọdọ jẹ ninu rè̩: nitoripe li ọjọ ti iwọ ba jẹ ninu rè̩ kikú ni iwọ o kú” (Gẹnẹsisi 2:17). Adamu ṣaigbọran si Ọlọrun, o si jẹ ninu eso igi ti a kọ fun un lati jẹ. Lọjọ naa ni o ti kú ikú ẹmi, nigbooṣe o kú ikú ti ara pẹlu. È̩ṣẹ Adamu ni o gbe iye ainipẹkun ti Ọlọrun fi sinu eniyan sọnu, eniyan ẹlẹṣè̩ si bọ sabẹ idajọ ikú ayeraye.

Aṣiiri Nla

Ki i ṣe gbogbo eniyan ni o ṣè̩ “bi afarawe irekọja Adamu,” (Romu 5:14); sibẹsibẹ, “gbogbo eniyan li o sa ti ṣè̩, ti nwọn si kuna ogo Ọlọrun” (Romu 3:23). Irugbin è̩ṣè̩ ti wọ inu eniyan lati igba iṣubu Adamu titi di oni-oloni. Gẹrẹ ti eniyan ba ti dagba to lati mọ rere yatọ si buburu, lai si aniani, è̩ṣẹ ni o n yàn. “Nitorina ẹniti o ba mọ rere iṣe ti kò ṣi ṣe, è̩ṣẹ ni fun u” (Jakọbu 4:17). Kò ṣe e ṣe fun eniyan lati gbà ara rè̩ la kuro ninu è̩ṣẹ, ati kuro ninu iparun ayeraye; È̩jè̩ Ọdọ-Agutan ati agbara Ọlọrun nikan ni o le ṣe iṣẹ iyipada iyanu yii.

Nihin yii ni a gbe fi aṣiiri nla nipa iṣẹ-iranṣẹ Jesu ninu ayé hàn kedere. Ọmọ Ọlọrun ta È̩jè̩ Rè̩ silẹ lati ṣe etutu fun è̩ṣẹ araye. A té̩ okú Jesu sinu iboji, ṣugbọn a kò le pa iyè ti o wà ninu Rè̩ run. Lai pẹ jọjọ, O jinde kuro ni ipo-oku lati so eso pupọ. Ipese nlá nlà ni a pese ki o le ṣe e ṣe fun eniyan lati jẹ alabapin iṣẹgun ayebaye yii. Nigba ti eniyan ba ronupiwada è̩ṣẹ rè̩, ti o si fi gbogbo ọkàn ati ayà rè̩ gba Ọmọ Ọlọrun gbọ, a o gba a la kuro ninu iparun ayeraye, yoo si di alabapin iyè ainipẹkun nipasẹ itoye Olugbala rè̩.

Lọna bayi nikan ṣoṣo ni eniyan tun le ri gba ninu iyè ainipẹkun ti o ti sọnu lọgba Edẹni – ani nipa biba Olufunni-ni-Iye pade nipasẹ È̩jè̩ Ọdọ-Agutan. “Njẹ nisisiyi Kristi ti jinde kuro ninu okú, o si di akọbi ninu awọn ti o sùn. Nitori igbati o ti ṣepe nipa enia ni ikú ti wá, nipa enia li ajinde ninu okú si ti wá pẹlu. Nitori bi gbogbo enia ti kú ninu Adamu, bḝni a ó si sọ gbogbo enia di alāye ninu Kristi” (I Kọrinti 15:20-22). Ki eniyan to le jinde pẹlu iṣẹgun si iyè ainipẹkun ni owurọ ọjọ ajinde ni, oluwarè̩ ni lati kọkọ jẹ alabapin iyè ainipẹkun yii ki o to fi aye yii silẹ.

Sisin Jesu

Jesu tun mu ẹkọ kan pataki jade nihin yii: eyi ni ni pe ki a to le fẹran Kristi ki a si maa sin In, Onigbagbọ ni lati maa tọ ipasẹ Kristi. Kò tun si ọna miiran mọ, ṣugbọn nibi gbogbo ni a gbe le ri awọn eniyan lọjọ oni ti wọn jẹwọ pe iranṣẹ Kristi ni awọn i ṣe, ṣugbọn iṣẹ ọwọ wọn ati iwà wọn kò dọgba pẹlu ẹri wọn. Ibi agbelebu ni ipa ti ọna Jesu laye lọ si taara. Bi ẹnikẹni ba fẹ de ibi ti Jesu wà, dandan ni ki ẹni naa tọ ipa ọna kan naa ti Oluwa rè̩ tọ, nitori Jesu wi pe, “Bi ẹnikẹni ba nsin mi, ki o ma tọ mi lẹhin: ati nibiti emi ba wà, nibè̩ ni iranṣẹ mi yio wà pẹlu: bi ẹnikẹni ba nsin mi, on ni Baba yio bù ọlá fun” (Johannu 12:26). Ọpọlọpọ ni o fẹ lọ si Ọrun lai fẹ gbé agbelebu Kristi.

Ki ni titọ Kristi lẹyin jẹ? S̩e iyẹn ni pe a ni lati mu iṣo ki a si kan ẹni naa mọ agbelebu gẹgẹ bii Olugbala rè̩? Eyi ṣẹlè̩ lotitọ si awọn ajẹriku ti igba nì, ṣugbọn a kò i ti i ké si awọn ọmọ-lẹyin Kristi ni orilẹ-ède wa lati fi ọrun wọn lelẹ fun pipa nitori igbagbọ wọn. S̩ugbọn ohun ti Jesu kọ ni ni pe ifẹ ti Oun ni si awọn eniyan ati ara Oun ti Oun fi rubọ patapata ni aṣiiri ti o wà nidi agbara ti Oun ni lori ọmọ eniyan. “Ọmọ ẹhin ki i jù olukọ rè̩ lọ, bḝni ọmọ-ọdọ ẹni ki i jù oluwa rè̩ lọ. O to fun ọmọ-ẹhin ki o dabi olukọ rè̩, ati ọmọ-ọdọ ki o dabi oluwa rẹ” (Matteu 10:24, 25).

Ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣe ohunkohun tabi ti o fẹ di ohunkohun fun Oluwa rè̩, ni lati ni ifẹ nì ninu ọkàn rè̩ lati kú, ani ikú gidi tabi ikú ti kò nira to bẹẹ, nipa ọna isẹra-ẹni ati pipa ilepa aye pẹlu aniyan rè̩ tì. Kò si ẹni ti o le jẹ Onigbagbọ ti o n so eso lai jẹ pe o kọ fi ara rè̩ rubọ. “S̩ugbọn bi o ba ku, a si so ọpọlọpọ eso”.

Èrè Gbogbo

Alaimọkan eniyan le wi pe kiki adanù ni o wà ni ọna Agbelebu, lai tilẹ si èrè rara, ṣugbọn dajudaju kò si eke ti o tun tayọ eyii. Gbogbo ọna miiran ni ọna adanu, a fi ọna Agbelebu. Jesu wi pe, “Ẹniti o ba fẹ ẹmi rè̩ yio sọ ọ nù; ẹniti o ba si korira ẹmi rè̩ li aiye yi ni yio si pa a mọ titi fi di iye ainipekun” (Johannu 12:25). Jesu ti la ọna igbesi-ayé ti yoo wa titi laelae, ani titi aye ainipẹkun silẹ. Kò si igbekalẹ tabi ọgbọn miiran kan ti o le fun ni ni idaniloju ba yii. “Iwa-bi-Ọlọrun li ère fun ohun gbogbo, o ni ileri ti aiye isisiyi ati ti eyi ti mbọ” (I Timoteu 4:8).

Jesu a maa tọ Onigbagbọ kọọkan nipa ifẹ -- bawo ni ọna yii si ti logo to! Ọmọ Ọlọrun fara da ọna Agbelebu, nitori pe ifẹ Baba Rè̩ ni, ọna yii ni o si mu ki a ṣe E logo. Pẹlu idaniloju yii ni ọkàn awọn iranṣẹ Jesu, Onigbagbọ tootọ a maa fi ayọ gbe iṣisẹ rè̩ kọọkan lọna ti Oluwa rè̩ tọ. Olorin kan sọ inu awọn Onigbagbọ lọna bayii:

“Wahala ọna ki yo jamọ nkan

Gba n ba dopin irin-ajo na”

Jesu mọ pe ninu ikú Oun ni iṣẹgun pipe lori Satani gbe wa. Ọmọ Ọlọrun lori igi agbelebu yoo jẹ Oofa nla ti yoo maa fa eniyan. Ifẹ ni a fi n fa ọmọ-eniyan mọra. A le fi ọna miiran tì wọn sihin-sọhun, ṣugbọn ifẹ nikan ni oofa ti o n fa eniyan. Kristi lori agbelebu jẹ ifarahan ifẹ ti o lọla jù lọ, ti o si tobi jù lọ ti aye yii ti i ṣe ẹlẹrii rè̩, nitori pe O yọọda ara Rè̩ tinutinu lati lọ sibẹ ki o le san gbese irapada araye!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni n wa Jesu ni akoko Ase Ajọ Irekọja?
  2. Ta ni awọn eniyan wọnyi sọ fun wi pe, awọn fẹ ri Jesu?
  3. Ki ni ohun ti Jesu fi da awọn eniyan wọnyi lohun?
  4. Bawo ni o ti ṣe e ṣe lati ri iyè ainipẹkun gbà?
  5. Bi ẹni kan ba n sin Jesu tọkantọkan, ki ni oluwarè̩ ni lati mura tan lati ṣe?
  6. Ki ni ṣẹlẹ ni akoko yii nigba ti Jesu gbadura si Baba Rè̩?
  7. Ta ni Oofa nla ti aye yii? Ki ni ṣe?
  8. Darukọ awọn ere pataki ti o wà ninu ririn ninu imọlẹ.
  9. Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn eniyan ti o n rin ninu okunkun?