Matteu 27:57-66; 28:1-15

Lesson 221 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Niwọnbi o ti da ọjọ kan, ninu eyi ti yio ṣe idajọ aiye li ododo, nipasẹ ọkunrin na ti o ti yàn, nigba ti o ti fi ohun idaniloju fun gbogbo enia niti o ji i dide kuro ninu okú” (Iṣe Awọn Aposteli 17:31).
Cross References

I. Isinku Jesu Kristi

1. A sin Jesu sinu iboji ọlọrọ kan gẹgẹ bi a ti sọtẹlẹ, Matteu 27:57-60; Isaiah 53:9; Marku 15:42-46; Luku 23:50-53; Johannu 19:38

2. Maria Magdalene ati Maria keji wa nibi isinku Jesu, Matteu 27:61; Marku 15:47; Luku 23:55, 56

II. Awọn Farisi Di Rikiṣi

1. Awọn Farisi tọrọ wọn si gba iranwọ awọn alaṣẹ Romu lati dena ajinde Jesu, Matteu 27:62-66; Orin Dafidi 2:1, 3

III. Owurọ Ọjọ Ajinde

1. Angẹli Ọlọrun sọ agbara awọn è̩ṣọ Romu di asan, Matteu 28:1-4

2. Angẹli kan sọ ihin ayọ ajinde Jesu, Matteu 28:2-7; Marku 16:6; Luku 24:6

3. A ran awọn obinrin lati sọ ti ajinde Jesu fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ati pe, Oun yoo pade wọn ni Galili, Matteu 28:7; 26:32; Marku 16:7

4. A doju ti awọn ọta Jesu nipa ajinde Rè̩, Matteu 28:11-15; Orin Dafidi 78:65, 66; Isaiah 51:9; 42:13-16

5. Jesu pade awọn obinrin naa bi wọn ti n lọ jiṣẹ ti angẹli ran wọn, Matteu 28:8-10; Marku 16:9.

Notes
ÀLÀYÉ

Iboji Ọkunrin Ọlọrọ

Ọkan ninu awọn ojiṣẹ Ọlọrun ni igba laelae sọ nipa awọn asọtẹlẹ ti o jẹ mọ ikú ati isinku Jesu bayii pe; “Olóye eniyan le ro arosọ ohun ti o le ṣẹlẹ, o si le sọ ohun pupọ ti o n bọ wa ṣẹ, ṣugbọn Ọlọrun nikan ni O le ri awọn ohun kékèké ti a kò kà si.” Ọlọrun nikan ni O le sọ asọtẹlẹ ohun wọnni ti yoo ṣẹlẹ ni kinnikinni nipa ikú Kristi ni ẹgbaagbeje ọdun ṣiwaju ki eyi to ṣẹlẹ. Ọkan ninu awọn asọtẹlẹ kikún wọnyi ni a ti ẹnu Woli Isaiah sọ bayii pe, “O si ṣe iboji rè̩ pẹlu awọn enia buburu, ati pẹlu ọlọrọ ni ikú rè̩” (Isaiah 53:9).

Jesu ṣe iboji Rè̩ pẹlu awọn eniyan buburu ni ti pe a kan An mọ agbelebu gẹgẹ bi arufin laarin ole meji. Ọjọ kan ṣoṣo naa ni awọn eniyan mẹtẹẹta yii kú, a si sin wọn si iboji wọn. Eyi yii jẹ imuṣẹ asọtẹlẹ lọnà ti o yani lẹnu, nitori pe awọn woli ti o sọ asọtẹlẹ nipa Jesu kò ni imọ tabi oye nipa ohun gbogbo ti o ṣẹlẹ nipa iku ati ajinde Rè̩. Nitori eyi, wọn ko ni le sọ asọtẹlẹ nipa iku Jesu bi ko ṣe pe Ọlọrun ba fi hàn fun wọn. Ta ni bi ko ṣe Ọlọrun, ni o le sọ wi pe Jesu yoo kú pẹlu awọn eniyan buburu, sibẹ ki a si wa sin In sinu iboji ọlọrọ.

Awọn oninunibini Jesu ti fi ewu sọna awọn ọmọ-lẹyin Jesu, paapa jù lọ ni akoko ti a kan An mọ agbelebu. Sibẹ, ni akoko iṣoro yii, Josẹfu ara Arimatea fi igboya dide lati lọ beere okú Jesu. Lẹyin ti Josẹfu mu ibeere rè̩ tọ Pontiu Pilatu lọ, a yọọda fun un lati lọ sin okú Jesu. Josẹfu si ṣe bẹẹ, bayii ni a sin okú Jesu sinu iboji ọlọrọ; nitori pe ọlọrọ ni Josẹfu i ṣe, o si ti gbẹ iboji kan silẹ, gẹgẹ bi aṣa awọn eniyan igbà nì. Bayii ni Ọlọrun fi idi rè̩ mulẹ wi pe pipe ni Ọrọ Rè̩ nipa mimu ohun wọnni ti a ti sọ asọtẹlẹ ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin ṣẹ kinnikinni.

Iṣọ ati Edidi Ijọba Romu

Awọn Farisi tọ Pilatu wa wi pe ki o ṣe iranlọwọ fun wọn lati rii pe awọn ọmọ-ẹyin Jesu kò ji okú Rè̩ gbe kuro ninu iboji. Pilatu fi ibeere wọn fun wọn. Wọn fi awọn ẹṣọ sibẹ, wọn si fi edidi ijọba Romu di okuta ti o wà ni ẹnu iboji, ki ẹnikẹni má le ni anfaani lati wọ ibẹ lọ.

Awọn Farisi sọ fun Pilatu wi pe wọn ni ero pe awọn ọmọ-ẹyin Jesu le wa ji okú Jesu gbe, ki wọn si wi pe, O ti jinde. Wọn ranti ohun ti Jesu wi pe Oun yoo jinde. Ohun ti o ya ni lẹnu ni pe o dabi ẹni pe igbagbọ wọn ninu ajinde Jesu tayọ ti awọn ọmọ-ẹyin Jesu paapa. Wọn mọ daju pe Jesu ti kú ṣugbọn ayà wọn kò lelẹ, wọn bè̩ru agbara ti O n lo nigba ti O wa layé, wọn si sa gbogbo ipa wọn lati dena isọji ẹkọ Rè̩ tabi ajinde Rè̩. Bi o ba ṣe e ṣe fun eniyan lati ri i pe Jesu kò jinde, Oun i ba wa ninu iboji titi di isisiyi. S̩ugbọn awọn ọta Rè̩ ti ṣe iṣẹ ọwọ wọn na! Akoko okunkun fẹrẹ rekọja na, lai pẹ jọjọ, imọlẹ didan ọjọ titun ninu eto nla Ọlọrun yoo bẹ jade. Nipa ajinde kuro ninu oku, Kristi di akọso ajinde wa, ireti ati idaniloju gbogbo Onigbagbọ!

Ju ati Keferi, aye, ara ati eṣu ti dimọ pọ lati pa Oluwa Ogo, ati lati pa A run patapata. Wọn ti lo gbogbo ipa wọn, Ọlọrun si fẹ fi agbara, ipa ati ogo Rè̩ hàn fun wọn.

Iboji Ofifo

A le fi oju inu wo idaamu ti o ba awọn Farisi ati awọn ara Romu nigba ti wọn gbọ nipa ajinde Jesu. Ihin ajinde jẹ ohun ti o maa n mu ki awọn eniyan Ọlọrun damuso fun ayọ ati iṣẹgun, eyi ti ẹnikẹni kò le pa lẹnu mọ. Ọlọrun ti ṣe iṣẹ nla Rè̩ ni aṣeyọri, igbala kuro ninu è̩ṣẹ si daju. Irera agbara Romu, eyi ti awọn oluṣọ duro fun bi aṣoju, ni a pa tì si apa kan, angẹli Ọlọrun kan si yi okuta bẹrè̩kẹtè̩ ti wọn yi di ẹnu iboji Jesu kuro. Wo bi o ti rọrun to fun Oluwa lati mu gbogbo ohun ti o dabi ẹni pe o le ṣe idena ajinde Jesu kuro!

A ṣẹtẹ iku, ọrun apaadi ati ipo-oku pẹlu. Kò si ẹni naa laye yii ti o le dena Rè̩ ninu ohunkohun miiran gbogbo, bakan naa ni eṣu ati gbogbo ogun rè̩ kò le se Oluwa mọ iboji. Orin ogun awọn Onigbagbọ ajagun lati owurọ ayọ naa ni pe, “Ikú, oró rẹ da? Isà oku, iṣẹgun rẹ dà?” (I Kọrinti 15:55). Ọrọ Isaiah ṣẹ wa yii: “Awọn ọba yio pa ẹnu wọn mọ sii, nitori eyi ti a kò ti sọ fun wọn ni nwọn o ri; ati eyi ti nwọn kò ti gbọ ni nwọn o rò” (Isaiah 52:15; Romu 15:21).

Ihin Ayọ

Jesu ti sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe akoko n bọ ti inu wọn yoo bajẹ gidigidi nitori awọn ohun ti o n bọ wa ṣẹlẹ, ṣugbọn ibanujẹ wọn yoo pada di ayọ. “Ẹnyin o ma sọkun, ẹ o si ma pohùnrere ẹkún, ṣugbọn awọn araiye yio ma yọ: inu nyin yio si bajẹ, ṣugbọn ibinujẹ nyin li yio si di ayọ. . . Nitorina ẹnyin ni ibinujẹ nisisiyi: ṣugbọn emi o tún ri nyin, ọkàn nyin yio si yọ, kò si si ẹniti yio gbà ayọ nyin lọwọ nyin” (Johannu 16:20, 22). “Bi ẹkun pẹ di alẹ kan, ṣugbọn ayọ mbọ li owurọ” (Orin Dafidi 30:5).

Oru ibanujẹ kọja fun awọn ti o fẹ Jesu. Awọn obinrin dide lati lọ si iboji ni kutukutu owurọ pẹlu ibanujẹ nitori ikú Oluwa wọn, wọn si de ibẹ ni akoko ti o wọ to bẹẹ ti o fi jẹ pe awọn ni o kọ gbọ ihin ayọ ti angẹli nì wa kede rè̩. “Kò si nihinyi: nitori o ti jinde gẹgẹ bi o ti wi. Wá, ẹ wò ibiti Oluwa ti dubulẹ si” (Matteu 28:6).

Awọn obinrin wọnyi fi ayọ gbà ihin ajinde, gẹgẹ bi ọpọlọpọ ti n fi ayọ gbà a lati igba naa wa. Pẹlu iwarapapà ati ọkàn ti o kún fun ayọ ni awọn obinrin wọnyi fi mu ọna wọn pọn lati ṣe ohun ti angẹli ni palaṣẹ fun wọn, ani lati lọ sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Jesu nipa ohun iyanu ti o ti ṣẹlẹ.

Kristi Ti O Jinde

Awọn obinrin wọnyi fẹrẹ maa ti bẹrẹ si i mu ọna wọn pọn lati lọ wa awọn ọmọ-ẹyin ti Jesu fi fara hàn wọn. Bẹẹ ni o maa n ri, kò si yi pada. Gẹrẹ ti a ba gbà ẹri awọn wọnni ti o mọ pe Kristi jinde, ni awa paapa yoo ri Kristi ti O jinde kuro ninu okú tikara wa. (Wo Iṣe Awọn Apọsteli 10:41). Eyi ni èrè ti i ṣe ti awọn ti o ba tete n wa Oluwa, nitori ileri Ọlọrun ni pe, “Ẹnyin o si ṣafẹri mi, ẹ o si ri mi, nitori ẹ o fi gbogbo ọkàn nyin wá mi” (Jeremiah 29:13).

Ihin ajinde Jesu ki i ṣe ohun ti o dùn mọ awọn Farisi ninu rara. Nigba ti iṣẹlẹ agbayanu yii ti aye kò ri irú rè̩ ri doju kọ wọn gbọngbọn, wọn gbà ọna irọ, ati owo abẹtẹlẹ, ati aiṣootọ lati gbiyanju ati bo otitọ ajinde mọlẹ. Wọn fi owo bọ awọn ọmọ-ogun lọwọ, ani awọn wọnni ti wọn ti wà bi ẹṣọ nibi iboji Jesu, ki wọn ki o le wi pe, awọn ọmọ-ẹyin ni o wá ti wọn si ji oku Jesu gbe. Sibẹsibẹ, Ọlọrun ti ṣe iṣẹ iyanu ti Rè̩. (Wo Isaiah 28:21; Iṣe Awọn Apọsteli 13:40, 41; Habakkuku 1:5). Kẹké̩ pa mọ awọn ti o ti purọ mọ Kristi lẹnu (Orin Dafidi 63:11; Iṣe Awọn Apọsteli 13:30).

Ikede Ihinrere

Akoko awọn Onigbagbọ bẹrẹ pẹlu ajinde Kristi. A ni lati rò ihin ati ireti ajinde ti i ṣe ipilẹ Ihinrere nibikibi ti a gbe le ri eniyan. Jesu kò paṣẹ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lati fi ikede wọn mọ ni ọdọ awọn Ju nikan. Iṣẹ Ihinrere naa ni pe, “Ẹ lọ, ẹ mā kọ orilẹ-ède gbogbo.” Niwọn bi Jesu ti kú fun gbogbo eniyan, gbogbo eniyan ni o ni lati gbọ ihin ti ajinde Rè̩. Iṣẹ awọn ti o ri I lẹyin ti O kú ti O si jinde ni lati maa kede ihin ayọ yii fun awọn ti kò ti i ri I, eyi yii ni ilana Ọlọrun.

Ki i ṣe gbogbo eniyan ni yoo gbà ihin ti Ọmọ Ọlọrun ti O kú ti O si tun jinde fun idalare eniyan gbọ. Jesu sọ fun Tọmasi, ẹni ti o sọ wi pe oun ki yoo gbagbọ afi bi oun ba fi ọwọ kan apa ara Kristi: “Nitoriti iwọ ri mi ni iwọ ṣe gbagbọ: alabukun-fun li awọn ti kò ri, ti nwọn si gbagbọ” (Johannu 20:29).

Nitori naa, a kọ ẹkọ yii pe kò si ire kan ninu ihin ajinde Kristi fun wa bi ẹni kọọkan afi bi otitọ yii ba n gbe inu ọkàn awa paapa. Nigba ti a ba ṣe eyi, Ọlọrun yoo jẹri si otitọ yii fun wa. A o mọ agbara ajinde ti o wọ igbesi-ayé wa, ti o fun wa ni agbara lati maa rin ni ọtun iwa, ti o si tun fun wa ni ireti lati wà lọdọ Oluwa titi laelae.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ohun ti awọn woli sọtẹlẹ nipa isinku Jesu?
  2. Awọn ta ni kọ ri Jesu lẹyin ajinde Rè̩?
  3. Ọna wo ni awọn Farisi rò pe, awọn o fi dena ajinde Jesu?
  4. Iwọ ha rò pe, wọn gbagbọ pe Kristi yoo jinde ni tootọ?
  5. Ki ni ṣe ti ajinde fi jẹ ireti danindanin fun awọn Onigbagbọ?