I Samuẹli 16:1-23

Lesson 210 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI:“Ọlọrun li Onidajọ: o sọ ọkan kalẹ, o gbé ẹlomiran leke” (Orin Dafidi 75:7).
Notes

Akoko Ayọ

Ọlọrun ti kọ Saulu lati maa jọba lori Israẹli nitori aigbọran rè̩. Samuẹli ti fẹran Saulu lọpọlọpọ ni akoko ti o ṣe akoso Israẹli daradara, o si dùn Woli naa gidigidi pe Saulu kò tun jẹ ọba rere ti Ọlọrun le lò mọ.

Ọlọrun wi fun Samuẹli ni ọjọ kan pe: “Yio ti pẹ to ti iwọ o fi ma kānu Saulu, nigbati o jẹ pe, mo ti kọ ọ lati ma jọba lori Israẹli?” Ọlọrun ti rán idajọ Rè̩ jade. Saulu ti ni ọpọlọpọ anfaani lati ronupiwada, o si ti ta wọn nù. Nisisiyi kò si ireti fun un mọ nipa ọran jijẹ ọba ni Israẹli. Ọlọrun sọ fun Samuẹli pe, ki o má ṣe banujẹ mọ, ṣugbọn ki o gbagbe ohun ti o ti kọja ki o si fi ororo yan ọba titun . Akokò ayọ nlá ni o maa n jẹ nigba ti a ba n fi ọba titun jẹ. Ireti titun maa n sọji.

Irubọ ni Bẹtlẹhẹmu

Ọlọrun ran Samuẹli lọ si Bẹtlẹhẹmu, si ile Jesse, O si wi fun un pe ki o fi ororo yàn ọkan ninu awọn ọmọ Jesse gẹgẹ bi ọba ti oye kàn. È̩rù ba Samuẹli pe bi Saulu ba gbọ nipa rè̩ yoo fẹ lati pa oun. Saulu wa lori itẹ sibẹsibẹ, o si daju pe yoo jowu ẹnikẹni ti a ba tun yàn sori itẹ naa. S̩ugbọn nigba ti Ọlọrun ba ran awọn ọmọ Rè̩ lati ṣiṣẹ kan fun Un, Oun a maa tọju wọn.

Ọlọrun sọ fun Samuẹli pe ki o mu ọdọ-malu kan lọwọ rè̩ nigba ti o ba lọ si Bẹtlẹhẹmu, ki o si ṣe irubọ gẹgẹ bi iṣe rè̩ nigba ti o ba n lọ kaakiri lẹnu iṣẹ rè̩. Nipa bẹẹ, Saulu le má gbọ nipa ifororoyàn naa.

Samuẹli lọ gẹgẹ bi Ọlọrun ti wi; nigba ti o si de Bẹtlẹhẹmu è̩rù ba awọn agba ilu naa pe iru aiṣedeede wo ni awọn i baa ṣe nipa eyi ti Samuẹli fi wá ni akoko yii. Samuẹli fi ọkàn wọn balẹ pe alaafia ni. O wi pe ki wọn yà ara wọn si mimọ ki wọn si wa ba oun jọsin. Ni pataki o pè idile Jesse.

A le yà ara wa si mimọ tabi ki a pese ọkàn wa silẹ ṣiwaju akoko isin nipa gbigbe gbogbo ero nipa iṣẹ wa ati eré wa kuro lọkàn wa, ati ṣiṣe aṣarò nipa nkan ti Ọlọrun. A ni lati gbadura ṣiwaju ipade pe ki Ọlọrun ràn wa lọwọ lati le sa gbogbo ipa wa lati sọ fun ẹlomiran nipa Jesu ni ọna ti oun yoo fi fẹ ri igbala. Nigba naa Ọlọrun yoo bukun fun wa, a o si ri i pe ipade naa kò lọ lasan.

Ohun ti Ọlọrun n Wò

Nigba ti olukuluku ṣetan fun akoko irubọ naa, wọn ba Samuẹli pade nibi pẹpẹ Ọlọrun. Bi Samuẹli ti fi oju wo awọn eniyan naa gààrà, o ri ẹgbọn patapata ninu awọn ọmọkunrin Jesse, Eliabu, ọdọmọkunrin ti oju rè̩ fa ni mọra, o si rò pé bi oun ni o tọ ki o jẹ ọba ni Israẹli. Ọlọrun naa ri i pẹlu, ṣugbọn oye Rè̩ kọja ti Samuẹli. O mọ pe, Eliabu kò yẹ lati jọba. O wi fun Samuẹli pe, “Enia a ma wò oju, OLUWA a ma wò ọkàn.”

Lẹyin naa ni Abinadabu, ati S̩amma awọn ọmọkunrin ti wọn tè̩le e kọja. Sibẹ wọn kò tẹ Ọlọrun lọrun. Kò si eyi ti ọba jijé̩ tọ si ninu wọn. Lẹyin naa ni awọn ọmọkunrin ẹkẹrin ati ẹkarun kọja – ati ẹkẹfa ati ekeje. Gbogbo wọn kọja tan, sibẹ Ọlọrun kò yàn wọn. Ki ni yoo jẹ ero Samuẹli? Ọlọrun rán an lati fi ororo yàn ọmọkunrin Jesse kan lọba, gbogbo wọn si ti kọja, sibẹ a kò ri ọba.

Samuẹli bi Jesse leere “Gbogbo awọn ọmọ rẹ li o wà nihin bi?” Jesse dahun pe, abikẹyin ọmọ oun ti o n ṣọ agutan ni o kù, ati bi o si ti jẹ ọmọ kekere, ko si ẹni ti o ro pe o ṣe pataki lati pe e. Awọn ẹgbọn rè̩ kò bikita lati ṣe iyọnu nipa aburo wọn kekere. Aburo kekere naa ni Dafidi, oun si ni ẹni ti Ọlọrun n fẹ ki o jọba lori Israẹli. Bi o tilẹ jẹ pe awọn ẹgbọn rè̩ kò kà a si, ṣugbọn Ọlọrun kà a si. Dafidi kò da wà ni ẹba oke pẹlu awọn agutan; Ọlọrun wà lọdọ rè̩, O si n kọ ọ ni nnkan ti ayeraye.

Imurasilẹ

Nigba ti Dafidi wà ni papa ti o n ṣọ awọn agutan, oun kò fi akoko rè̩ ṣofo rara. Ọlọrun maa n fẹ lati ri ki eniyan fi gbogbo ọkàn rè̩ ṣe ohunkohun ti o ba n ṣe; bi Dafidi si ti n ṣọ awọn agutan, o tun n kọ ohun-elo orin rè̩ pẹlu. Oun i ba wi pe ko si ẹni ti o le gbọ orin ti oun n fi ohun-elo orin kọ, nitori bẹẹ kò ṣanfaani lati mura si i. S̩ugbọn nigba ti o ṣe, a pe e lati wa fi ohun-elo orin ṣire fun ọba, a kò si ba a ni itulẹ. Nigba ti o ba n lo ohun-elo orin oun a maa kọ orin iyin si Ọlọrun pẹlu. Dafidi ni o kọ ọpọlọpọ ninu awọn Psalmu inu Bibeli, o si le jẹ pe, o kọ ninu wọn nigba ti o n sọ awọn agutan. Lai ṣe aniani, lati inu iṣẹ ti o ti n ṣe nigba ewe rè̩ yii ni o ti ni imisi lati kọ “OLUWA li Oluṣọ-agutan mi; emi ki yio ṣe alaini” (Orin Dafidi 23:1).

Nigba ti Dafidi de ibi ase ti wọn ti ṣe irubọ naa, Ọlọrun sọ fun Samuẹli pe, ọba titun naa ni yii. Samuẹli dide o si fi ororo sa a ni amì fun ipo naa nibẹ gan an ni oju gbogbo idile rè̩, awọn ti kò kà a si ẹni ti o yẹ lati pọnle to bẹẹ.

Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe: “Bi ẹnikẹni ba nsin mi, on ni Baba yio bù ọlá fun” (Johannu 12:26). Tinutinu ni Dafidi ti fi n sin Ọlọrun, nisisiyi Ọlọrun wa bẹrẹ si bu ọlá fun un nitori ijolootọ rè̩.

Ẹni Bi ti Inu Ọlọrun

Ẹmi Oluwa ba le Dafidi lati ọjọ naa lọ; ati laarin ọpọlọpọ ọdun ti Dafidi fi sin Ọlọrun pẹlu ọkàn otitọ, o gbiyànju nigba gbogbo lati wu Ọlọrun. Nigba ti o ba si dẹṣẹ, pẹlu irobinujẹ ọkàn ni o fi ronupiwada, Ọlọrun si dariji i. O jẹ ẹni bi i ti inu Ọlọrun. Ilepa ọkàn rè̩ ni lati bu ọlá fun Ọlọrun ati lati sin In.

Dafidi kò rò pe, nisisiyi ti a ti fi ororo yàn oun ni ọba, oun ti ga jù ẹni ti o yẹ ki o maa ṣiṣẹ lọ. O pada lati maa ṣọ agbo agutan baba rè̩ titi di akoko ti Ọlọrun yoo fi pè e. Ni gbogbo ọdun ti o fi n duro yii, Ọlọrun wà pẹlu rè̩, O si n ṣe itọju rè̩.

Ibanujẹ Saulu

Saulu wa ni aafin daradara rè̩ sibẹ, ṣugbọn Ẹmi Ọlọrun ti fi i silẹ, ẹmi buburu si n yọ ọ lẹnu. O jẹ onikanra, kò si si ẹni ti o le té̩ ẹ lọrun. Awọn iranṣẹ rè̩ rò wi pe, boya orin le mu ki ara rè̩ balè̩, wọn si gbiyanju lati wá ẹni ti o mọ lilo ohun-elo orin ati orin kikọ. Ta ni iwọ rò pe wọn ri? Ni tootọ Dafidi ni. Ẹni kan gbọ nigba ti o n fi ohun-elo orin rè̩ kọrin, o si sọ nipa rè̩ fun ọba. O tun sọ pẹlu pe Dafidi jẹ ọdọmọkunrin ti o ni igboya, ati iru eniyan ti ọba yoo fẹ ki o maa gbe ninu ile rè̩.

Saulu ranṣẹ si Jesse pe, ki o jẹ ki ọmọ rè̩ ọkunrin abikẹyin wá maa gbe inu aafin fun igba diẹ. Inu Jesse dùn pe ọba fẹ bu ọlá fun ẹni kan ninu ẹbi oun. Kiakia ni o wá ẹbun kan lati fi ran Dafidi, o si fi Dafidi ṣọwọ si ọba.

Ninu Aafin

Nigba ti Saulu ri Dafidi “on si fẹ ẹ gidigidi.” A fi Dafidi ṣe ẹni ti o nrù ihamọra ọba, nipa eyi ti o fi jẹ iranṣẹ ti yoo maa wà nitosi oluwa rè̩ nigba gbogbo. Lẹyin eyii, nigba ti ẹmi buburu ba de si Saulu, Dafidi a fi ohun-elo orin rè̩ kọ orin didùn, boya o maa n fi ẹnu rè̩ kọrin pẹlu, ẹmi buburu naa a si fi i silẹ.

Anfaani ni eyi jẹ fun Dafidi lati kọ nipa iṣẹ ọba. Inu pápá ni o sa ti n gbe, kò si mọ bi wọn ti n ṣe ni aafin. Ọlọrun ni O ṣi ọna yii silẹ ki Dafidi ba le kẹkọ nipa ohun ti oun ni lati ṣe nigba ti o ba di alakoso Israẹli.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nibo ni Ọlọrun ran Samuẹli lọ lati fi ororo yàn ọba?
  2. Ki ni ṣe ti Samuẹli fi bẹrù Saulu?
  3. Bawo ni Ọlọrun ti ṣe ṣeto bi wọn o ti ṣe le fi ororo yan ọba?
  4. Ọmọkunrin melo ni Jesse bi?
  5. Melo lo kọja niwaju Samuẹli ti a si kọ?
  6. Nibo ni Dafidi wà?
  7. Pẹlu iṣẹ oojọ rè̩, ki ni Dafidi tun n ṣe?
  8. Bawo ni Samuẹli ṣe mọ wi pe Dafidi ni ọba ti o kàn lati gun ori oye?
  9. Ki ni Dafidi ṣe lẹyin ti a fi ami ororo yàn an lọba?
  10. Bawo ni Dafidi ṣe de aafin Saulu?